Aworan àrà to n ṣafihan Donald Trump nibi to ti n naka si olori Iran tẹlẹ, Ayatollah Ali Khamenei, lapa osi. Aworan ibi yii ni awọ ewe,loke, isalẹ rẹ si n tan ina pupa. Awọn kinni to n ru eefin wa nitosi, irinṣẹ ogun wa nibẹ pẹlu ati baaluu kan to n fo, gbogbo rẹ ṣe rẹgi bi wọn ṣe to lera wọn. Apapọ aranbara gbogbo yii si n kede agbegbe ẹkun oṣelu, ibẹru awọn ologun ati agbara  ati da ileeṣẹ gbe kalẹ

Bi ibugbamu ado oloro lati Iran ṣe ko jinni-jinni

Ọsẹ meji ti wọn bẹrẹ ,awọn eeyan agbaye si ti n ri ọwọja ija yii kaakiri

Ikede kan to n waye lati gba agbara ado oloro Iran, ti ikọ ogun oju omi rẹ ati erongba yowu ti won ni lati ṣe nnkan ija ogun ti da rogbodiyan to n dunkoko mọ iduro ṣinṣin ọrọ aje lẹka-jẹka ati kari aye silẹ.

Bi ijiya to lagbara si ti kọlu wọn to, ikọ Iran ṣi duro, wọn n sa agbara lọna tuntun to kun fun ewu.

Ẹkun Aarin Ila-Oorun paapaa n mi titi pẹlu bi nnkan ṣe n tuka, eyi ti Aarẹ Donald Trump juwe rẹ bii iriri ti ko ni i pẹ́

Fun awọn eeyan Iran, ti Trump n rọ lati gba ijọba wọn,asiko yii nira pupọ.

Iran-ẹkùn to n tiraka agbara lagbegbe ti nnkan ti le yi biri nigbakigba

Iran-ni awọn adojukọ kan. O tobi gidi gan ju Iraq ati Afghanistan ti wọn jẹ alamuleti rẹ lọ bi a ba pa awọn iyẹn pọ-Orilẹede meji ti idasi US pada di ija nibẹ fun ọpọ ọdun.

Awọn nnkan elo ologun rẹ, bii eto ṣiṣẹ nnkan ija ogun pọ kaakiri orilẹede nla kan, nigba mi-in abẹ ilẹ lori apata ni wọn yoo lọ ri i mọ́.

Aworan atọna Iran kan ṣafihan awọn ibudo nnkan agbara ti wọn tan ina si pẹlu diamọndi, ati ibudo ikọlu US//Israel titi di ọjọ kejila oṣu Kẹta, wọn fi awọ pupa rondo ṣe ami si i. Akọlẹ kan wa ti wọn kọ Tehran si. Ami pupa yẹn fọn kiri ọpọ orilẹede naa,pẹlu ọpọ rẹ to ṣujọ sawọn ilu nla nla lojuna odo ni Guusu.

Awọn eeyan rẹ ti wọn le ni miliọnu marundinlaadọrun-un jẹ ẹya oriṣiriṣi-Idaji wọn jẹ ẹya Persia, amọ awọn ti wọn ko pọ bii ẹya naa wa pẹlu, to fi mọ Azerbaija, Kurds ati awọn Arab.

Lati ọdun 1979 ni wọn ti bẹrẹ ijọba ẹsin Islam nibẹ, o si fẹsẹ mulẹ gidi pẹlu eto to ṣe rẹgi.

Pẹlu bi ikọlu mẹrin ṣe ti waye ṣaaju loṣu Kẹrin ọdun 2024, ti Israel gbe ikọlu de, ti US naa kọlu lẹẹkan, bi wọn ṣe mu agbara koko ko ruju rara, wọn ṣe afihan rẹ loṣu Kin-in-ni, nigba to koju awọn iwọde ọlọpọ eeyan ti ko ba waye.

Rogbodiyan n ja ran-in bii ina inu ọyẹ kaakiri ẹkùn naa.

