'Biola Bayo, mo fà ẹ́ sí kóòtù Ọlọ́run'-Princess bú sígbe torí Baba Ijesa tí Biola Bayo gbé wá sóri ètò

Princess, Baba Ijesa ati Biola Adebayo

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 10

"Ika ni ẹ, Biola Adebayo, mo fa ẹ le kootu Olorun lọwọ. Agbepo laja ko jale bii ẹni to gba a kalẹ lọwọ ẹ, Ọlọrun to ni idajọ lọwọ yoo da ọ lẹjọ."

Wọnyi ni diẹ ninu ọrọ ti Damilola Adekoya tawọn eeyan mọ si Princess, ṣọ tẹkun-tẹkun lasiko to n sọrọ ninu fidio kan to fi sori ayelujara.

Fidio ti Princess gbe jade naa lo fi fesi si ifọrọwerọ ti Biola Adebayo ṣe pẹlu Baba Ijesa lori eto Talk To B ti Biola n ṣe.

Ki lo fa ẹkun ti Princess n sun?

Princess Damilola Adekoya

Oríṣun àwòrán, Princess Damilola Adekoya/Instagram

Bi Princess ṣe n sunkun naa lo n ṣalaye pe:

"Inira ti mo n koju yii, ti ọmọ mi n koju pẹlu awọn ọmọ miran ti ko le sọrọ n ko ju, ki i ṣe Ijesa lo fa a fun mi o, iwọ Biola Bayo lo fa a fun mi.

"Biola Adebayo, o fi igi gun oju ọgbẹ mi, o fi gun oju ọgbẹ ọmọ mi atawọn ọmọ yoku naa ti wọn o le sọrọ.

" Mo fi ọla aawẹ ti awọn Musulumi ṣẹṣẹ gba tan ati ọla aawẹ tawọn Kristẹni n gba lọwọ yii, mo pe Ẹlẹdaa ọmọ mi atawọn ọmọ nmiran ti Ijesa ti huwa aida sii, mo fa a ẹ le kootu Ọlọrun lọwọ."

Lori ifọrọwerọ naa ni Princess fi tun sọ pe Ọlọrun yoo ṣedajọ fun Biola ati Ijesa, to ba jẹ pe bi eeyan ṣe n ṣe ni wọn ṣe yẹn.

Ẹ o ranti pe Biola Adebayo ti tọrọ aforiji lori Ijesa to gbe wa sori eto, ṣugbọn Princess sọ pe oun ri ohun ti oṣere tiata naa ṣe bii iwa afigi gun oju ọgbẹ ẹni.

Ati ẹni to mu egbo to ti n jinna tẹlẹ to si tun ki igi bọ ọ loju.

Ẹ má bínú torí Baba Ijesa tí mo pè wá sórí ètò mi, kì í ṣe pé mo faramọ́ ìwà tó gbé e dé ẹ̀wọ̀n-Biola Bayo

Biola Adebayo lapa osi, Lanre Omiyinka (Baba Ijesa) lapa ọtun. Biola n wo ọọkan pẹlu oju ẹgbẹ kan, Baba Ijesa naa n wo ookan pẹlu fila alawọ aro to de sori. O wọ aṣó funfun pẹlu ṣokoto alawọ aro.

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Biola Adebayo lapa osi, Lanre Omiyinka (Baba Ijesa) lapa ọtun

Ifọrọwerọ ti gbajumọ oṣere, Abiola Adebayo, ṣe fun oṣere ẹgbẹ rẹ, Lanre Omiyinka (Baba Ijesa) ti ba ibo miran yọ pẹlu bawọn eeyan kan ṣe n binu si i pe ki lo de to gbe Baba Ijesa waa ṣalaye ọrọ lori eto rẹ.

Ẹ o ranti pe ori eto Biola Bayo to pe ni 'Talk To B', lo gbe Baba Ijesa wa, ti ọkunrin naa si ṣalaye ohun to ṣẹlẹ nipa bo se di ero ẹwọn.

