Ayẹyẹ ọdún Lisabi gbérasọ ní ìlú Abeokuta pẹ̀lú àwọn àkọ̀tun àrà

Oríṣun àwòrán, Others
Kaakiri gbogbo agbaye ni awọn ọmọ Ẹgba ti peju pesẹ si aafin Alake ilẹ Ẹgba to wa ladugbo Ake niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun lati ṣayẹyẹ ọdun Lisabi Agbongbo Akala ti wọn maa n ṣe lọdọọdun.
Lisabi Agbongbo Akala jẹ akikanju jagunjagun to gba awọn ọmọ Ẹgba silẹ lọwọ awọn to n fi ogun ja wọn.
Bo tilẹ jẹ pe lati ọjọ Aje, ọsẹ yii, ni ayẹyẹ naa ti bẹrẹ pẹlu oniruuru eto ọlọkan-o-jọkan ti wọn ti la kalẹ, ṣugbọn oni ọjọ Abamẹta, ọjọ Kejidinlọgbọn, oṣu Kẹta ni aṣekagba eto naa, nibi ti awọn eeyan pataki ti wọn ti ṣe bẹbẹ ni oniruuru ẹka ti peju lati kopa.
Alake ilẹ Ẹgba, Ọba Adedotun Aremu Gbadebo lo gba gbogbo ọmọ Ẹgba ati awọn alejo lalejo ni aafin Ake.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ọdun to kọja ni ayẹyẹ naa gbọna ara yọ nipa eto tuntun ti wọn fi sinu rẹ, eyi ti wọn pe ni Egbaliganza, lati fi ṣafihan oniruuru imura to n fi aami idanimọ ojulowo ọmọ Ẹgba han fun araye.






















