ICPC tú El-Rufai sílẹ̀ lẹ́yìn tó pàdánù ìyá rẹ̀

Oríṣun àwòrán, NASIR EL-RUFAI/FACEBOOK
Àjọ tó ń gbógunti ìwà ìbàjẹ́ àtàwọn ìwà ọ̀daràn míì tó fara pẹ ìyẹn The Independent Corrupt Practices and Other Related Offences Commission, ICPC ti fi gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Kaduna, Mallam Nasir El-Rufai sílẹ̀ láti máa lọ sílé rẹ̀ fún ìgbà kan ná.
ICPC ní àwọn ń fi El-Rufai sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ ná ni.
Èyí ló ń wáyé lẹ́yìn tí ìròyìn gbòde pé El-Rufai pàdánù ìyá rẹ̀, Hajiya Umma El-Rufai ní ọjọ́ Ẹtí ní ìlú Cairo, orílẹ̀ èdè Egypt.
Olùrànlọ́wọ́ El-Rufai kan sọ fún àwọn akọ̀ròyìn pé ICPC buwọ́lu títú El-Rufai sílẹ̀ nítorí pé ó pàdánù ìyá rẹ̀.
Bákan náà ni ọmọ El-Rufai, Bashir El-Rufai kọ sójú òpó X pé àjọ ICPC ti tú bàbá òun sílẹ̀ tó sì ń kí àwọn ọmọ Nàìjíríà fún àtìlẹyìn wọn lásìkò tí wọ́n ń kojú àwọn ìṣòro tí wọ́n ń là kọjá.
Àmọ́ pẹ̀lú gbogbo ìròyìn tó ń lọ lórí ayélujára, ICPC kò ì tíì sí sọ ohunkóhun lórí ìròyìn tó gba orí ayélujára náà.
Láti Kejìdínlógún, oṣù Kejì, ọdún 2026 ni Nasir El-Rufai ti wà ní àhámọ́ ICPC lórí àwọn ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu, tí wọ́n sì ti fojú rẹ̀ bale ẹjọ́.
El-Rufai lóun ò jẹ̀bi ẹ̀sùn ṣíṣe owó ìlú kúmọkùmọ tí wọ́n fi kan òun

Oríṣun àwòrán, Other
Gomina ipinlẹ Kaduna tẹlẹ, Nasir El-Rufai, ti sọ pe oun o jẹbi ẹsun ṣiṣe owo ilu kumọkumọ ti ajọ ICPC fi kan oun.
Lonii ọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹrinlelogun oṣu Kẹta ni igbẹjọ naa waye nile ẹjọ kan to wa niluu Kaduna.
Igba akọkọ ree ti El-Rufai yoo farahan nile ẹjọ lati bi oṣu kan ti ajọ ICPC ti fọwọ mu un.
Niṣe lawọn ẹṣọ eleto aabo duro wamu wamu nile ẹjọ ọhun niluu Kaduna, bakan naa lawọn alatilẹyin El-Rufai pọ biba loju popo.
Aṣoju ileeṣẹ iroyin BBC to wa nibẹ sọ pe awọn ololufẹ El-Rufai mu oriṣiiriṣii beba ti wọn kọ ọrọ atilẹyin si lọwọ ti wọn si n kọrin.
Bakan naa ni a gbọ pe awọn alatilẹyin El-Rufai da sukẹrẹ fakẹrẹ ọkọ silẹ loju popo.
Iroyin fidi rẹ mulẹ pe agbẹjọro gomina ipinlẹ Kaduna tẹlẹ ri ọhun, Ukpon Akpan, rọ ile ẹjọ lati gba beeli rẹ ko le raye gbaradi fun igbẹjọ rẹ.
Amọ, agbẹjọro ICPC tako aba naa lẹyin to sọ pe ki ile ẹjọ ma gba beeli El-Rufai tori o le ṣakoba fun iwadii to n lọ lọwọ lori ẹjọ rẹ.
Adajọ ti sun igbẹjọ beeli El-Rufai si ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu Kẹta yii bayii,
El-Rufai yóò fojú balé ẹjọ́ lónìí lórí ẹ̀sùn ṣíṣe owó ìlú kúmọkùmọ
Àjọ tó ń gbógunti ìwà ìbàjẹ́ àtàwọn ìwà ọ̀daràn míì tó fara pẹ ìyẹn The Independent Corrupt Practices and Other Related Offences Commission, ICPC ti ní lónìí, ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kẹrìnlélógún, oṣù Kẹta ni àwọn máa wọ gómìnà tẹ́lẹ̀ rí fún ìpínlẹ̀ Kaduna, Mallam Nasir El-Rufai lọ sílé ẹjọ́.
Ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ tó wà ní ìpínlẹ̀ Kaduna ni El-Rufai yóò ti máa jẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí ICPC ṣe gbe jáde.
Àjọ náà ní àwọn ẹ̀sùn tí El-Rufai yóò máa jẹ́jọ́ lé lórí gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n gbé lọ sílé ẹjọ́ lọ́jọ́ Kejìdínlógún, oṣù Kẹta ni sísọ dúkìá ìjọba di ti ara rẹ̀ àti ṣíṣe owó ìlú kúmọkùmọ.
Àtẹ̀jáde tí agbẹnusọ ICPC, John Okor Odey fi léde lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹtàlélógún, oṣù Kẹta sọ pé El-rufai àti Joel Adoga ni wọn yóò jọ máa jẹ́jọ́.
Bákan náà ló fi kun pé wọ́n tún ti fàwọn ẹ̀sùn míì kan El-Rufai èyí tó nííṣe pẹ̀lú èrú àti láti hùwà ọ̀daràn.
Ẹ ó rántí pé lẹ́yìn tí El-Rufai kúrò ní àhámọ́ àjọ EFCC ní oṣù Kejì ni ó ti wà ní àhámọ́ àjọ ICPC.
Ní ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Kẹta ni ilé májísíréètì ni kí El-Rufai ṣì wà ní àhámọ́ ICPC fún ọjọ́ mẹ́rìnlá sí ọjọ́ tí wọ́n ti kọ́kọ́ ní kó fi wà ní àhámọ́.


