Atọna Middle East to n ṣafihan Iran ninu aṣọ pupa laarin, ti Israel si wọ aṣọ pupa ni bebe Iwọ-Oorun. Ayika awon ilu to mule ti wọn ni wọn ni awọ eeru lai ni atọka. Atọna naa ṣafihan bebe okun Mediterranean, ti Iran to bẹrẹ lati Persia de Aarin Gbungbun Asia.

Ogun naa bẹrẹ pẹlu iya gidi fun ikọ alaabo Iran, awọn nnkan ija wọn ati duroonu. Ninu ati nita Gulf, ọpọ ọkọ oju omi awọn Iran ni wọn rì. Olori Iran,Ayatollah Ali Khamenei ati awọn eekan nijọba rẹ ni wọn pa lọjọ kan ṣoṣo.

Atọna kan to n ṣafihan agbegbe Aarin Ila-Oorun pẹlu awọn orilẹede to pọ ti wọn ni awọ pupa, titi kan Syria, Iraq, Jordan, Kuwait, Bahrain,Qatar, Saudi Arabia, UAE ati Oman. Wọn fi aala kaluku han, orilẹede kọọkan si ni orukọ tiẹ lara. Awọn orilẹede alamuleti lo fi awọ eeru han.

Ogun naa tete tan kalẹ pẹlu bi Iran ṣe kọlu Israel atawọn ibi to ni i ṣe pẹlu America, ti wọn n lo ado oloro ati eyi ti a mọ si duroonu. Awọn orilẹede ilẹ Araabu ti wọn ti ro pe awọn ko ni i da si ogun naa , ba ara wọn laarin ogun.

Atọna Aarin Ila-Oorun to gbe Lebanon han lapa Ila-Oorun Mediterranean. Ibi to fẹ ju, titi kan Iran ati etikun Arab ni wọn kun lawọ pupa lati ṣafihan ibi to de ati ọwọja rẹ.

Ni Lebanon, ija ọlọdun pipẹ to wa laarin Israel ati Hezbollah to jẹ ọrẹ timọtimọ fun Iran tun dide pada, o si dena ipinnu didawọ ogun duro ti wọn ṣe loṣu Kọkanla ọdun 2024.

Atọna to fi Turkey han ni Aarin Ila-Oorun, Cyprus ati Azerbaijan pẹlu akọle. Apa ibi to tobi ju-titi kan Iran, agbegbe omi Arab ati awọn orilẹede to yi wọn ka-ni wọn kun lọda pupa lati fi apa ibi to tobi ju han.

Ija naa tan de Aarin Ila-Oorun. Laaarin ọjọ diẹ,wọn ti kọlu ibudo ilẹ Gẹẹsi, iyẹn RAF to wa ni Akrotiri,Cyprus. Ọkọ oju omi Iran kan to n rin loju omi ni Sri Lanka ni ikọ America tẹ ri. Wọn gba awọn nnkan ija oloro ti wọn doju ẹ kọ Turkey lọwọ wọn, wọn si lo awọn duroonu wọn lati koju Azerbaijan.

Atọna nla kan n ṣafihan agbegbe Aarin Ila-Oorun, wọn kun pupọ rẹ lọda pupa, eyi kan Iran,agbegbe omi Arab, Iraq, Syria, Jordan ati awọn agbegbe to yi i ka. Wọn ko da orukọ kọ sara awọn orilẹede kọọkan nibi,awọn to han fi ibi to tan de han ni.

"Ogun ki i jokoo jẹ tabi dun un wo laarin ibode," Tom Fletcher, Adari to n ri si nnkan amayedẹrun lasiko pajawiri ninu ajọ UN.

Ireti di ibẹru ati ifoya.

Laaarin pipa awọn olufẹhonuhan to ti ọwọ awọn to n ṣelu wa loṣu Kin-in-ni,awọn eeyan Iran gbọ ti Trump n ṣeleri pe iranlọwọ de tan.

Nigba to de tan lopin oṣu Keji, inu awọn kan dun si i. Fidio ṣafihan awọn eeyan Iran to n ṣajọyọ pe wọn ti pa olori wọn.

