Gbajúgbajà olórin ẹ̀mí, Toun Soetan jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Instagram/tounsoetan
Gbajugbaja olorin ẹmi nni, arabinrin Toun Soetan, ti jade.
Ẹni ọdun mẹtalelaadọrin ni Soetan ṣaaju iku rẹ lọjọ Ẹti, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹta, ọdun 2026 yii.
Alawada ori ayelujara to n fi ilu Ibadan ṣe ibugbe, Wolii Agba, lo fidi iroyin naa mulẹ loju opo Instagram rẹ lọjọ Ẹti.
Nigba to n kede iku oloogbe naa, Wolii Agba sọ pe "Iya wa daadaa Toun Soetan… Iya wa, ẹ kọ orin pẹlu awọn angẹli, oga o, o daarọ. Mo gbadura ki Ọlọrun wa pẹlu ọkọ yin atawọn mọlẹbi yin."
Olorin ẹmi miran, Peter Olaniyi, tun fidi iroyin iku oloogbe naa mulẹ, o si juwe rẹ bii ẹni ti ko ṣee fọwọ rọ sẹyin lagbo olorin ẹmi ni Naijiria.
O ni "A tun ti padanu agba ọjẹ olorin ẹmi miran, iya agba Toun Soetan.
"Adura mi ni pe ki Ọlọrun wa pẹlu ẹbi wọn ati baba Titus Soetan, ẹ jọwọ ẹ ba mọlẹbi wọn kẹdun."
Lati igba ti iroyin iku oloogbe naa ti gbode lọpọ eeyan kaakiri agbaye ti n ba mọlẹbi rẹ kẹdun lori ayelujara.
Pupọ ninu awọn to n fi ọrọ ibanikẹdun naa ranṣẹ ni wọn n juwe oloogbe ọhun gẹgẹ bii awokọṣe rere laarin awọn ọmọlẹyin Kristi atawọn olorin ẹmi akẹgbẹ rẹ, paapaa awọn to ṣẹṣẹ n goke agba.
Olorin ẹmi mii, Bukola Omowaye sọ pe oloogbe Soetan ko ipa rere ninu idagbasoke oun gẹgẹ bii olorin ẹmi.
O ni awọn ẹkọ oloogbe naa atawọn orin to ti kọ ṣeyin ran oun lọwọ lati dagba ninu ẹmi.
Lara awọn orin ti Soetan kọ to lamilaaka ni "Darling Jesus, Train Up Your Child, Iye Ree, Gbe Jesu Ga" ati bẹẹbẹẹ lọ.
Ta ni Toun Soetan?
Ilu Eko ni wọn ti bi Racheal Olatoun Soetan amọ agbegbe Beere–Oke Are lo dagba si niluu Ibadan.
O jẹ ọkan lara ọmọ mejidinlọgbọn mọlẹbi rẹ, idile Musulumi lo si ti wa.
Irinajo ajo ẹmi rẹ gba ọna mii yọ lẹyin to lọ sibi isọju kan nile ijọsin Oritamefa Baptist Church lọdun 1974, irinajo naa lo si bẹrẹ iṣẹ orin ẹmi rẹ.
Oun lo da Trinity World Evangelical Ministries ati Trinity School of Worship silẹ.























