Yilwatda wọlé padà bíi Alága àpapọ̀ APC pẹ̀lú àwọn olóyè ẹgbẹ́

Awon ọmọ alakooso ẹgbẹ APC nibi ipade apapọ ẹgbẹ naa to waye l'Abuja

Oríṣun àwòrán, APC

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 11

Lẹyin ipade apapọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) to waye niluu Abuja, ẹgbẹ naa ti ni ki Nentawe Yilwatda to jẹ Alaga apapọ wọn tẹlẹ máa tẹ̀síwájú nipo naa lọ gẹ́gẹ́ bíi alága .

Afẹnuko yii waye nibi eto idibo abẹle to yẹ ko waye niluu Abuja ni owurọ oni ọjọ Abamẹta, sugbọn ti gbogbo ọmọ ẹgbẹ tun fohun sọkan pe ki gbogbo àwọn ọmọ alakoso ẹgbẹ to ti n tukọ APC bọ tẹlẹ tun tẹsiwaju.

Bi wọn ṣe fẹnuko naa ni wọn si bura fun awọn alakoso tuntun yii lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

Ẹgbẹ fi kun un pe awọn ni yoo maa dari ọkọ ẹgbẹ APC lọ fun ọdún mẹ́rin tó ń bọ̀.Díẹ̀ lára àwọn alakooso naa ni :

Igbakeji Alága Orílẹ̀-èdè (Àríwá), Ali Dalori; Igbakeji Alága fun Gúúsù, Emma Eneukwu; Akọ̀wé, Surajudeen Basiru; Akọ̀wé Owo; Alhaji Bashir Gumel; àti agbẹjọro fun ẹgbe naa, Murtala Kankia, pẹ̀lú àwọn mi-in.

Nínú ọ̀rọ̀ ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀,Yilwatda sọ pe oun ti ṣetan lati maa dari ọkọ ẹgbẹ naa lọ gẹgẹ bi alaga igbimọ amuṣẹṣe (NWC).

O ni oun ṣetan lati nipa ninu mimu idagbasoke ba APC labẹ́ ìdarí Ààrẹ Bola Tinubu.

Gẹgẹ bo ṣe Yilwatda ṣe wi:

"Àfojúsùn wa han kedere pẹ̀lú ìṣọ̀kan, a ó kọ ẹgbẹ́ kan tí yóò jẹ́ ti gbogbo Africa àti gbogbo Nàìjíríà, to lágbára to si kún fún idagbasoke gbogbo ènìyàn, ẹgbẹ to ní ìfaradà àti ìṣọ̀kan ju ti tẹ́lẹ̀ lọ."

Alaga APC lapapọ naa tẹsiwaju pe awọn yoo mu ìjọba olómìnira inú ẹgbẹ́ jinlẹ̀ sí i, kí gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ lè ní ohun isọkan.

Bakan naa lo ni awọn yoo tun tẹle ilana ti gbogbo ọmọ ẹgbẹ yoo gbagbọ ninu rẹ.

O gboriyin fun Aarẹ Tinubu fún atìlẹ́yìn rẹ̀ sí ẹgbẹ́ náà, àti bo ṣe n dari orílẹ̀-èdè Naijiria.

APC ni ọjọ ọla Naijiria bi Yilwatda ṣe wi, labẹ ireti ọtun ti Aarẹ Tinubu n ṣatilẹyin fun.

PDP naa n gbero ipade apapọ tuntun ọlọjọ meji

Ipade apapọ PDP ti ọdun 2025

Oríṣun àwòrán, PDP

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, ẹgbẹ naa ṣi n gbiyanju lati mu nnkan bọ sipo to yẹ.

Ẹ o ranti pe laipẹ yii ni ile ẹjọ Kotẹmilọrun fagile ipade apapọ ti igun PDP kan ṣe n'Ibadan lọdun to kọja.

Idajọ naa si wa lara ohun to tun sọ ẹgbẹ Alaburada di alailẹnikan, nigba ti ọpọ gomina ẹgbẹ naa ti yipada si APC.

Ni bayii, igun PDP ti Tanimu Turaki n lewaju, ti kootu da idibo rẹ nu ti lọ ba Nyesom Wike, Minisita ilu Abuja pe kawọn jọ maa ṣe pọ.

Turaki ninu ọrọ to sọ fun awọn akọroyin sọ pe ki awọn ọmọ ẹgbẹ PDP ti ko ti I kuro ninu ẹgbẹ naa ma ṣe bẹru, nitori awọn yoo ri i daju pe awon fa oludije kalẹ ni PDP fun 2027.

