Akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́rin jáde láyé bí ọkùnrin tó lọ forúkọ ọmọ rẹ̀ sílé ẹ̀kọ́ wọn, ṣe gún wọn lọ́bẹ pa

Oríṣun àwòrán, Uganda Police Force
Àwọn ọmọdé mẹ́rin, tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún méjì sí ọdún mẹ́ta, ni wọ́n ti pàdánù ẹ̀mí wọn bí ọkùnrin kan ṣe gún wọn lọ́bẹ pa.
Ní ìlú Kampala, olú ìlú orílẹ̀ èdè Uganda ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé ní ilé ẹ̀kọ́ jẹ́léósinmi kan.
Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Uganda sọ pé afurasí tó hùwà láabi náà ló jẹ́ ọkùnrin, ẹni ọdún mọ́kàndínlógójì.
Wọ́n ní afurasí ọ̀hún lo ọ̀bẹ tó ju ẹyọ̀kan lọ láti fi ṣe iṣẹ́ láabi yìí àti pé níṣe ni àwọn ọmọ náà - ọkùnrin mẹ́ta àti obìnrin kan dágbére fáyé lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Àtẹ̀jáde ti iléeṣẹ́ ọlọ́pàá náà fi sójú òpó X wọn sọ pé ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ti tẹ afurasí náà, tó sì ti wà ní àhámọ́.
"Ọ̀pọ̀ àwọn òbí tí inú ń bí ni wọ́n fẹ́ yabo ọkùnrin náà kí àwọn ọlọ́pàá tó fi póró òfin gbé e"
Wọ́n ní ìwádìí ti ń lọ láti mọ ohun tó mú afurasí náà hùwà tó wù, láti ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìmọ̀ nípa rẹ̀ àti gbogbo ohun tó le ṣe ìrànwọ́ fún ìwádìí wọn lórí ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà.
Iléeṣẹ́ ìròyìn AFP sọ pé agbẹnusọ ọlọ́pàá Uganda, Racheal Kawala ní ọ̀pọ̀ àwọn òbí tí inú ń bí ni wọ́n fẹ́ yabo ọkùnrin náà kí àwọn ọlọ́pàá tó fi póró òfin gbé e.
Àwọn fídíò tó gba orí ayélujára ṣàfihàn bí ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń bínú, tí ìgbàgbọ́ wà pé wọ́n jẹ́ òbí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wà káàkiri iwájú ilé ẹ̀kọ́ náà pẹ̀lú èròńgbà láti rí ọmọ wọn.
Kawala sọ pé afurasí náà ti ṣáájú lọ sí ilé ẹ̀kọ́ náà ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sẹ̀ yìí láti lọ bèèrè nípa fífi ọmọ rẹ̀ sílé ẹ̀kọ́ náà, tí wọ́n sì ní kó padà wá lọ́jọ́bọ̀.
"Lẹ́yìn tó padà sílé ẹ̀kọ́ náà ló lọ san owó ìbaniwọlé tí wọ́n ní kó san, lẹ́yìn náà ló sì lọ ṣe ìkọlù sáwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà, tó sì pa mẹ́rin nínú wọn lójú ẹsẹ̀.
Ileesẹ ọlọpaa sọrọ lori isẹlẹ naa
Ní nǹkan bíi aago mọ́kànlá òwúrọ̀ ni àwọn ọlọ́pàá gba ìpè lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, tó sì dájú pé ó ti wáyé kí wọ́n tó pe àwọn ọlọ́pàá.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá náà fi kun pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́wàá míì tó wà nílé ẹ̀kọ́ Ggaba Early Childhood Development Program School lásìkò tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé ni wọ́n ti dá padà fáwọn òbí wọn.
Àwọn tó ń ṣe ìwádìí ṣì wà ní ilé ẹ̀kọ́ náà, tí Kawala sì sọ pé àwọn máa fi ìròyìn bí ìwádìí bá ṣe ń lọ ní agbègbè náà kéde láìpẹ́.
Ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, Abas Byakagaba ti ṣe àbẹ̀wò sí ilé ẹ̀kọ́ náà, tó sì rọ àwọn aráàlú láti fi ọkàn balẹ̀, tí àwọn ọlọ́pàá yóò sì máa tẹ̀síwájú pẹ̀lú iṣẹ́ wọn.
Níṣe ni gbogbo ìta ilé ẹ̀kọ́ náà, níbi tí àwọn òṣìṣẹ́ kan dúró sí, pa lọ́lọ́.
Ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti dá ìbẹ̀rùbojo sọ́kàn àwọn èèyàn káàkiri orílẹ̀ èdè náà, báwọn èèyàn ṣe ń kọminú lórí ààbò àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní orílẹ̀ èdè ọ̀hún.


