Ijesa sọ awọn ọrọ to fi gbe ara rẹ lẹsẹ, pẹlu awijare kọọkan to tako awọn eeyan bii Princess ati Iyabo Ojo to lewaju ọrọ to gbe e de ẹwọn.

Ṣugbọn bi ifọrọwerọ naa ṣe gun ori afẹfẹ ni ọpọ eeyan ti n koro oju si i, ti wọn si n sọko ọrọ si Biola to gbe Baba Ijesa wa.

Bawọn kan ṣe n sọ pe awijare ti Ijesa ko ri ṣe ni kootu lo wa n sọ lori eto naa, bẹẹ ni awọn miran n sọ pe ṣe Biola fara mọ iwa ti Ijesa hu lo fi gbe e wa sori eto rẹ ni.

Awọn kan tilẹ sọ pe Iyabo Ojo ni Biola fẹ ba ja to fi gbe Ijesa wa, bẹẹ ni oniruuru ọrọ n jade si oṣere tiata to n ṣeto lori afẹfẹ naa.

"Mo ro pe Baba Ijesa fẹẹ wa toro aforiji lori eto mi ni, mi o ni ikapa lori ohun to sọ"

Ninu fidio kan ti Biola Adebayo fi soju opo Instagram rẹ lọjọ Iṣẹgun lo ti ṣalaye idi to fi gbe Baba Ijesa wa, to fi kun un pe iṣẹ oun loun n ṣe.

" Ohun to ṣẹlẹ ni pe nigba ti Baba Ijesa de lati ẹwọn, mo beere lọwọ ẹ pe ṣe o fẹ ṣe ifọrọwerọ pẹlu mi ni tabi o fẹ wa tọrọ aforiji, o si ni oun ko ti I ṣẹtan.

"Emi ro pe yoo tọrọ aforiju ni, ṣugbọn mi o le ma tabuku rẹ lori eto gẹgẹ bii atọkun.

"Eto naa wa fun daadaa ati idakeji rẹ ni, bo ṣe wa fun awọn ẹni mimọ naa lo wa fun awọn ẹlẹṣẹ.

"Awọn ibeere to yẹ ki n beere naa ni mo beere, ẹ lọọ wo fidio naa daadaa.

"Ifọrọwerọ naa ki I ṣe lati wi awijare fun Baba Ijesa, bẹẹ ni emi naa ko le ba ẹni to ba n ba ọmọde laṣepọ tabi to n fipa ba eeyan lo pọ ṣe."

Bẹẹ ni Biola Bayo ṣalaye.

O tẹsiwaju pe oun funra oun ti lugbadi ifibanilopọ ri, o pẹ koun too gbe e kuro lara.

Biola sọ pe oun maa n da aabo bo awọn ọmọbinrin ni, ati gbogbo ọmọ pẹlu agbara oun.

"Ifọrọwerọ naa ki i ṣe lati ba orukọ Iyabo Ojo jẹ"

Nipa awon to n sọ pe Iyabo Ojo lo fẹ ba lorukọ jẹ to fi ṣe ifọrọwerọ naa, Biola sọ pe:

"Ọpọ eeyan n sọ pe mo fẹ fi ifọrọwerọ yẹn ba Iyabo Ojo lorukọ jẹ ni, mi o ni I ṣeyẹn laye. Mo jẹ ki Baba Ijesa sọrọ nipa rẹ nitori mo ri i pe ki I ṣe ohun ti ko daa lo n sọ nipa Iyabo Ojo.

"Ẹ jọọ, ẹ foriji mi. Mi o wa sibi lati wi awijare kankan. Olufẹ alaafia ni mi, mi o fẹran awuyewuye."

Bẹẹ ni Biola to ni Kristẹni tootọ, abiamọ ati ọmọluabi loun, bẹbẹ to si ṣalaye ara rẹ ninu fidio naa.