Wike ni tiẹ ti kede pe awọn yoo ṣepade apapọ tuntun lọla ode yii ti i ṣe ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kẹta ati ọgbọnjọ oṣu Kẹta ọdun 2026 yii.

Bakan naa ni Wike paapaa sọ pe PDP ṣi duro digbi, bo tilẹ jẹ pe awọn kan wa ti inu wọn ko dun ninu ẹgbẹ naa.

O fidi ẹ mulẹ pe asọye ti yoo mu PDP di odidi ti n lọ lọwọ, gẹgẹ bi eto ṣe n to lati ṣepade apapọ ẹgbẹ naa lẹyẹ o sọka.

APGA gba lati tẹle Tinubu ni 2027

Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Grand Alliance (APGA) ti kede ni tiẹ pe oun ko fa oludije ipo aarẹ kankan kalẹ ni 2027, Aarẹ Tinubu ni awọn n ba lọ.

Alaga apapọ APGA; Sly Ezeokenwa, lo sọrọ naa lori eto ileeṣẹ amohunmaworan kan l'Ọjọru.

"Koda ki ẹnikẹni too sọ pe oun fẹ dupo yii, ẹgbẹ wa ti duro lori ipinnu pe a maa ṣe atilẹyin fun ẹgbẹ oṣelu APC ati eto Ireti ọtun (Renewed Hope Agenda) ti Aarẹ n ṣe."

Alaga APGA, Ezeokenwa lo ṣalaye bẹẹ.

Tẹ o ba gbagbe, ṣaaju ni Gomina ipinlẹ Anambra, Chukwuma Soludo to jẹ gomina kan ṣoṣo lati inu ẹgbẹ APGA, ti sọ pe Aarẹ to wa lori aleefa lọwọ ni APGA yoo tilẹyin ni 2027.

Iná mọ̀nàmọ́ná máa tó duro ire padà láìpẹ́, àtúnṣe ti bẹ̀rẹ̀ - Tinubu

Aarẹ Bola Tinubu wọ aṣọ agbada APC, o n bọ igbakeji rẹ lọwọ. Iyawo rẹ Remi Tinubu ati ọkunrin to wọ aṣọ dudu wa lẹyin rẹ.

Ààrẹ Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ti fi dá àwọn aráàlú lójú pe atunṣe maa ba ina mọnamọna to n ṣe segesege lẹnu ọjọ mẹta yii laipẹ̀.

Aarẹ ni ọpọ àwọn àtúnṣe lo ń lọ lọwọ lẹka ohun amuṣagbara ina ti ayipada nla yoo si ba ina mọnamọna laipẹ lojuna ati ṣe àtìlẹyìn fún ìdàgbàsókè awọn ilé-iṣẹ́ àti eto ìṣúná orílẹ̀-èdè yii.

Lasiko to n ba awọn ọmọ ẹgbẹ oselu All Progressives Congress (APC) sọrọ níbi apero ẹgbẹ oṣelu naa to n waye ni ilu Abuja ni aarẹ ti sọrọ naa.

O woye pé àwọn ìṣòro to wa pẹ̀lú ìlànà ẹ̀ka ina mọnamọna lati igba pipẹ ṣi wà sibẹ, to si fi kun pe gbèsè pọ tí wọ́n jẹ́ àwọn ilé-iṣẹ́ tó ń peṣe ina mọnamọna (GENCOs) àti àwọn to n pese afẹfe gaasi.

O ni lati igba ti oun ti gba akoso iṣejọba Naijiria ni oun ti n gbiyanju lati mu awọn ileri ti ẹgbẹ oṣelu awọn ṣe fawọn araalu lasiko ipolongo ibo.

O fi kun pe pẹlu gbogbo ipenija ti awọn koju latara eto isuna ati oṣelu, o ni awọn gbiyanju lati maa pese awọn ohun amayedẹrun fawọn ọmọ Naijiria bi o ṣe tọ.

"Yàtọ̀ sí ọ̀nà oju popo, a tún ń ṣe àtúnṣe si àwọn ibùdó ọkọ̀ ojú omi àti ibùdó ọkọ̀ ojú ofurufu.

"A ti bẹ̀rẹ̀ ìmúlò àwọn àtúnṣe owó orí àti ìṣúná tó ṣe pàtàkì. A tún ń ṣe àwọn ètò idokoowo àwùjọ, a sì ń ṣiṣẹ́ láti mú ààbò orílẹ̀-èdè lagbara."

