'Ìwà ọ̀daràn sí ẹ̀tọ́ ọmọnìyan tó burú jùlọ': Ṣé ó yẹ káwọn orílẹ̀ èdè tó kó ilẹ̀ Africa san owó gbà mábinú?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Fernando Duarte
- Role, BBC World Service
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
Igbimọ aṣofin aajọ ìṣọkan agbaye ti buwọlu kikede fifi awọn eeyan ṣe ẹru gẹgẹ bi iwa ọdaran to buru julọ ti wọn ṣe lati fi tẹ ẹtọ awọn eeyan mọlẹ. Nibi ifẹnuko naa ti wọn ti rọ gbogbo awọn orilẹ ede to ko awọn eeyan lẹru lati da awọn ohun ini awọn eeyan bẹẹ ti wọn ji ko pada.
Aarẹ Ghana, John Mahama lo gbe ijabọ naa kalẹ pẹlu atilẹyin ajọ iṣọkan ilẹ Africa, Africa Union pẹlu erongba lati ri daju pe gbogbo awọn ti wọn ko lẹru nigba naa ri iwosan, ki wọn si gba owo gba mabinu.
Ibo 123 ni aba naa ni nigba ti awọn orile ede 52 to fi mọ United Kingdom ati awọn orilẹ ede ilẹ Yuroopu kọ lati gba aba naa wọle.
Orilẹ ede Amẹrika, Argentina ati Israel kọ lati ṣatilẹyin fun aba naa.
Mahama sọ fun ajọ iṣokan agbaye pe gbigba aba naa wọle ko ni jẹ kawọn orilẹ ede naa gbagbe.
Awọn orilẹ ede ti ikonilẹru ṣe akoba fun ti n beere fun mimu atunṣe ba iwa yii lati bii ọgọrun-un ọdun sẹyin amọ ti ipe naa ti wa peleke si ni sẹnturi kọkanlelogun paapaa nigba ti awọn orilẹ ede kan ti wọn jẹ anfaani owo ẹru gba pe awọn lọwọ ninu rẹ.

Oríṣun àwòrán, Anadolu via Getty Images
Ki ni sisan owo gba mabinu lori owo ẹru?
Lati sẹnturi kẹẹdogun si kọkandinlogun, awọn eeyan ti iye wọn to miliọnu mejila si mẹẹdogun nilẹ Africa to fi mọ awọn ọkunrin, obinrin atawọn ọmọde ni wọn ko lọ lati ta soko ẹru, ti wọn si fi wọn ṣọfa.
Lara awọn orilẹ ede ti wọn ta wọn si ni Spain, Portugal, France ati Great Britain. Eeyan to to miliọọnu meji ni igbagbọ wa pe wọn padanu ẹmi wọn sinu ọkọ ti wọn fi n ko awọn eeyan naa loko ẹru.
Ipa ti ikonilẹru naa n ni lori awọn eeyan ilẹ Africa ṣi wa titi di oni ni awọn orilẹ ede ti wọn ti ko awọn eeyan naa lẹru.
Awọn eeyan orilẹ ede naa wa n beere fun titọrọ aforiji ati sisan owo gba mabinu fawọn orilẹ ede ti wọn fori sọta ikonilẹru ni tipatipa eyi ti orilẹ ede Ghana n lewaju rẹ ti wọn si n rọ ajọ iṣọkan agbaye lati tọrọ aforiji lọwọ awọn eeyan naa.

Oríṣun àwòrán, The Washington Post / Getty Images
Minisita fọrọ ilẹ okeere tẹlẹ ri ni Ghana, Samuel Okudzeto Ablakwa sọ fun eto BBC Newsday pe awọn n beere fun owo gba mabinu ati pe kii ṣe awọn adari ilẹ Africa kan n beere owo naa fun apo ara wọn.
"A n fẹ idajọ ododo fawọn eeyan wa ti wọn ta soko ẹru, a si n fẹ atilẹyin ati owo idanilẹkọọ."
Sugbọn Esther Xosei, to jẹ onimọ nilẹ Britain, to si tun jẹ ọkan lara awọn ajafẹtọọ to n beere fun awọn nnkan naa n fi ikọnilominu han lori ipa ti awọn ibeere naa maa ni lori awọn eeyan.
O ni o jẹ ohun iwuri pe awọn orilẹ ede n lewaju lori ijiroro yii ṣugbọn to woye pe o ṣeeṣe ki wọn ma riI atilẹyin ni UN.

