Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé wọ́n tún ń pe ìṣàná ní bíkèlí, ìgbálẹ̀ ní ayílẹ́ ní èdè Yorùbá bí?

Àkọlé fídíò, Àwọn ohun èèlò
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Yorùbá bọ́ wọ́n ní bí èèyàn kò bá dé oko babaẹlòmíràn ó máa sọ pé ti bàbá òun òun ló tóbi jùlọ.

Tí a bá ń sọ̀rọ̀ èdè àdúgbò, onírúurú èdè àdúgbò tí kò ní òǹkà ló wà nílẹ̀ Yorùbá.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ Yorùbá gbà pé Oyo Yorùbá ni èdè àjùmọ̀lò, a ó lè ṣàì gbọ́ ẹ̀ka èdè míì nílẹ̀ Yorùbá kí etí èèyàn má nà.

Bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò ti ẹ̀ mọ̀ pé bí wọ́n ṣe ń pe àwọn ohun èèlò kan ní èdè àdúgbò wọn yàtọ̀ sí ti èdè àdúgbò míì nínú Iran Yorùbá kan náà.

Èyí ló mú BBC News Yorùbá láti máa ṣe àbẹ̀wò sáwọn ìlú nílẹ̀ Yorùbá láti mọ bí wọ́n ṣe ń pe àwọn ohun èèlò èyí tó yàtọ̀ sí Yorùbá àjùmọ̀lò.

Ọ̀kan lára àwọn ìlú nílẹ̀ Yorùbá ni ìlú Oja Odan tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Yewa North ní ìpínlẹ̀ Ogun.

Níbẹ̀ ni a ti ṣe alábàápàdé àọn èèyàn méjì tí wọ́n sì sọ bí wọ́n ṣe ń pe àwọn ohun èèlò bíi ìṣàná, ẹ̀kọ, ìgbálẹ̀, iyẹ̀pẹ̀, ìkòkò ìsebẹ̀ fún wa ní ẹ̀ka èdè àdúgbò wọn.