Tinubu tẹsiwaju pe Nàìjíríà ti ń ní àfikún lori bi a ṣe n ta ọja silẹ okeere ju ti tẹlẹ lọ ati pe adinku ti ba owo ti awọn eeyan fi n ra ounjẹ eyi to ti ń mú ìdẹ̀kùn bá àwọn ọmọ orilẹ ede Naijiria.

Máa ṣe gudugudu méje yàyà mẹ́fà tí mo bá lè wọlé ìbò Gómìnà ìpínlẹ̀ Ogun - Iyabo Obasanjo-Bello

Iyabo Obasanjo-Bello wọ aṣọ buba APC ati gele to ba a mu nibi apero ẹgbẹ oṣelu APC niluu Abuja

Iyabo Obasanjo-Bello to jẹ ọkàn lára èèkàn inú ẹgbẹ oselu APC lati ipinlẹ Ogun to wa nibi apero ẹgbẹ naa to n lọ lọwọ l'Abuja sọ pe oun yoo maa se gudu-gudu meje yaya mẹfa ti wọn ba yan oun gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Ogun

Arabinrin Iyabo ni ẹgbẹ APC ti gbaradi fun eto idibo ọdun 2027 to ń bọ lati tun jawe olubori ninu rẹ.

Iyaafin Iyabọ Obasanjo-Bello tun parọwa fun awọn agba ẹgbẹ oselu APC lati tubọ yan n àwọn obìnrin púpọ̀ sí ipò oṣèlú káàkiri orílẹede Naijiria.

O ni eyi kì í ṣe pé yóò mú ìdọ̀gba ba awọn ọkunrin atawọn obinrin, ṣùgbọ́n yóò tún jẹ́ kí ìṣọ̀kan àti ìfọkànbalẹ̀ gbilẹ̀ nínú ètò ìṣèlú.

Iyaafin Iyabo Obasanjo-Bello ni oun ni iriri gẹgẹ bi asofin àti kọmisọna tẹlẹri ni ipinlẹ Ogun.

O tun wá gbosuba fàwọn àgbà ẹgbẹ oselu APC fun isọkan àti ifọwọsowọpọ fun eto ìdìbò abẹnu ti yoo waye l'Abuja.

Iyabo ní èyí yóò je awokọse fun àwọn ẹgbẹ́ oṣelu yòókù.

Ìṣọ̀kan ati ifọwọsowopọ lo le mu Naijiria borí iṣoro eto aabo to mẹhẹ

Ninu ọrọ tiẹ, Minisita fun eto aàbò lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Christopher Musa (tí ó ti fẹ́yìntì), ti jẹ ko di mimọ pe Ààrẹ Bola Tinubu ko ni kaarẹ láti mú eto àlàáfíà àti aabo padà bọ sipo ni gbogbo ipinle to wa jake jado orilẹ ede Naijiria.

Minisita wa rọ gbogbo ọmọ Nàìjíríà pé kí wọ́n ni ssuru, kí wọ́n sì fọwọ sowọ pọ pẹlu ajọ to n mojuto eto aabo láti dojú kọ gbogbo àwọn ìṣòro to n dojukọ eto orílẹ̀-èdè yii.

Minisita náà sọ pé àwọn ìpenija tó wà níwájú orílẹ̀-èdè Naijiria bayii nílò ìfọwọ́sowọ́pọ̀ gbogbo ọmọ orílẹ̀-èdè yii.

Ọgagun fẹyinti Musa sì tẹnumọ́ pé ìdàgbàsókè, àlàáfíà àti ààbò kò lè ṣẹlẹ̀ láìsí ifọwọsowọpọ gbogbo awọn ọmọ orilẹ ede Naijiria ni tile-toko.

Kí ni kókó àpérò ẹgbẹ́ òṣèlú APC tó ń wáyé nílùú Abuja dá lé lórí?

Gbọngan Eagles Square ìlú Abuja tí wọ́n fi aṣọ alawọ pupa ati awọ ewe dara si

Oríṣun àwòrán, Tobi Sangotola

Ni ọjọ Aje, ọjọ Kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹta ọdun 2027 ni apero ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC nibi ti wọn ti maa ṣe eto idibo ti wọn fi maa yan awọn alaṣẹ ẹgbẹ naa.

Ni gbọngan nla Ẹagles Square to wa niluu Abuja ni apero naa ti maa waye tawọn aṣoju ẹgbẹ naa si ti n balẹ si gbọngan naa.

APC jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú ti ko se fọwọrọ sẹyin lorilẹ ede Nàìjíríà, wọ́n dá ẹgbẹ oṣelu APC sílẹ̀ ní oṣù Kejì ọdún 2013 nigba ti ẹgbẹ oṣelu mẹ́rin ni parapọ lati da ẹgbẹ oselu APC silẹ.

