Wo ohun tí wàhálà àṣejù yóò ṣe sí àwọ̀ ara à rẹ nígbà tó bá rẹ̀ ọ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
To ba rẹ eeyan latari wahala, ti agbara ko si fun onitọhun lati ṣe bo ṣe maa n ṣe tẹlẹ nigba ti ko rẹ ẹ, ọpọ eeyan ni ko mọ pe rirẹ naa maa n nipa lara awọ ẹni to rẹ, ki I ṣe inu ara nikan ni rirẹ maa n ba a.
Awọn onimọ lori rirẹ (Fatigue) ti fidi ẹ mulẹ tipẹ, pe to ba rẹ eeyan, o ni ai daa to n ṣe fun awọ ara.
Pẹlu iwadii lọpọ ọdun sẹyin naa ni wọn fi sọ pe o le jẹ ki awọ eeyan gbẹ furufuru, o si tun le mu ki aisan bii ikọ ife wọle si eeyan lara pẹlu awọn arun mi-in.
Dokita Alia Ahmed, onimọ nipa awọ ara to fi London ṣe ibugbe, ṣalaye pe to ba rẹ eeyan, o le nipa to pọ lori awọ ara.
Bawo ni aarẹ ara ṣe la kan awọ eeyan ?
Ọpọlọ ati awọ ara eeyan maa n wa lati oju opo kan naa nigba ti ọmọ ba wa ninu iya rẹ bii oyun, awọn mejeeji ni ibaṣepọ to sunmọ ara wọn gan-an.
Nigba to ba rẹ wa, ọpọlọ wa yoo maa pese awọn kẹmika kan sinu ẹjẹ wa.
Eyi yoo jẹ ki ẹni to rẹ naa mọ pe nnkan ko lọ daadaa lara oun.
Ṣugbọn ṣaa, awọn ohun to n jade sinu ẹjẹ naa le fun awọn apa ibi kan ni okun, yoo si ko ba awọ ara ni tiẹ.
"Wọn tun maa n ba ẹran ara ti a n ri nita jẹ, eyi to le jẹ kawọn ohun to lewu wọle sinu ara eeyan, to si le fa ki awọ gbẹ furufuru."
Dokita Ahmed lo ṣalaye bẹẹ.
Bakan naa ni rirẹ maa n mu adinku ba awọn ohun to n pa kokoro ara, atawọn eyi to le ṣẹgun kokoro aifojuri.
Paripari rẹ bi Dokita Ahmed ṣe wi ni pe, to ba rẹ eeyan larẹju, yoo koba bi ẹni naa ṣe n sun, yoo si mu ki awọ ara rẹ ma ṣe oju ire.
"Bi awọ ara ko ba jọ lọ, ti eeyan ni aisan kan ti a mọ si psoriasis, yoo tun maa koba bi eeyan ṣe n ṣe lawujọ.
Eyi yoo ri bẹẹ nitori awọn eeyan yoo maa beere lọwọ ẹni naa pe ki lo n ṣe e, iyẹn yoo si tun mu iṣoro awọ ara naa buru fun un ju bo ṣe ro lọ."
Bi o ba din wahala ṣiṣe ku, ṣe yoo ran ọ lọwọ bi?
"Ko maa rẹ eeyan maa n di ohun to lewu nigba ti eeyan ko ba ri ọgbọn da si ohun to n fa rirẹ".
Ọjọgbọn Rajita Sinha, lati Yale University l'America lo ṣalaye bẹẹ.
O ni lasiko to ba rẹ eeyan, ẹni naa le maa ri awọn apẹẹrẹ bii ori fifọ, inu rirun tabi ki ẹni naa ma le sun daadaa.
Koda, o ni o ṣee ṣe ki ẹni naa maa gbagbe nnkan.
To ba ti ri bayii, Ọjọgbọn Rajita Sinha, sọ pe o daa ki eeyan wa ojutuu si I ko si maa ṣe ere idaraya ju ti tẹlẹ lọ.
O ni ẹri wa to fi han pe ere idaraya maa n din rirẹ ku.
O tun ni ki ẹni to ba n rẹ maa mi sinu sita, eyi to n mọ -ọn mọ ṣe yatọ si eemi gbogbo igba, nitori eyi maa n ran ilera ọpọlọ lọwọ.
Dokita Ahmed gba awọn eeyan nimọran lati maa ṣe awọn ere idaraya ori bẹẹdi ki eeyan too sun, ki eeyan maa mi sinu sita lasiko to ba n rin.
Ohun ti awọ ara nilo
Gẹgẹ bi Dokita Ahmed ṣe wi, awọ ara nilo:
Itọju to peyẹ.
Oogun to yẹ ni lilo.
Ounjẹ to daa.
Oorun sisun ati
Gbigbe igbe aye alaafia to tẹle ilana ilera.
O ni eeyan gbọdọ maa ṣe eyi fun igba pipẹ, ki ẹni naa le ri iyatọ lara rẹ, ko si le tete mọ nigba ti ayipada ba de ba awọ ara rẹ.

























