Àlàyé lórí ọ̀nà tuntun tí Amẹrika fẹ́ gbà láti fìyà jẹ orílẹ́èdè Iran

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ogun to n lọ lọwọ laarin Amẹrika, Israel ati Iran ti n ṣakoba nla fun ọpọ orilẹede agbaye lẹyin ọsẹ mẹta ti ogun naa ti bẹrẹ.
Aarẹ Donald Trump ti n sọ pe o ṣee ṣe ki ogun naa pari laipẹ yii, amọ, ọrọ Trump tako nnkan to n ṣẹlẹ ni Iran lọwọ yii.
Idi ni wi pe awọn ọmogun Amẹrika to fi mọ awọn ọmogun oju omi ti wa loju ọna wọn bayii si ẹkun Middle East.
Bakan naa ni Trump tun sọ pe irọkẹkẹ ogun naa ti n lọọlẹ, ṣugbọn Amẹrika ati Israel ko dẹkun jiju ado oloro si Iran ti Iran naa si n daa pada fun Israel atawọn ibudo ologun Amẹrika to wa lawọn orilẹede to yi Iran kan lẹkun Middle East.
Ọna ori omi okun Strait of Hormuz ti wọn n gbe ida 20% epo rọbi lagbaaye gba ti Iran ko jẹ ki gbogbo orilẹede maa ri gba mọ jẹ nnkan to n ṣakoba gidi fun ọrọ aje awọn orilẹede agbaye bayii.
Ni bayii, awọn ọkọ oju omi ti Iran ba fọwọ si nikan lo n gba Strait of Hormuz kọja.
Trump ni Amẹrika ti ba ileeṣẹ ologun Iran jẹ, amọ, Iran si tun n ju ado oloro si oriṣiiriṣii ibudo Amẹrika lẹkun Middle East.
Aarẹ Amẹrika tun kilọ fun Iran wi pe ti ko ba ṣi ọna Strait of Hormuz lori omi, awọn yoo ṣekọlu nla sile iṣẹ amuṣagbara Iran.
Trump tun sọ pe Amẹrika ti sọ asọyepọ pẹlu Iran, idi si niyii toun fi sọ pe kawọn ọmogun Amẹrika dawọ ikọlu si ileeṣẹ amusagbara Iran duro.
''Amẹrika n gbero lati gbẹsẹ le erekusu Kharg Island nibi ti Iran n ko epo rọbi to n ta silẹ okeere pamọ si''
Awọn onwoye sọ pe Amẹrika n gbero lati gbẹsẹ le erekusu Kharg Island nibi ti Iran n ko epo rọbi ti wọn n ta silẹ okeere pamọ si.
Iru igbesẹ yii yoo dena ibi ti Iran ti n pa owo, eyi si le jẹ ki wọn gba nnkan ti Amẹrika ba sọ fun wọn lati pari ogun to n lọ lọwọ.
Lọjọ Ẹti to kọja ni Trump sọ pe oun o gbero lati ko ọmogun oriilẹ lọ si Iran, amọ, o fikun ọrọ rẹ pe oun maa sọ fawọn akọroyin ti oun ba fẹ ṣe bẹẹ.
Eyi lo jẹ kawọn ileeṣẹ iroyin ni Iran fi iroyin kan lede lọjọ Abamẹta ọsẹ to kọja wi pe wahala yoo ṣẹlẹ ẹkun Gulf Oman ti Amẹrika ba le ṣe ikọlu si Kharg Strait.
Ẹkun Gulf Oman tun jẹ ọna mii tawọn ọkọ oju omi maa n gbe epo rọba gba.
Iroyin sọ pe Iran le sọ ina sawọn ibudo amuṣagbara lẹkun Middle East ti Amẹrika ba le ṣe ikọlu si Kharg.
Ni bi ọjọ meloo kan sẹyin ni iroyin kan jade lorilẹede Amẹrika eyi to sọ pe Trump n gbero lati gba iyọnda ile aṣofin agba orilẹede naa lati gba $200bn owo pajawiri fun ogun to n lọ ni Iran.
Eyi fi han pe ijọba Amẹrika ko tii ṣetan lati pari ogun to n ja pẹlu Iran pẹlu bi ijọba Trump ṣe n nawo gọbọi lori ogun naa.
Amọ, ọpọ ọmo ile aṣofin Amerika to fi mawọn to wa ninu ẹgbẹ Republican to jẹ ẹgbẹ Trump ni wọn sọ pe ki o semẹdọ.


























