Amẹ́ríkà àti Iran ní ìjíròrò ń so èso rere àmọ́ kò tíì sí ìfẹnukò

Donald Trump jókòó, ó tọwọ́ bọ inú ara wọn, àwọn ọkùnrin mẹta wà lẹ́yìn rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump ti ní ìjíròrò tó dára ti ń wáyé láàárín Amẹ́ríkà àti Iran lórí ogun tó ń lọ lọ́wọ́ àmọ́ tó ní àwọn kò ní jẹ́ kí Iran bá àwọn lórúkọ jẹ́ nítorí Strait of Hormuz.

Trump sọ fún àwọn akọ̀ròyìn ní ọjọ́ Àbámẹ́ta pé Iran ń ṣe bí wọ́n ṣe máa ń ṣe láti bíi ọdún mẹ́tàdínláàádọ́ta sẹ́yìn.

Bákan náà ló ní bí àwọn ọmọ ogun orí omi Amẹ́ríkà ṣe dí epo Iran mọ́lẹ̀ yóò tẹ̀síwájú títí tí wọ́n fi máa parí ìjíròrò wọn.

Olórí ilé aṣòfin Iran, Bagher Ghalibaf náà fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìjíròrò ń lọ pẹ̀lú Amẹ́ríkà lójúnà àti wá bí ogun ṣe máa parí àmọ́ tó ní àwọn kò ì tíì fẹnukò rárá.

Ghalibaf, tó wà lára àwọn tó ń bá Amẹ́ríkà jíròrò fún Iran, jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó bá igbákejì ààrẹ Amẹ́ríkà, JD Vance ṣèpàdé ní Pakistan ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá.

Kò ì tíì sí ìkéde ìgbà tí ìjíròrò míì tún máa wáyé láàárín wọn.

Wọ́n ti Strait of Hormuz, ṣi fún ìgbà díẹ̀

Ọ̀nà kan gbòógì tí wọ́n ń gbé epo gbà, Strait of Hormuz ni wọ́n tit ì padà lẹ́yìn tí Iran ṣi fún ìgbà díẹ̀ lọ́jọ́ Ẹtì. Ikọ̀ ẹ̀ṣọ́ ààbò Iran, Islamic Revolutionary Guard Corps Navy sọ pé ojú ọ̀nà náà máa wà ní títìpa títí tí Amẹ́ríkà bá kó àwọn ẹ̀ṣọ́ tó fi dí epo Iran mọ́lé.

Bí Amẹ́ríkà ṣe dí epo Iran mọ́lé, wọ́n ní àwọn kò ní jẹ́ ọkọ̀ tó ń gbé epo wọ Iran tàbí jáde rárá. Trump ní ìdèná máa tẹ̀síwájú títí tí wọ́n fi máa fẹnukò.

Ọkọ̀ ojú omi agbépo kan kojú ìkọlù lọ́wọ́ Iran nígbà tó gbé epo gba Strait of Hormuz ní ẹ̀bá Oman gẹ́gẹ́ bí UK Maritime Trade Operations (UKMTO) ṣe sọ.

Èyí ni ìkọlù àkọ́kọ́ tó ń wáyé sí ọkọ̀ ojú ní ẹkùn náà láti bíi ọjọ́ mẹ́wàá sẹ́yìn.

Ẹ̀wẹ̀, iléeṣẹ́ ilẹ̀ òkèèrè India sọ pé àwọn okọ̀ ojú omi agbépo àwọn méjì ló ti kojú ìkọlù ní ojú ọ̀ nà náà.

Iye ìgbà tí ìjíròrò ti ń wáyé láàárín Amẹ́ríkà àti Iran

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Báyìí ni ìjíròrò tó ń wáyé láàárín Amẹ́ríkà àti Iran ṣe ti lọ:

Ọjọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù Kejì: Ogun bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Amẹ́ríkà àti Israel pawọ́pọ̀ ṣe ìkọlù sí Iran bí ìjíròrò ṣe kùnà.

Ọjọ́ Kẹfà oṣù Kẹta: Donald Trump ní kò ní sí ìfẹnukò àyàfi tí Iran bá sọwọ́ sílẹ̀

Ọjọ́ Kọkànlélógún oṣù Kẹta: Trump kéde gbèdéke ọjọ́ tó máa ṣe ìkọlù sáwọn ohun amáyédẹrùn Iran tí Iran bá kọ̀ láti ṣí Strait of Hormuz.

Ọjọ́ Kẹtàlélógún oṣù Kẹta: Trump fi ọjọ́ kún gbèdéke tó gbé kalẹ̀ bó ṣe ní ìjíròrò tó ń so èso rere ń wáyé.

Ọjọ́ Keje oṣù Kẹrin: Trump ṣèkìlọ̀ pé ọ̀làjú máa dópin tí Iran kò bá ṣí Strait of Hormuz kí gbèdéke tó pé.

Ọjọ́ Kẹjọ oṣù Kẹrin: Pakistan kéde ìdádúró ogun fún ọ̀sẹ̀ méjì láàárín Amẹ́ríkà àti Iran láti fi ààyè gba ìjíròrò.

Ọjọ́ Kọkànlá oṣù Kẹrin: Àwọn aṣojú Amẹ́ríkà tó fi mọ́ igbákejì ààrẹ Amẹ́ríkà JD Vance àti Mínísítà fọ́rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè Iran, Abbas Araghchi pàdé ní Pakistan. Lẹ́yìn ìpàdé tó lé ní wákàtí mọ́kànlélógún, wọn kò fẹnukò lórí ohunkóhun.

Ọjọ́ Kejìlá oṣù Kẹrin: Trump kéde dídí epo Iran mọ́lé.

Ọjọ́ Kẹtàdínlógún oṣù Kẹrin: Iran ní àwọn máa ṣí Strait of Hormuz tí ọjọ́ tí wọ́n fẹnukò láti dáwọ́ ogun dúró dè fi máa pé.

Ọjọ́ Kejìdínlógún oṣù Kẹrin: Iran kéde títi Strait of Hormuz padà. Trump ní ìjíròrò ń wáyé láàárín tó dára ń wáyé Amẹ́ríkà àti Iran.