TB Joshua burial: Wo àwọn gbajúmọ̀ òṣèré tó lọ sí ibi ètò ìsìnkú Temitope Joshua
Eto ayẹyẹ isin idagbere ati isinku gbajugbaja wolii, Temitope Balogun Joshua ti n waye.
Nibi ayẹyẹ naa to ti bẹrẹ ni ile ijọsin Synagogue Church of All Nations, SCOAN, to wa ni agbegbe Ikotun, nipinlẹ Eko, lati ri awọn gbajumọ lawujọ.
Lara awọn ti a ri nibẹ ni oṣerebinrin Jumoke George, Ronke Ojo, Femi Branch.
Koda, Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams, ati Minisita Naijiria nigba kan fun irianjo oju ofurufu, Femi Fani-Kayode, naa ba wọn kopa.
Ninu ọrọ ti Gani Adams ba BBC Yoruba sọ, o ni oloogbe TB Joshua kii sẹ ajihinrere nikan, o tun jẹ alaanu ọpọlọpọ eniyan.
O ṣalaye pe inu ọ̀fọ̀ ni awọn ara ilu Arigidi-Akoko, nibi ti Joshua ti wa.
Ọmọ ilu Arigidi naa ni Gani Adams.
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìròyìn tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn jùlọ
Content is not available
{{rankTranslation}}