Ṣugbọn bi onka iku awọn araalu naa ṣe ti pọ si,ireti wọn ti di ibẹru. Ninu ikọlu kan to waye nile ẹkọ alakọọbẹrẹ ni Minab, o kere tan, eeyan ọgọjọ ti pupọ wọn jẹ ọmọde ni wọn pa. Ninu ikọlu mi-in, wọn n wa awọn to yè labẹ ilẹ kan ti ikọlu ba ni Ila-Oorun Tehran ni.

Aworan lati ara fidio kan to fi ohun to ṣẹlẹ lẹyin ikọlu ile to wa ni Resalat Square ni Ila-Oorun Tehran han. O ṣafihan apa kan ibi to ti bajẹ nibi ile naa pẹlu ogiri ita rẹ to ti bajẹ tan ati inu ile to ti bajẹ gidi.
Ile naa to wa ni Resalat Square ni Tehran ree ni kete ti ikọlu ba a.

Ajọ UN sọ pe o to miliọnu mẹta ati ẹgbẹrun meji eeyan to ti di alainile lori , bawọn eeyan Iran ati awọn ogunlende ọlọdun pipẹ ṣe n kuro niluu naa lati wa ibugbe si apa ibomiran. Ni Guusu Lebanon, o kere tan eeyan ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin (800,000) lo ti di dandan fun lati fi ibugbe wọn silẹ lẹyin aṣẹ to ni ki wọn kuro.

Ogun yii ko mu idẹrun ba awọn to bẹrẹ rẹ naa. US ati Israel naa ti padanu diẹ ninu awọn ọmọ ogun wọn. Awọn araalu naa ti ku pẹlu, titi kan awọn ọmọ Israeli mẹsan-an to ku nigba ti ado oloro Iran ba ibudo bọọmbu niluu Beit Shemesh lọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹta.

Ohun to n mu ibẹru wa ju ni pe lẹyin tawọn eeyan ba koju gbogbo ijiya yii tan, awọn ẹlẹsin yii naa ni yoo ṣi tun maa ṣejọba lọ, orilẹede ẹlẹsin Islam naa ni yoo si maa dari lọ
Obinrin kan lati Karaj, Iran

Wọn gbena woju duroonu US pẹlu awọn nnkan ija ti ko le

US ti fi ọpọ ọsẹ ko ikọ ologun to tobi julọ jọ latigba ti wọn ti wọ Iraq ni 2003, to fi mọ ikọ onikọlu meji ati ọpọ baaluu.

Israel ati US, laaarin wọn, ni gbogbo nnkan ija ti eeyan le ronu ẹ. Wọn le yin awọn ado oloro to yara ti ko si ki n tase, lati ọna jinjin lati kapa agbara yowu ti ologun Iran ba fẹ sa. Wọn si le mu un ni koko pẹlu obitibiti bọọmu ti iye rẹ fẹrẹ ma tan mọ.

Akọwe eto aabo fun US
Won ko bẹrẹ ija yii nilana pinpin ire ati la a ire latilẹ.
Pete Hegseth
Akọwe eto aabo fun US

Iran naa ko kere, bo ti ẹ n dinku ni ipele awọn nnkan ija ati duroonu , o le maa tọju awọn kan, ṣugbọn lẹyin ọsẹ meji, eyi ti wọn n lo n dinku si i ni.

Amọ o ṣi ku lara wọn naa, bi wọn ṣe kọlu awọn tanka loju omi pẹlu lilo awọn nnkan ija ti ko han ati iku ologun oju omi. Duroonu ti fi han pe yoo ṣoro lati ridi eyi tabi lati ba a jẹ, o si le mu ogun yii pẹ si i .

Ijọba sọrọ latari awọn nnkan to n gbowo leri

Ọwọja ogun yii ti kari ọrọ aje agbaye lọna ti ile agbara America paapaa ko rokan.

Ọna tin-in-rin Hormuz, nibi ti o kere tan, ida ogun epo agbaye n gba kọja ni wọn ti di pa..

