Senegal yóò ṣàfihàn Ife ẹ̀yẹ AFCON 2025 lópin ọ̀sẹ̀ yìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé CAF ti gbé ife náà fún Morocco

Oríṣun àwòrán, SEBASTIEN BOZON / AFP via Getty Images
- Author, Ian Williams
- Role, BBC Sport Africa
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Ẹgbẹ agbabọọlu Senegal yoo ṣafihan ife ẹyẹ Afcon 2025 ti ajọ CAF kede wi pe awọn ti gbe fun Morocco.
Lọjọ Aabamẹta ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Kẹta yii ni Senegal yoo ṣafihan ife ẹyẹ naa ki ifẹsẹwọnsẹ ọlọọrẹsọọrẹ ti wọn fẹ gba pẹlu Peru niluu Paris to bẹrẹ.
Ẹgbẹ agbabọọlu Senegal gbafe Afcon fun igba keji lọjọ kejidinlogun osu Kinni ọdun yii lẹyin ti won fi ami ayo kan sodo ṣagba Morocco ninu ere bọọlu aṣekagba idije Afcon 2025.
Ti ẹ o ba gbagbe, ede-ai-yede ṣẹlẹ lasiko ti aṣekagba idije Afcon naa n lọ lọwọ lẹyin tawọn agbabọọlu Senegal binu kuro lori papa nigba ti rẹfiri fawọn Morocco ni pẹnariti.
Lẹyin o rẹyin, awọn agbabọọlu naa pada sori papa, wọn si fagba han Morocco pẹlu ami ayo kan sodo lẹyin ti Brahim Diaz sọ pẹnariti ti wọn fun Morocco nu.
Amọ, iyalẹnu lo jẹ fun Senegal ati ọpọ ololufẹ ere bọọlu nigba ti ajọ naa kede wi pe awọn ti gbe ife ẹyẹ Afcon ti Senegal gba fun Morocco nitori Senegal tapa sofin CAF pẹlu bi wọn ṣe binu jade lori papa.
Koda, CAF ni ami ayo mẹta sodo ni Morocco fi jawe olubori ninu ere bọọlu ọhun.
Lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii ni ileẹjọ CAS nibi ti Senegal ti pẹjọ kotẹmilọrun sọ pe igbẹjọ naa ko ni pẹ rara.
Aarẹ ajọ FSF to n ri si ere bọolu ni Senegal, Abdoulaye Fall, sọ pe iwa gbewiri to buru julọ ninu itan ere idaraya ni igbesẹ ti ajọ CAF gbe.
Aarẹ Fall si ṣeleri wi pe gbogbo nnkan tawọn ba ni lawọn yoo fi ja gba ife ẹyẹ Afcon awọn pada.
Ki lawọn eeyan n sọ nipa ife ẹyẹ Afcon ti CAF gbe fun Morocco?
Lẹyin ti Senegal ti gba ife Afcon naa tan ni Morocco gbe ẹjọ lọ si ajọ CAF ati FIFA lori nnkan to sẹlẹ ninu ere bọọlu naa pe bawọn agbabọọlu Senegal ṣe binu kuro lori papa da omi tutu sawọn lọkan eyi to ṣakoba fun bawọn ṣe gba bọọlu naa pari.
Ajọ CAF to n ri si ifiyajẹ awọn ẹgbẹ agbabọọlu to ba tapa sofin kọkọ tako ẹjọ ti Morocco pe, igbimọ naa si paṣẹ wi pe ki Morocco ati Senegal san faini fun ihuwasi wọn lasiko aṣekagba ere bọọlu naa.
Lẹyin o rẹyin ni Morocco ni ki CAF tun ẹjọ awọn wo, eyi ti wọn si ṣe bẹẹ.
Idajọ to tẹle agbeyẹwo naa ni pe CAF kede wi pe Morocco lo gbafe ẹyẹ Afcon 2025 tori Senegal tapa sofin pẹlu bi wọn ṣe binu kuro lori papa.
Lẹyin ikede yii ni ijọba Senegal pe fun iwadii ẹsun iwa ibajẹ ni ajọ CAF, amọ, aarẹ CAF Patrice Motsepe ni ko si nnkan to jọ bẹẹ.
Aarẹ ajọ to n ri si ere bọọlu ni Senegal ṣo pe awọn ti gba awọn akọṣẹmọṣẹ agbẹjọro ti won ni iriri lati ṣoju awọn ni ileẹjọ CAS.
Fall ni idajọ igbimọ CAF to ni Morocco lo gbafe ife Afcon 2025 kii ṣe idajọ to fidi ododo mulẹ rara.
O ni idajọ naa tẹ ẹtọ ọmọniyan Senegal mọlẹ gẹgẹ bi orilẹede agbabọọlu.
Amofin Juan Perez naa sọ pe ko ṣẹlẹ ri wi pe ki rẹfiri ti pari ere bọọlu, kawọn alaṣẹ ere bọọlu tun wa ṣe ayipada esi ifẹsẹwọnsẹ naa.
Ọrọ ko tii tan lori ife Afcon 2025 pẹlu bi Senegal ṣe fẹ ṣafihan ife naa lopin ọsẹ yii ni ilu Paris nigba ti ileẹjọ CAS ko si tii dajọ lori rẹ.


























