Àwọn jàndùkú agbébọn ṣekúpa sọ́jà mọ́kànlá, ọlọ́pàá kan, Gómìnà ṣàtìlẹ́yìn ìrànwọ́ fáwọn ẹ́bí olóògbé

Ajona ku ọkọ awọn sọja tawọn agbebọn dana sun ni Kebbi

Oríṣun àwòrán, KGSG

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

O kere tan ẹṣọ eleto aabo mẹtala lawọn janduku agbebọn ti ṣekupa nipinlẹ Kebbi lẹkun iwọ oorun ariwa orilẹede Naijiria.

Iroyin fidi rẹ mulẹ pe ọpọ eeyan mii lo farapa nibi iṣẹlẹ naa.

Lalẹ ọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii ni iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ ni Giro Masa ni ijọba ibilẹ Shanga ni ipinlẹ Kebbi.

Ohun ti a gbọ ni pe awọn agbebọn naa ti lọ sa pamọ sibi kan de awọn ẹṣọ eleto aabo naa, wọn si ṣina ibọn bolẹ le wọn lori nibi ti wọn ti n lọ sibi tawọn eeyan kan ti ranṣẹ pe wọn.

Awọn alaṣẹ agbegbe ti iṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ fidi rẹ mulẹ pe sọja mọkanla ati ọlọpaa kan lo wa lara awọn to padanu ẹmi wọn naa.

Iroyin tun fidi rẹ mulẹ pe ọkọ awọn oṣiṣẹ eleto aabo meji ni wọn tun dana sun ninu ikọlu ọhun.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kebbi sọ pe oun ko le sọrọ lori iṣẹlẹ naa tori awọn ọmogun lo ṣẹlẹ si.

A gbọ wi pe Gomina Nasir Idris ipinlẹ Kebbi ti ṣabẹwo si ibi ti ikọlu naa ti waye atawọn to farapa ninu iṣẹlẹ ọhun nile iwosan.

Gomina Idris ṣapejuwee iṣẹlẹ naa gẹgẹ bi eyi to buru jai.

Gomina Idris ṣalaye pe awọn ẹṣọ eleto aabo gbọ pe awọn janduku agbebọn fẹ ṣiṣẹ laabi nibi kan ni wọn ṣe gbera lọ si bẹ lai mọ pe ọrọ ko ri bẹẹ.

Gomina ipinlẹ Kebbi wa ṣeleri lati ṣatilẹyin fun ẹbi awọn to ku ninu ikọlu naa.

Bakan naa ni gomina tun ṣeleri lati sanwo itọju awọn to farapa to n gbatọju nile iwosan.

Ọgbẹni Idris tun sọ pe oun yoo ra ọkọ mii fawọn ẹṣọ eleto aabo.

Ibẹru-bojo ti gbalẹ kaakiri igberiko ipinlẹ Kebbi tori awọn agbebọn

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọpọ eeyan lo n tọka sawọn agbebọn to ti n ṣọṣẹ ni Kebbi ati ipinlẹ Sokoto wi pe o ṣee ṣe ko jẹ pe awọn lo ṣe ikọlu naa.

Awọn olori agbegbe sọ pe ibẹru-bojo ti gbalẹ kaakiri igberiko ọhun debi wi pe awọn agbẹ ko le lọ soko mọ tori ẹru awọn agbebọn.

Iṣẹlẹ yii tun ṣapejuwee bi eto aabo ṣe mẹhẹ si lẹkun iwọ oorun ariwa orilẹede Naijiria nibi tawọn agbebọn ti n ṣoṣẹ.

Bi ẹgbẹ agbesunmọmi Boko Haram ti n ṣọṣẹ lẹkun ila oorun ariwa ni lawọn n agbebọn n ji maalu atawọn eeyan gbepawo lẹkun iwọ oorun ariwa.

Awọn onimọ nipa eto aabo sọ pe bi ipinlẹ Kebbi ṣe sun mọ orilẹede Niger jẹ ọkan lara idi ti ikọlu awọn agbebọn fi n ṣẹlẹ lera lera nibẹ.

Ikọlu tawọn agbebọn ṣe sawọn ẹṣọ alaabo ti ṣafihan bi wọn ṣe lagbara to ati bi wọn ṣe n ṣiṣẹ.

Ni apa ila oorun ariwa, ọpọ sọja ni iroyin sọ pe awọn agbebọn ti ṣekupa ni ibẹrẹ ọdun 2026 yii.

Ileeṣẹ ologun Naijiria ko tii ṣalaye lẹkunrẹrẹ nnkan to ṣẹlẹ nibi ikolu ọhun.

Amọ, ileeṣẹ ologun ti kawọn ọmogun lọ si Shanga ati ayika rẹ, awọn ọmogun si ti n wa awọn agbebọn kiri ninu igbo nibẹ.