Àwa là ń fiyà jẹ ara wa - Okunnu bu ẹnu àtẹ́ lu àwón alágbàtà epo bí owó bẹntiróòlù ṣe gbẹ́nu sókè

Wale Akorede, Okunnu wọ aṣọ olómi aro, dé fìlà dúdú, ó ń wo ọ̀ọ́kán

Oríṣun àwòrán, Okunnu_1

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà, Wale Akorede tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Okunnu ti bu ẹnu àtẹ́ lu bí owó epo bẹntiróòlù ṣe ń gbẹ́nu sókè lásìkò yìí tó sì ní àwọn alágbàtà epo wà lára àwọn tó ń ṣokùnfà ìgbésẹ̀ náà.

Nínú fídíò kan tí àgbà òṣèré náà fi léde lórí ìkànnì Instagram rẹ̀ sọ pé bí àlékún ṣe ń bá owó epo bẹntiróòlù ní ojoojúmọ́ ti pọ̀ jù bó ṣe yẹ lọ.

Okunnu ní ṣé ìjọba nìkan ló yẹ kí àwọn èèyàn máa báwí lórí ọ̀rọ̀ epo, pé ohun táwọn alágbàtà epo ń ṣe nínú gbogbo ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ yìí náà pọ̀.

Ó wòye pé epo tí òun rà ní N1,240 jálà kan ní ọjọ́ Àbámẹ́ta ti fò fẹ̀ẹ̀rẹ̀ di N1,340 sí N1,350 ní ọjọ́ Àìkú, tó sì ní bí àlékún náà ṣe wáyé ti yára jù láàárín àsìkò péréte náà.

Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ogun tí Amẹ́ríkà àti Israel ń gbé ti Iran wà lára ohun tó ṣokùnfà bí àlékún ṣe n bá owó epo, ó ní kò yẹ kí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ní ipa tó pọ̀ bẹ́ẹ̀ lórí Nàìjíríà nítorí Nàìjíríà wà lára àwọn orílẹ̀ èdè tó ní epo rọ̀bì púpọ̀.

Ó kọminú pé àwọn ọmọ Nàìjíríà wà lára àwọn tó ń dákún ìjìyà tó ń kojú ọ̀pọ̀ èèyàn ní orílẹ̀ èdè yìí.

Àgbà òṣèré náà sọ pé bí epo bẹntiróòlù ṣe gbẹ́nu sókè máa ní ipa lórí ọrọ̀ ajé Nàìjíríà, èyí tó máa fa àlékún lórí owó ọkọ̀, oúnjẹ àtàwọn ohun èlò ìgbáyégbádùn míì.

Bákan náà ló tún sọ̀rọ̀ lórí bí iye tí àwọn òṣìṣẹ́ ń gbà gẹ́gẹ́ owó oṣù kò ṣe tó ná mọ́, tó sì ń mú kí ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ dàbí ọ̀lẹ tí kò mọ iṣẹ́ ṣe mọ́.

Ọ̀rọ̀ tí Okunnu sọ yìí ti wá fa onírúurú awuyewuye lórí ayélujára, bí àwọn kan ṣe ń wòye pé ẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà kò sí lọ́wọ́ àwọn alágbàtà epo gẹ́gẹ́ bí Okunnu ṣe sọ.

Àwọn èèyàn kan ń sọ pé ìjọba ni kò pọnmi sílẹ̀ de òùngbẹ, tí wọ́n ń sọ pé ká ni ìjọba ṣe àwọn ohun tó yẹ ṣáájú àsìkò yìí, kò ní sí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ náà.

Ohun tí Okunnu sọ yìí ṣàfihàn ìrírí àwọn ọmọ Nàìjíríà láti ìgbà tí owó epo bẹntiróòlù ti ń gbẹ́nu sókè láti ìgbà tí ogun tí ń wáyé láàárín Amẹ́ríkà, Israel àti Iran.

Nígbà tí àwọn kan faramọ́ Okunnu pé àwọn alágbàtà náà ní ti wọn lára, làwọn míì sọ pé àìsí ètò ìjọba tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ wà lára ohun tó fà á.