Asia meji lẹgbẹẹ ara wọn to n ṣafihan ọkọ to n kọja ni oju ọna Hormuz-ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Keji ọdun 2026. Awọn ami pupa to ki n fi han pe awọn ọkọ oju omi wa nibẹ ki rogbodiyan too de lọjọ kẹjọ oṣu Kẹta 2026:Awọn ami pupa ti ko pọ naa wa nibẹ, to n ṣafihan agba epo to kere jọjọ to n kọja. Akọle kan ṣalaye pe wọn maa n ka iye àgbá to wa nikalẹ nipa lilo onka oniwakati.

Ọpa epo Saudi kan lapa Okun Pupa, ati ọna kekere to ja si Oman lati United Arab Emirates, le ṣe iranwọ lati ri ojutuu si didipa yii. Ṣugbọn lasiko yii na, ai to epo ati afẹfẹ gaasi jẹ iṣoro to kari aye.

Koda, o ṣoro lati sọ pe ibi kan wa ti ko maa koju iṣoro yii lẹka ọrọ aje lagbaaye, bẹrẹ lati ẹka irinna ofurufu titi de ọgbin,ike ati gbigbe wọn kọja.

Ila mẹfa ṣafihan bi owo epo, gaasi, epo jẹẹti, urea, ajilẹ, alumi ati wiiti ṣe n lọ lati oṣu mẹfa sẹyin. Ila kọọkan n fi ibi ti ikọlu US ati Israel lara Iran wa han.  Awọn owo ọja naa gbera soke kia kete lẹyin ọjọ ti wọn ṣe ami si.

Ni Philippines, awọn oṣiṣẹ kan n ṣiṣẹ fun ọjọ mẹrin laarin ọsẹ lati din irinajo ku. Ni Thailand, wọn n gbe ẹrọ amuletutu wọn si odiwọn 26C (79F) ninu awọn ọfiisi ijọba lati din bi wọn ṣe n lo ina ku. Ni Myanmar, ijọba ologun to wa nibẹ ti ni ọkọ adani ki i ṣe wiwa lojoojumọ mọ, ki wọn maa yọ ọ sira wọn ni.

Ni Britain ati Europe, ijọba sọ pe oun yoo gbe igbesẹ lori awọn to n fowo kun un, wọn ni o jọ pe awọn ileeṣẹ agbara n fi ohun to n ṣẹlẹ yii pawo sapo ara wọn.

Ni US,owo epo bentiroolu n gunke si i, pẹlu bi Trump ṣe leri lati mu un wa silẹ to.

Irinajo ati afẹ paapaa ti tọ wo ninu inira yii, paapaa ni Qatar ati UAE, ibi meji pataki lagbaaye. Papakọ ofurufu Dubai, to n ṣakoso eeyan to to igba ati aabọ ero ọkọ lojumọ nibẹrẹ ọdun 2025, ni ikọlu ado oloro Iran ti ba lọpọ igba bayii.

Ẹgbẹẹgbẹrun arinrinajo lo ti sa kuro nibẹ latigba ti ogun yii ti bẹrẹ.

Laipẹ yii ni awọn tanka naa koju ikọlu lati Iran. .Bi agbara nla lati Israel ati US si ṣe doju kọ wọn, o han pe Iran naa ti pinnu lati maa koju wọn lọna ti ko le, ti ko na wọn lowo pupọ ṣugbọn ti ipa rẹ buru jọjọ

Iyalẹnu nla ba awọn alajọṣe US

Aworan to fi orukọ Israel ati United States han, ti wọn kọ si ara asia wọn.

Orilẹede meji pere lo fẹ ogun yii. Benjamin Netanyahu, Olootu ijọba Israel ti fi han tipẹ pe oun fẹ rẹyin ijọba kan ti oun ati ọpọ ọmọ Israeli gba pe o le fopin si iwalaaye awọn Jew. Donald Trump n fẹ pana erongba nnkan agbara Iran lọwọ kan.

