Iran tako ìgbésẹ Amẹrika láti parí ogun tó ń lọ, sọ nǹkan márùn ún tó lè mú wọn dá ogun dúró

Ile ori oke ti wọn ju ado oloro si

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Orilẹede Iran ti tako erongba Amẹrika lati pari ogun to n lọ lọwọ laarin wọn.

Ileeṣẹ iroyin Iran sọ pe nnkan marun un ti Amẹrika ni kawọn o ṣe ti pọju.

Ileeṣẹ tẹlifisan Iran ni adari eto aabo ni Iran ti wọn ko darukọ rẹ lo sọ pe awọn ko tii ṣetan lati jogun o mi.

O ni Iran yoo jogun o mi ti wọn ba ṣetan ati nigba ti Amẹrika ba faramọ gbedeke nnkan marun un tawọn sọ fun wọn wi pe wọn gbọdọ ṣe.

Lọpọ igba lawọn abẹnugan ijọba Iran ti n sọ pe awọn fẹ ki ogun naa pari patapata ni, awọn ko fẹ ki ogun o mi lasan.

Wọnyi ni nnkan marun un ti Iran n beere lọwọ Amẹrika lati le pari ogun to n lọ:

-Idaduro ikọlu ati iṣekupani

Agbekalẹ adehun eyi ti yoo mu Amẹrika gba pe ogun ko ni ṣẹlẹ mọ ni orilẹede Iran.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Idaniloju loju wi pe Amẹrika yoo sanwo gbamabinu fun Iran lori awọn nnkan to ti bajẹ.

Fifi opin si ogun to n lọwọ kaakiri ẹkun Middle East

-Gbogbo agbaye gbọdọ gba wi pe Iran lagbara lori oju ọna omi okun Strait of Hormuz.

Ileeṣẹ tẹlifisan Press Tv sọ pe Amẹrika ti n wa orṣiiriṣii ọna lati ba Iran sọrọ lori a ti pari ogun naa.

Ẹwẹ, bi gbogbo agbaye ṣe n reti ki ogun naa pari ni Iran ati Israel tẹsiwaju lati maa ju ado oloro sira wọn.

Ṣaaju ni Iran ti sọ pe irọ nla lọrọ ti Aarẹ Donald Trump sọ pe Amẹrika ti n jiroro pẹlu Iran lati pari ogun naa.

Agbẹnusọ apapọ ileeṣẹ ologun Iran, Ebrahim Zolfaqari, sọ lori ẹrọ tẹlifisan wi pe Iran ko le ba iru eeyan bii Trump sọrọ.

O ni Amẹrika lo n bara wọn sọrọ nibi ti ọrọ de duro bayii.

Agbẹnuso ileeṣẹ ijọba Iran to n ri si ọrọ ilẹ okeere, Esmaeil Baghaei, sọ pe Iran ko le fọkan tan Amẹrika rara.

Baghaei sọ pe nnkann ti Iran n ṣe bayii ni lati daabo bo orilẹede naa.

Ẹgbẹẹgbẹrun eeyan lo tik u bayii ninu lati bii ọsẹ mẹrin ti ogun naa ti bẹrẹ.

Ogun ọhun si ti ṣakoba fun ọrọ aje epo rọbi kaakiri awọn orilẹede agbaye.

Awọn ọkunrin meji mu iya agba kan dani lori pangulutu ile ti wọn ju ado oloro si

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Erongba Amẹrika lati ogun to n lọ ni Iran

Ile iwe iroyin New York Times sọ nipa nnkan mẹẹdogun ti Amẹrika n fẹ lati fi jẹ ki ogun to n lọ ni Iran pari.

Ileeṣẹ iroyin Israel Channel 12 sọ pe Amẹrika fẹ ki ogun naa o mi kawọn le jiroro pẹlu Iran lori nnkan mẹẹdogun naa.

Ileeṣẹ iroyi n Israel ni ọkan lara nnkan mẹẹdogun naa lati ba nnkan ija olori Iran jẹ.

Nnkan miran ni pe ẹgbẹ Hezbollah ko gbọdọ ṣatilẹyin fun Iran mọ lati Lebanon.

Ohun miran ijiroro lori a ti ṣi ọna ori okun Strait of Hormuz.

Lati igba ti ogun naa ti bẹrẹ ni Iran ti n ju ado oloro sawọn ibudo ologun Amẹrika to wa lawọn orilẹede to yi i ka.

Bakan naa tun ni Iran tun di ọna ori omi okun Strait of Hormuz tawọn orilẹede agbaye maa n gba gbe epo rọbi kọja.

Ẹwẹ, olootu ijọba Pakistan, Shehbaz Sharif, ti sọ pe oun ṣetan lati ṣe agbatẹru ijiroro Amérika ati Iran lati pari ogun to n lọ.

Orilẹede Pakistan ni ibaṣepọ to dan mọran pẹlu Iran ati Amẹrika.

Bi ọrọ lori ijiroro laarin Amẹrika ati Iran ṣe n lọ lọwọ, iroyin kan fidi rẹ mulẹ pe o ṣee ṣe ki ẹgbẹẹgbẹrun ọmogun ti wa lọna si ẹkun Middle East bayii lati Amẹrika.