Àwọn ọ̀dọ̀ ilẹ̀ Africa ni ìlera ọpọlọ wọn pé jù lọ láàgbáyé-Ìwádìí
Awọn Yoruba to sọ pe inu ikoko dudu ni ẹkọ funfun ti jade ko jayopa rara.
Idi ni pe awọ dudu to wọpọ fun awọn eeyan ilẹ Africa, ko tumọ si pe nnkan ribiribi ko le ti ibẹ jade.
Iwadii ti fi han bayii pe awọn ọdọ ilẹ Africa ni ilera ọpọlọ wọn pe ju lọ lagbaaye, ti a ba fi we ti awọn orilẹede agbaye yooku.
Koda, pẹlu gbogbo wahala to n koju awon ọdọ ilẹ Africa, iwadii ti ajọ Mental Health Quotient (MHQ) ṣe, fi han pe awọn ọdọ ilẹ Africa ni ilera ọpọlọ wọn pe ju lọ lagbaaye.
Iwadii naa fi han pe ilera ọpọlọ awọn ọmọ ilẹ okeere bii UK, Newzealand ati Japan ko kun to ti awọn ọmọ ilẹ Africa.
Nini ọla ati ọrọ, jijẹ ọmọ ilẹ okeere kọ ni odiwọn ọpọlọ pipe, obi to bimọ nilẹ Africa ni ko gbiyanju kọ ọmọ rẹ nilana ti yoo fi ya daadaa, ti yoo si lo ọpọlọ rẹ soju ọna ire ati ti ọmọluabi.