Ṣugbọn bawọn olori mejeeji ṣe ni erongba ijẹgaba kan naa, ko foju han boya boya ẹnikẹni ninu wọn ti ro ohun ti yoo ṣẹlẹ lẹyin rẹ. Ohun ti awọn mejeeji n sọ ni pe awọn fẹ kawọn eeyan Iran le da duro ni, ṣugbọn idaamu ti ogun naa le mu wa ko jọ pe o kan eyikeyi ninu wọn.

Aworan to ni orukọ Saudi Arabia, United Arab Emirates, Kuwait, Bahrain, Qatar ati Oman lara pẹlu asia wọn.

Fun awọn ọre Washington nilẹ Araabu, titi kan Saudi Arabia ati UAE, iyalẹnu nla ni ogun yii jẹ fun wọn.Pupọ wọn n fura si Iran, ẹru si n ba wọn de aaye kan, ṣugbọn wọn ti jagbọn ọna ti wọn fi n ba awọn ẹni nla ti wọn mule ti yii ṣe. Wọn mọ pe Iran le da rogbodiyan ti yoo mi agbaye silẹ, ṣugbọn yoo wu wọn lati sọ asọye ju lilo ipa lọ. Oman ro pe oun ti ri aṣeyọri ṣe lati mu alaafia wa laaarin US ati Iran lori nnkan ija ogun. Wakati diẹ si igba ti ogun naa yoo bẹrẹ, lati le sare dẹkun wahala, minisita ọrọ ilẹ okeere rẹ gba ori amohunmaworan US lọ, o si ni adehun kan wa ni ikawọ awọn.

Aworan to ni orukọ United Kingdom lara, ti wọn si tun ya a si asia rẹ

Siwaju si i,awọn alajọ US mi-in n koju idaamu gidi. Ẹni to si jọ pe idaamu naa ba ju ni Olootu ilẹ UK;Sir Keir Stamer, ẹni to ti tiraka lati ma ṣe da si ogun naa ati titẹle ohun ti UK n fẹ pẹlu awọn alajọṣe .Nigba ti ọrọ nipa boya ki wọn ran ikọ ogun naa le jẹ sisọ lọna ofin, bo ṣe ṣoro lati ṣe ti fi han pe agbara ikọ ologun oju omi Britain ti ko ṣee koju tẹlẹ ti di ofege.

Aworan alafọwọya to ni orukọ Russia ati China lara, ati asia wọn.

Lara awọn alajọṣe Tehran, Russia le kabaamọ ibajẹ to ṣẹlẹ si Iran, ṣugbọn bi adinku ṣe ba owo to n wọle lati ibi epo yoo fun Moscow ni agbega laaarin ogun ọwọngogo to n ja ni Ukraine.

China, ilu to n lewaju ninu awọn to n ko epo Iran wọle lagbaaye, yoo maa wa ọna abayọ mi-in bayii pẹlu owo to ju ti tẹlẹ lọ. Bakan naa ni Beijing ko ti i ri ọna lati dena ikọlu lori orilẹede to ni ajọṣe to kun rẹrẹ pẹlu.

Awọn aarẹ US to ti gba ipo yii kọja ti sọrọ nipa pe kawọn kuku maa ba Asia sọrọ, kawọn si kọju si igbiyanju US lati koju iṣoro ọrọ aje ati ti ologun ti China n gbe wa. Ogun to n lọ ni Iran yii tun fi han pe agbegbe Middle East to tobi ni ọna kan to le gba mu America. Ilana aabo Trump ti wọn gbe jade loṣu Kọkanla to kọja, ṣalaye pe agbara Iran ti lọ silẹ gidi, ati pe agbegbe Aarin Ila-Oorun ti ṣe bẹẹ di ibi ti ijangbọn wọn ti dinku.

"Awọn ọjọ ti Aarin Ila-Oorun gba ofin America kari fun igba pipẹ ati fun lilo lojoojumọ." wọn ni awọn dupẹ pe iru rẹ ti kọja lọ.

Afi to ba jẹ pe.

Data

Institute for the Study of War and AEI's Critical Threats Project, Nuclear Threat Initiative, International Atomic Energy Agency, Global Fishing Watch, Bloomberg.