Ohun tí a mọ̀ rèé lórí ìròyìn pé wọ́n yìnbọn fún Broda Shaggi ní Ogun

Brother Shaggi lasiko to n ṣere lọwọ

Oríṣun àwòrán, Brother Shaggi

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kejìlá, oṣù Kẹta, ọdún 2026 ni ìròyìn gbòde pé àwọn kan yìnbọn mọ́ gbajúmọ̀ adẹrìnínpòṣónú, Samuel Perry tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Broda Shaggy níbi tó ti ń ya fídíò kan ní agbègbè Sango-Ota, ìpínlẹ̀ Ogun.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tí a rí, wọ́n ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kẹjọ, oṣù Kẹta ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé lábẹ́ afárá Sango-Ota.

Ìròyìn tó gbòde sọ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tó ṣokùnfà ìṣẹ̀lẹ̀ náà kò ye ẹnikẹ́ni, wọ́n ní ọlọ́pàá kan tí kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni dárúkọ òun nítorí òun kò ní àṣẹ láti sọ̀rọ̀ lórí ìròyìn náà sọ pé nígbà tí adẹ́rìnípòṣónú náà ń ya fídíò ni Sango-Ota ni wọ́n yìnbọn mọ́-ọn.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn náà ṣe sọ, wọ́n sáré gbé Broda Shaggy lọ sílé ìwòsàn Blooming Care tó wà ní agbègbè Alakuko ní ìpínlẹ̀ Eko níbi tí wọ́n ti kọ́kọ́ tọ́jú rẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí iléeṣẹ́ ìwé ìròyìn PUNCH gbé síta, lẹ́yìn tí wọ́n tọ́jú Broda Shaggy fún ìgbà díẹ̀ ní Blooming Care ni wọ́n tún gbe lọ sí ilé ìwòsàn Duchess Hospital tó wà ní agbègbè Ikeja, ìpínlẹ̀ Eko níbi tó ti ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ báyìí.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko, Abimbola Adebisi náà fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ bí ó ṣe sọ pé àwọn aláṣẹ ilé ìwòsàn tí Broda Shaggy ti ń gba ìtọ́jú ló kàn sí àgọ́ ọlọ́pàá láti fi ọ̀rọ̀ náà tó wọn létí.

Adebisi ní kété tí ilé ìwòsàn pe àgọ́ ọlọ́pàá pé wọ́n gbé èèyàn tó ní ọgbẹ́ ọta ìbọn wá sí ilé ìwòsàn àwọn ni àwọn ọlọ́pàá lọ síbẹ̀ tí wọ́n sì ri pé Broda Shaggy ni ẹni náà.

Ó fi kun pé ibi itan ni Broda Shaggy ti gbọgbẹ́, tó sì ti ń gba ìtọ́jú.

Ki ni ọlọpaa ipinlẹ Ogun sọ?

Nígbà tí BBC News Yorùbá kàn sí agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun láti fìdí ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an múlẹ̀, Agbẹnusọ ọlọ́pàá Ogun, Oluseyi Babaseyi nínú àtẹ̀jíṣẹ́ tó fi ránṣẹ́ sí wa sọ pé òun kò le fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n yìnbọn fún Bdoda Shaggy gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó gbòde.

Ó ní síbẹ̀síbẹ̀ ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ láti mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ ní pàtó àti pé àwọn yóò máa fi àbọ̀ ìwádìí àwọn tó aráàlú létí ní kété tí àwọn bá ti mọ ohun tó ń lọ.

Babaseyi rọ àwọn èèyàn láti dènà gbígbé àwọn ìròyìn tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, kí wọ́n sì máa ṣe ìwádìí dáadáa kí wọ́n tó máa gbé ìròyìn síta.

Lẹyin naa lo tun fi iroyin to fi ṣọwọ si wa sita loju opo X ileeṣẹ ọhun.