Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Ẹ gbà mí o, ẹni tí mo ṣèèṣì fi ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n ránṣẹ́ sí kọ̀ láti dáwó mi padà

Ọkùnrin kan Ani Gerald Chukwuebuka, ló ké gbàjarè bẹ́ẹ̀

Chukwuebuka ní gbogbo ìgbìyànjú òun láti gba owó náà ló já sí pàbó

Nítorí ọmọbìnrin tí òun sanwó náà sí àṣùwọ̀n owó rẹ̀ tí búlọ̀ọ̀kù òun

Wo àwọn ọ̀nà tí o lè gbà láti gba owó rẹ̀ padà tí o bá ṣèèṣì san owó sí àṣùwọn ẹlòmíì lójú òpó wa

xxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxx

Ìdẹ̀rùn dé fáwọn òṣìṣẹ́ nípìnlẹ̀ Ogun

Bí ìjọba ṣe kéde fífún àwọn èèyàn ní ìsinmi lọ́jọ́ kan láàárín ọ̀sẹ̀

Láti mú ìdẹ́kùn bá àwọn òṣìṣẹ́ lórí làásìgbò tí wọ́n ń kojú kí wọ́n tó dé ibiṣẹ́

Nítorí àlékún tó ti bá owó epo tí owó ọkọ̀ sì ti lékún

Ìjọba tún kédé fífún àwọn òṣìṣẹ́ ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lóṣóòṣù

Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn náà wà ní bbc news yorùbá

xxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxx

Àwọn aráàlú ní ìyalẹ́nu ni ìkéde dídáwọ́ ogun dúró ní Lebanon jẹ́ fún àwọn

Báwọn aláṣẹ ìjọba kan ṣe ń fẹ̀sùn kàn pé àwọn kò mọ̀ nípa rẹ̀

Wọ́n ní níṣe ló dàbí Netanyahu kàn ǹ ṣe ìfẹ́ inú Amẹ́ríkà ni