Awọn ẹgbẹ oṣelu naa ni Action Congress of Nigeria (ACN), Congress for Progressive Change (CPC), All Nigeria Peoples Party (ANPP), àti apá kan lára All Progressives Grand Alliance (APGA).

Láti ọdún 2015 ni ẹgbẹ oselu APC ti wa lori iṣejọba lorilẹ ede Naijiria nígbà tí wọ́n jawe olubori ninu eto idibo to waye lọdun 2015 ni eyi to gbe oloogbe Muhammadu Buhari wọle gẹgẹ bi aarẹ orilẹ ede Naijiria, ki Bola Ahmed Tinubu naa to jawe olubori gẹgẹ bi aarẹ orilẹ ede Naijiria lọdun 2023.

Ki ni pataki ṣiṣe apero ẹgbẹ oṣelu APC?

Gbọngan Eagles Square ìlú Abuja tí wọ́n fi aṣọ alawọ pupa ati awọ ewe dara si

Oríṣun àwòrán, Tobi Sangotola

Nibi apero gbogbogbo ẹgbẹ oṣelu to wa kaakiri orilẹ ede Naijiria ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ti máa n yan àwọn asoju ti yoo maa ṣe iṣakoso ẹgbẹ naa. Awon aṣoju ẹgbẹ ti wọn yoo yan maa n wá lati wọọdu, ijọba ibilẹ, ijọba ipinlẹ ati ní ẹkùn kọọkan to wa lorilẹ ede Naijiria.

Lara awọn ipo ti wọn maa n yan awọn aṣoju ni alága gbogbogboo (National Chairman), akọ̀wé agba (National Secretary), àtiàwọn ipò míì nínú ẹgbẹ.

Lẹyin ti igbimọ to n mojuto apero naa ba ti sayẹwo gbogbo awọn oludije to n gbero lati ipo kan tabi omiran mu tan ni wọn maa wa ṣe eto ìdìbò lati yan awọn aṣoju fun ẹgbẹ́ wọn.

Àwọn ipò ìṣàkóso wọ̀nyí ní ipa púpọ̀ lórí bí ẹgbẹ́ ṣe máa ṣètò ara rẹ̀, àti bí wọ́n ṣe máa ṣe ipolongo àti ìdíje nínú àwọn eto ìdìbò to maa waye lọjọ iwájú paapaa julọ fun eto idibo ti yoo waye lọdun 2027.

Awọn wo lo ṣeeṣe ki wọn dipo alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu APC mu lẹyin apero yii?

  • Nentawe Yilwatda

Lati ọdun 2025 ni Nentawe Yilwatda ti wa gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ oṣelu APC. Oun naa tun fẹ dije pada gẹgẹ bi alaga gbogbogboo fun nibi apero to n waye naa.

Lẹyin ti gomina tẹlẹ ri ni ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje kọwe fipo alaga ẹgbẹ naa silẹ lọdun 2025 nitori ilera rẹ ni Yilwatda gbakoso ẹgbẹ naa.

Ohun ti a ń gbọ ni pe awọn agba inu ẹgbẹ oṣelu APC ati awọn gomina ti fẹnuko lati tun yan Nentawe Yilwatda pada gẹgẹ bi aarẹ ẹgbẹ.

  • Ajibola Basiru

Ni ọdun 2025 ni oun naa di akọwe apapọ fun APC ti ireti si wa pe oun naa fẹ pada sipo naa lẹyin apero to n lọ lọwọ naa.

  • Ali Bukar Dalori

Oun ni igbakeji alaga ẹgbẹ oselu APC lati ọdun 2025.

Ipo alaga APC ni Dalori n gbero lati dimu bayii lẹyin apero ẹgbẹ.

Ireti wa pe gbogbo awọn alaṣẹ ti wọn di ipo kan mu tabi omiran ni wọn tun dibo yan pada lati di ipo wọn mu ni igbaradi fun eto idibo gbogbogbo to maa waye lọdun 2027.

A ti gbaradi fun apero ẹgbẹ wa - Oyebanji

Gomina ipinlẹ Ekiti, Abiodun Oyebanji ti wa sọ pe gbogbo eto ti to lati jẹ ki apero ẹgbẹ oṣelu naa lọ ni irọwọ rọsẹ, ko si so eso rere,

Oyebanji to jẹ alaga igbimọ to n ṣayẹwo awọn oludije ni ẹgbẹrun mẹjo awọn aṣoju ni awọn n reti ni lati gbogbo ẹkun mẹfa to wa lorilẹ ede Naijiria nibi apero naa.