O fi kun un pe oun wulẹ ti mu ifọrọwerọ to mu ariwo wa yii kuro loju opo oun, nitori naa, ki awọn eeyan jawe oriji lori ọrọ oun, oun bẹbẹ ni.

Yéé fi àwọn ọmọ mi wá ojú ire-Iyabo Ojo kìlọ̀ fún Baba Ijesa

Aworan Iyabo Ojo ati Baba Ijesha

Oríṣun àwòrán, Instagram

Gbajugbaja oṣere tiata, Iyabo Ojo ti fi ikilọ ransẹ si Olanrewaju Omiyinka, ti ọpọ mọ si Baba Ijesha pe ko ma fi orukọ awọn ọmọ re wa oju rere araalu.

Iyabo Ojo tun ni oun yoo morile ile ẹjọ ti Baba Ijesha ko ba dẹkun dida orukọ awọn ọmọ rẹ.

O sọ eyi ninu ọrọ kan to gbe soju opo ayelujara rẹ Instagram, to si tun jẹ ko di mimọ pe awọn alagbatọ iya oun lo ba oun tọ ọmọ, ti oun ko si fi igba kan kan fi awọn ọmọ silẹ.

Ojo ni botilẹjẹpe oun ni ileeṣẹ kan ni agbegbe Ilu Peju niluu Eko lasiko kan, oun ni ọpọ ọmọ iṣẹ to ba oun siṣẹ, ti ko si ṣeeṣe pe oun ko raye lati tọ awọn ọmọ rẹ, ti oun yoo si gbe wọn fun eeyan lati mojuto.

"N ko ni iṣoro pẹlu pe o sọ itan rẹ, ṣugbọn dẹkun lilo orukọ awọn ọmọ mi lati wa oju rere. ko le lọ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Lootọ, o jẹ agba akẹgbẹ, ko si nnkan mii mọ. Ẹwẹ, ọmọ ọdun mẹrinla jẹ ọmọde ati pe biba lopọ ko bojumu. Ẹsẹ ni. O yẹ ko ka ẹ lara diẹ.

"Ile ẹjọ ti ni o jẹbi lẹyin ọpọ ẹri, fun idi eyi, ma fa orukọ awọn ọmọ mi sinu eyi," Iyabo sọ

Eyi waye lẹyin ifọrọwerọ ti Baba Ijesha ṣe lẹyin to kuro lọgba ẹwọn, to si ṣalaye gbogbo ohun ti oju ri ati bi iṣẹlẹ naa ṣe lọ ni apa ọdọ rẹ.

Iyabo Ojo wa lara awọn to bu ẹnu atẹlu Baba ijesha lasiko ti ẹjọ n lọ lori ẹsun ti wọn fi kan.

Lọdun 2021, Iyabo Ojo kesi awọn to n ro ibi ro oun wi pe gbogbo wọn ni wọn yoo ba Ọlọrun oun nibẹ.

O sọ eyi ninu atẹjade to kọ si oju opo ikansiraẹni Instagram, lẹyin ti o fi fidio lede nibi ti baba kan to gbe aṣọ iṣẹmbaye sọrun.

Ninu fidio ọhun ni baba agbalagba naa to dabi babalawo ti n sọrọ kubakugbe si Iyabo Ojo, to si ro iku si.

Amọ Iyabo Ojo ninu atẹjade ni oju opo rẹ sọ wi pe ibẹru kankan ko si fun ọmọ Ọlọrun, a ti pe ẹni to ba ro iku ro oun, ni yoo fi ori ara rẹ gbe.

''Baba Ijesha, Yomi Fabiyi ati gbogbo ẹni buruku ati awọn obinrin to n ṣe atilẹyin fun awọn ẹni ibi, ko fẹ ki ẹ mọ wi pe igbiyanju yin lori aye mi yoo jasi asan, ẹ kan n daamu ara yin lasan ni o.''

