Agbẹ̀bí méjì kó sí gbaga ọlọ́pàá l'Ondo lẹ́yìn ikú ìyá àtì ọmọ tuntun jòjòló méjì

Oríṣun àwòrán, Ondo NPF
Eeyan meji ti ko si gbaga ọlọpaa nipinlẹ Ondo lẹyin iku awọn ọmọ tuntun jojolo kan lasiko ti wọn n bi wọn niluu Akure ati Emure-Ile.
Iṣẹlẹ meji ọtọtọ naa ti mu ki ọpọ maa kọminu lori iku ọmọde ati ipo ti ẹka eto ilera ipinlẹ Ondo wa bayii.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abayomi Jimoh, sọ ninu atẹjade kan pe awọn fi ṣikun ofin gbe awọn afurasi naa lẹyin iku awọn ọmọ tuntun jojolo ati iya wọn to waye ninu oṣu Kẹrin ọdun 2026 yii.
Bi iku ọmọ ati iya kinni ṣe waye
Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹrin yii ni iṣẹlẹ akọkọ to ọlọpaa leti nigba ti obinrin kan, Remilekun fi to ọlọpaa leti pe iyawo ẹgbọn oun ti orukọ rẹ n jẹ Blessing Bawa jade laye lasiko to n bimọ.
Ile iwosan aladani kan ni iku oloogbe naa ti waye lagbegbe Gloryland, loju ọna ilu Ado-Ekiti.
Obinrin kan, Elizabeth Aremu, ti wọn ni o n pe ara rẹ ni agbẹbi lo ni ile iwosan naa.
Ọlọpaa ni ni kete ti oloogbe ọhun bi ọmọ tan ni nnkan yiwọ, o si dakẹ ki wọn to gbe de ile iwosan gidi.
Nigba ti awọn ọlọpaa de ile agbẹbi naa, wọn ri oku ọmọ tuntun jojolo nibẹ, eyii to mu ki wọn fi ṣikun ofin gbe agbẹbi ọhun.
Bi iku ọmọ ati iya keji ṣe waye
Ninu iṣẹlẹ mii to waye ṣaaju lọjọ kọkanla, oṣu Kẹrin yii kan naa, ọkunrin kan, Augustine Kufre, fi to ọlọpaa leti pe ọrẹbinrin oun ọmọ ogun ọdun ti orukọ rẹ n jẹ Jenifer Sunday, lọ sile iwosan kan ni Emure-Ile lati lọ bimọ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, iya wolii kan ti orukọ rẹ n jẹ Blessing Efiong lo n gbẹbi Jenifer.
A gbọ pe ọmọ tuntun jojolo ti Jenifer bi ku sile agbẹbi ọhun, nigba ti Jenifer funra naa jade laye lasiko ti wọn n gbe lọ sile iwosan fun itọju pajawiri.
Iya wolii to gbẹbi ọdọbinrin naa ti wa ni akoto ọlọpaa bayii.
Agbẹnusọ ọlọpaa ni iwadii ti n lọ lọwọ lori awọn afurasi naa, wọn si ti gbe oku awọn iya ọmọ mejeji lọ sibi ti wọn yoo ti ṣe ayẹwo wọn fun iwadii.
Lẹyin naa lo rọ araalu ki wọn maa lọ sile iwosan to gba ontẹ ijọba ki wọn si maa tọ awọn akọṣemọṣe lọ ti wọn ba fẹ bimọ.


























