Dókítà bọ́ sọ́wọ́ NDLEA fún lílọ́wọ́ nínú òwò Cocaine ní ìpínlẹ̀ Ogun

Oríṣun àwòrán, NDLEA
Ajọ NDLEA ti ni ọwọ awọn ti ba Dokita oniṣegun oyinbo kan, Chudi Ofomata, fun pe o lọwọ si gbigbe oogun oloro Cocaine pẹlu ẹnikan ti wọn pe orukọ rẹ ni Gohouri Michael.
Eyi di mimọ ninu atẹjade ti agbẹnusọ NDLEA, Femi Babafemi, fi sita.
Ninu atẹjade naa ni NDLEA ti sọ pe Gohouri Michael, ọmọ orilẹede Côte d'Ivoire to jẹ ẹni ọdun mọkanlelogoji ( 41), ni ọwọ kọkọ ba ni papakọ ofurufu Mallam Aminu niluu Kano.
Ajọ naa sọ pe nigba ti wọn n yẹ awọn ero ọkọ wo ni wọn ri i pe Gohouri ti gbe cocaine ìdì mejilelọgọrin mii, eyi ti iwọn rẹ jẹ 1.49kg.
"Gohouri de siluu Eko lati Milan, Italy, lọjọ kẹtadinlogun oṣu Kin-in-ni ọdun 2026, o si n rin irin ajo laaarin Eko si Enugu fun ọsẹ mẹta.
" O pada lọ si Kano, nibi to duro si fun ọsẹ kan ko to gbe oogun oloro naa mì ni yara otẹẹli to gba.
"Ẹgbẹrun marun-un euro (5,000) ni iye owo ti ko ba gba to ba gbe oogun oloro naa wọ Milan.
" Iwadii fi han pe Gohouri ni ẹnikan nikọkọ to n kọ ọ bi yoo ṣe gbe cocaine naa kọja ni papakọ ofurufu."
Bẹẹ ni apa kan atẹjade naa ṣalaye.
Wọn mu Dokita Chudi
Agbẹnusọ NDLEA naa tẹsiwaju pe iwadii pẹlu titẹlẹmuyẹ lo fi han pe Dokita Chudi Ofomata, ẹni ọdun mọkandinlaadọrin (69) lo wa lẹyin Gohouri.
Ibudo Dokita Ofomata to wa ni Magboro, ipinlẹ Ogun ni wọn ti mu un lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹta ọdun 2026 yii.
Babafemi sọ pe lara nnkan ti NDLEA gba lọwọ dokita nibi ti wọn ti mu un ni ni ohun ti a mọ si promazepam ti iwọn rẹ jẹ 63 grams, ati omi abẹrẹ promethazine meje.
Baba agba ẹni ọdun 93 naa wọ gau nitori oogun oloro nipinlẹ Abia
Yatọ si dokita oniṣegun oyinbo tọwọ ba fun iwa aitọ yii, NDLEA sọ pe baba agba ẹni odun mẹtalelaadọrun-un (93) kan naa wa lara awọn tọwọ tun ba .
Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, Alagba Friday Ahukanna Chigbu ni baba tọwọ ba naa n jẹ.
Ile rẹ to wa ni Umuagbaigba, Amavo Nkwogu, nipinlẹ Abia ni wọn ti mu un lọjọ keje, oṣu Kẹrin yii pẹlu oogun oloro skunk ti iwọn rẹ jẹ 7.7kg.
" Afurasi naa sọ fun wa pe ọmọlanke loun n ti tẹlẹ, koun too kọ iṣẹ ile kikun ati bi wọn ṣe n le taisi mọlẹ.
"Lẹyin eyi lo ni oun darapọ mọ okoowo skunk tita, eyi to ti ju ọdun kan lọ bayii toun ti n ṣe e.
Baba agba Ahukanna sọ pe oun ti n mu skunk lati 1959, koun too sọ ọ di okoowo bayii."
Agbẹnusọ NDLEA lo ṣalaye bẹẹ, pẹlu alaye pe ajọ naa ko ni I sinmi lai rẹyin awọn eeyan to n fi ohun to lodi sofin ṣe ọrọ̀.

