''Ẹ kiyesi o, Ọlọrun nkan lo ni agbara lati gba ẹmi ẹnikẹni ni igba ati asiko to ba yẹ''

''Ọlọrun nikan ni yoo gba gbogbo ogo lori aye mi, titi di igba naa, asan lori asan ni igbiyanju yin.''

'Princess dalẹ̀ gbogbo èèyàn' -Baba Ijesa onítíátà sọ̀rọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn tó jáde lẹ́wọ̀n

Aworan Baba Ijesha ati Princess

Oríṣun àwòrán, Instagram

Gbajugbaja oṣere tiata, Olanrewaju Omiyinka, ẹni ti ọpọ mọ si Baba Ijesha, ti sọrọ fun igba akọkọ lori ẹsun ifipabanilopọ ti akẹgbẹ rẹ, Princess fi kan, eyi to ran lọ si ẹwọn ọdun marun un.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu Biola Bayo, oṣere tiata naa sọ pe Princess mọ pe o ti dalẹ ọpọ awọn eeyan to sumọ.

Bakan naa lo tun sọ pe oun ko ni ajọsepọ kankan pẹlu Princess, ti ko si fi igba kankan kọ ẹnu ifẹ si, dimọ tabi fi ẹnu ko lẹnu.

"Princess fun ara rẹ mọ pe oun ti da lẹ ọpọ eeyan to jẹ ọrẹ pẹlu. N ko kọ ẹnu ifẹ si, tabi ni ajọsepọ kankan pẹlu rẹ, dimọ tabi fi ẹnu ko lẹnu

"O sunkun wa bami bi o ṣe n sunkun bayii, to n sọ pe oun ko le ṣe lia ri mi tabi eto mi. N ko le sọ awọn nnkan ti ko le sọ".

Baba ijẹsha tẹsiwaju pe ohun to dun oun ju ni ọrọ Iyabo Ojo nitori ọpọ igba ni oun ba Iyabo Ojo duro ti awọn ọmọ rẹ, ti oun ko si ṣe wọn ni aburu kankan.

"Ohun to dun mi ju nipa Iyabo Ojo ni pe o fi awọn ọmọ rẹ Priscillia ati aburo rẹ si ikẹ mi nigba ti awọn ni ọmọde. Nigba ti eeyan kan sọ nipa Iyabo Ojo ati nnkan to ṣe , mo sọ pe

"Iṣe mi ni Iyabo, n ko ṣe ni buburu. Idi ree ti Yomi Fabiyi fi n ja kikankikan."

Bawo ni ìṣẹ̀lẹ̀ tó gbé Bàbá Ijesha dé ẹ̀wọ̀n ṣe wáyé?

Gbajumọ aderinposonu ati oṣere tiata, Princess, lo kede pe akẹẹgbẹa oun lagbo tiata, Olanrewaju Omiyimika, ta a tun mọ si Baba Ijesha n ṣe aṣemaṣe pẹlu ọmọbìnrin ti oun gba tọ, ọmọ ọdun mẹ́rìnlá, to si fi ọlọpaa mu.

O gbe baba Ijesha lọ síle ẹjọ, ti ìgbẹjọ si waye fun ọpọlọpọ oṣu, ti ile ẹjọ sì kede pe Baba Ijesha jẹbi esun ifipabanilopọ pẹlu ọmọ ọdun mẹrinla naa.

Agbẹjọro Baba Ijesha, Dada Awosika níbi ìgbẹjọ naa sọ fun ile ẹjọ wí pe ile ẹjọ nílo lati se atungbeyẹwo ọrọ ọjọ ori ọmọ ti wọn fi ẹsun rẹ kan oun, wí pe oun ba lopọ kìí ṣe ootọ.

Adajo Oluwatoyin Taiwo, ninu idajọ wakati meji rẹ, da Baba Ijesha lẹbi fun iwa aisedede si ọmọ na, aṣemaṣe to fara pẹ ibalopo, ati igbidanwo ìfipábánilòpọ̀.