Wo ìbéèrè méje tí ọkùnrin kò gbọdọ̀ bi obìnrin

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iṣẹ ọwọ Eledumare ni awa eniyan to da ni takọ-tabo, ṣugbọn àdámọ́ ọtọọtọ lo wa lara awa ẹda meji ti Ọlọrun da naa.
Ohun ti ọkunrin le mu mọra ko si ma binu si rara ni obinrin yoo sọ di babara, to si le binu rangbọndan.
Eyi naa lo fa a to fi jẹ pe awọn ibeere kan wa ti ko yẹ ki ọkunrin beere lọwọ obinrin to ba fẹẹ fẹ, tabi ti wọn jọ wa lori ipinnu a n fẹra ẹni.
Wọnyi ni ibeere meje ti ko yẹ ko ti ẹnu ọkunrin jade si obinrin.
- Ṣe o ti bimọ ri?
Bi ibeere yii ṣe ṣe pataki to, paapaa laye ode oni ti otitọ ko wọpọ, ko tọ fun ọkunrin lati beere rẹ lọwọ obinrin to ba n fẹ sọna.
Idi ni pe itumọ ti yoo ni lọkan obinrin ni pe ọkunrin naa n fi oju ẹni ti inu rẹ tobi ju wo oun, tabi to ti bimọ ri.
Idi miran ni pe obinrin naa le jẹ ẹni to n wa ọmọ lati bi, ti ko si ti I bi, ti ọkunrin si wa n foju ẹni to ti bi wo o.
Eyi le mu un banujẹ ko si binu pẹlu.
Ti o ba fẹ mọ boya obinrin ti bimọ ri, igba ti ẹ ba sọrọ debẹ, tabi ti oun funra rẹ mu ẹnu ba a lo daa.
- Ẹni ọdun meloo ni ẹ?
Ibeere yii ko yẹ ko fa ija, fun obinrin ti ọjọ ori rẹ wa laaarin ọdun mẹẹẹdọgbọn si mẹtadinlọgbọn (25-27).
Awọn wọnyi ṣi wa lọjọ ori Sango ode, ọjọ ori ọlọmọge ṣi ni wọn wa.
Ṣugbọn fun obinrin to ti pe ọgbọn ọdun si ogoji (30-40), o ṣee ṣe ki ibeere yii gbodi lara rẹ, o si le maa ro o pe o n yẹyẹ oun ni.
- Ṣe o le ya mi lowo?
Lati ayebaye, ọkunrin lo maa n fun obinrin lowo, o si ti mọ obinrin lara lati maa gba lọwọ ọkunrin.
Ṣaṣa obinrin lo n nawo rẹ fọkunrin, awọn ti wọn ti sọ ara wọn di bukata ọkunrin lati gbọ lo pọ ju.
Fun idi eyi, nigba ti ọkunrin ba wo ṣunṣun to si ni ṣe obinrin yoo ya oun lowo, paapaa lasiko ti ifẹ wọn ko ti I rin jinna, obinrin naa le maa ri I bii alaini nnkan I ṣe.
Nigba miran si ree, obinrin funra rẹ le ronu pe oun yoo ya ọkọ tabi ọrẹkunrin oun lowo, eyi to daa ju ki ọkunrin beere lọ.
- Ki ni ìwọ̀n rẹ?
Koda bi obinrin sanra fakia, tabi to pẹlẹngẹ delẹ patapata, ki I wu wọn ki ọkunrin beere pe ki ni iwọn wọn.
Bi ọkunrin ba n bi wọn ni ibeere yii, o le mu ọkan wọn kuro lọdọ rẹ, wọn si le ma jẹwọ iwọn naa paapaa.
- Ṣe o nifẹẹ mi?
Bi o ba beere ibeere yii lọwọ obinrin, ibeere ẹlẹgẹ ni yoo jọ loju obinrin naa.
Obinrin le dahun pe oun ko nifẹẹ rẹ, koda to ba ṣe pe ina ifẹ ọkunrin ọhun n jo lọkan rẹ gidi.
Eyi le pada ja okun ifẹ, ki ohun ti ko to nnkan si da ajọṣepọ rere ru.
Bi o ba ni oju inu ti o si n woye ọrọ, iwọ yoo mọ boya iyawo tabi ọrẹbinrin rẹ nifẹẹ rẹ tootọ, tabi bẹẹ kọ.
- Ki lo de ti o ko ti i lọkọ?
Aṣiṣe ni lati beere lọwọ obinrin pe ki lo de ti ko ti I lọkọ, nitori oun funra rẹ lo mọ idi ti ko ṣe ti I di abilekọ nigba to yẹ ko ti wa lọọdẹ ọkunrin.
Ai ti i lọkọ rẹ ko le jẹ ohun to wu u, o le ma ti I ri ọkunrin gidi, o si le jẹ ilera tabi iṣoro kan ti araata ko mọ lo n ba a finra.
Fun idi eyi, ibeere yii yoo ni ipa aburu lọkan obinrin naa.
- Ṣe wa a sanwo ohun ti a ra?
Ti o ba gbe obinrin jade lati jẹun, ma ṣe duro de e pe ko sanwo ounjẹ ti o ra fun un.
Ṣugbọn to ba loun yoo sanwo funra oun, o wu u niyẹn. Ọkunrin le gba ko sanwo naa, o si le sọ pe oun yoo ba a san an.
Ṣugbọn ma ṣe sọ fun un pe ko sanwo ounjẹ to jẹ funra rẹ.
Lati gbadun obinrin ti ifẹ da iwọ ati ẹ pọ, iwọ ọkunrin gbọdọ jẹ eeyan daadaa, ọlọgbọn ati amoye eeyan.
Ẹni to ṣetan lati maa gbọ bukata obinrin, ti yoo nifẹẹ rẹ tọkantọkan, ti yoo si ṣetan lati gba àrà ti obinrin ba n da gẹgẹ bi abuda obinrin .

























