Agboolé Akọni: Ohun tó fa ìjà láàárín Afonja àti Aláàfin Aole àti bí Alimi ṣe dìtẹ̀gbàjọba lọ́wọ́ Afonja nítorí ẹ̀sìn

Àkọlé fídíò, Agboole Akoni Afonja
Agboolé Akọni: Ohun tó fa ìjà láàárín Afonja àti Aláàfin Aole àti bí Alimi ṣe dìtẹ̀gbàjọba lọ́wọ́ Afonja nítorí ẹ̀sìn

Lori eto Agbole Akọni lọtẹ yii, idile Afonja ni a lọ niluu Ilorin lati mọ nipa itan igbesi aye rẹ, bo ṣe jagun ati bo ṣe ṣe akinkanju to nigba aye rẹ.

Lara awọn ti a ba sọrọ ni Idi Ape ni alagba Hassan Amoo, to jẹ akọwe agba ẹgbẹ arọmọdọmọ Afonja.

Amoo ṣalaye fun BBC Yoruba pe Alaafin Aole lo fi Afonja jẹ Aarẹ Ọna Kakanfo bo tilẹ jẹ pe ija pada bẹ silẹ laarin awọn mejeji ti wọn si pin gaari wọn.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, Baba-baba Afonja to n jẹ Oladerin, lo tẹ ilu Ilorin do, ile kan ti wọn n pe ni Ile Aarẹ ni Afonja si gbe nigba aye rẹ.

Ile Aarẹ ọhun ṣi wa nibẹ titi di oni yii bo tilẹ jẹ pe wọn ti ṣe atunṣe si ko le ba igba mu.

Ninu irinajo wa sile Akọni Afonja, a tun fi ẹsẹ kan de Mọṣalaṣi idi Ape nibi ti irinṣẹ ati awọn nnkan ogun Afonja wa tẹlẹ ki wọn to sọ ibẹ di mọṣalaṣi lẹyin ti ẹsin Islam de.

Ede aiyede laarin Afonja ati Alaafin Aole

Lori ohun to fa ede aiyede laarin Alaafin Aole ati Afonja, Amoo sọ fun wa pe ko ṣẹyin lori ogun Iwere Ile.

O ni "Iwere Ile, ilu iya Alaafin ni, ẹnikan ko le kogun ja ibẹ."

Amoo sọ pe ẹni to ba lagbara amọ ti wọn ba fẹ ge iyẹ rẹ ni wọn maa n ran lọ lati lọ ja ogun Iwere Ile.

Nigba ti wọn ni ki Afonja lọ ja ogun Iwere Ile, lo ba yari pe oun ko ni lọ nitori ọna ati gbẹni oun ni igbesẹ naa jẹ.

Lẹyin naa lo fopin si ibaṣepọ oun ati Alaafin Aole, to si ni ki Aole maa ṣe tirẹ ni Oyo, ki oun naa maa ṣe ijọba oun niluu Ilorin.

Ẹsin lo fa ipinya laarin Afonja ati Alimi

Jagunjagun ni Alimi, iha Afonja lo si wa.

Amọ nigba to di asiko kan ni Alimi atawọn ẹmẹwa rẹ sọ fun ara wọn pe Afonja ko le maa dari awọn nitori kii ṣe Musulumi, bẹẹ ni kii kirun.

Wọn ni keferi ko le maa dari awọn, wọn si ditẹ mọ lati gba ijọba lọwọ rẹ to fi jẹ pe titi di oni yii, ẹsin Islam lo jẹ kokaari gbogbo ẹsin to wa niluu Ilorin.

Wo fidio oke yii fun ẹkunrẹrẹ nipa oun ti a ba bọ lati agbole akọni Afonja niluu Ilorin.