Oríṣun àwòrán, United Nations
Se wọn ti fun awọn eeyan ni owo gba mabinu ri?
Lati ọdun 1952, awọn orilẹ ede ilẹ Yuroopu tis an owo to le ni ọgọrin biliọnu dọla fawọn eeyan Juu ti wọn fori sọta iṣejọba Nazi to fi mọ owo ti wọn san fun Israel.
Amọ ko I tii si orilẹede kankan to san owo ikonilẹru fun awọn eeyan ilẹ Africa, Carribean ati latin Amerika.
Koda awọn orilẹ ede ti wọn ti tọrọ aforiji ni gbangba fun ipa ti wọn lori ọrọ ikonilẹru bii Netherlands lọdun 2022 ti ni awọn ko ni san owo kankan fawọn to fori sọta owo ẹru. Ijọba Dutch ni tirẹ ni awọn ti ṣe idasilẹ owo $230m lati fi ṣe awọn akanṣe iṣẹ lori ipa owo ẹru.
"Ohun to ṣe Pataki julọ ni pe ẹnikẹni ko maa gbiyanju lati mu ayipada ba awọn iṣẹlẹ atijọ ṣugbọn lati koju awọn ipa to ni lori asiko ti a wa yii," Dokita Celeste Martinez to jẹ oniwadii nipa bi Spain ṣe ko awọn eeyan lẹru nilẹ Africa sọ.

Oríṣun àwòrán, Universal Images Group via Getty Images

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
Elo ni owo ti a n sọrọ nipa rẹ?
Ajọ iṣọkan agbaye ti ṣe atilẹyin fun idajọ ododo lori owo ẹru. Ni ọdun 2025, ọga agba ẹka to n ri si ẹtọ ọmọniyan, Volker Türk, sọ pe wọn gbọdọ fun awọn eeyan naa ni owo gba mabinu.
Sugbọn igbimọ aṣofin ajọ UN, nibi ti gbogbo awọn orilẹ ede 193 ti ni anfaani lati ṣoju orilẹ ede wọn ni ọkọọkan ko I tii dibo nipa rẹ.
Igbimọ naa ko le pa a ni dandan fawọn orilẹ ede ti ọrọ kan.
Lara awọn nnkan ti wọn sọrọ nipa rẹ julọ ni pe ta lo maa san owo ati pe elo gan ni wọn yoo san.
Øpọ awọn ileeṣẹ ati ẹbi ti wọn ni ẹru ni wọn ti n pe lati san owo gba mabinu amọ awọn ijọba ni ọpọ ibeere n dari si julọ. ni ọdun 2013, awọn orilẹ ede Caribbean mẹẹdogun ni wọn gbe aba mẹwaa jade lori ọna ti wọn fẹ fi gba idajọ ododo.
Lara ohun ti wọn beere fun ni pipa awọn gbese ti wọn jẹ nilẹ okeere rẹ ati lẹka eto ilera.

Oríṣun àwòrán, Ullstein Bild via Getty Images
Ni ọdun kan naa, Patrick Robinson, to jẹ adajọ ni ile ẹjọ International Court of Justice tun gbe idajọ kalẹ pe apapọ owo $107trn ti awọn orilẹ 31 jẹ to ffi mọ awọn orilẹ ede bii Brazil ati US ti wọn jẹ anfaani owo ẹru julọ lẹyin ti wọn gba ominira lọwọ Portugal ati Great Britain.
Lara awọn ohun to jẹ iṣoro sisan owo yii ni asiko to ti lọ lori rẹ, eyi to ti ṣẹlẹ bẹẹ ri ni ti awọn to lugbadi Holocaust eyi ti wọn yanju nigba ti awọn to lugbadi rẹ ṣi wa laye.
Onimọ nipa ofin, Luke Moffet, olukọ ni ile ẹkọ Queen's University Belfast gbagbọ pe awọn nọmba naa ko ṣe e fi mulẹ.

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
Ki lawọn aforiji naa?
Awọn ipolongo bii ti Caricom ko duro lori owo nikan. Okan lara ohun ti wọn n kọminu le lori ni pe awọn orilẹ ede ti wọn jẹ anfaani rẹ julọ ko tọrọ aforiji.
Verene Shepherd sọ pe titọrọ aforiji lọwọ awọn iran awọn ti wọn lọ fi ṣẹru latọdọ ijọba ilẹ Yuroopu.
O ni dipo bẹẹ, awọn orilẹ ede kan gbe atẹjade sita lati fi bu ẹnu atẹ lu ṣiṣe owo ẹru ni eyi to jẹ ko dabi pe awọn eeyan naa ko nilo ki wọn tọrọ aforiji lọwọ wọn.
Sara Hamood to jẹ oṣiṣẹ lẹka ajafẹtọọ ni UN sọ pe gbigba pe o waye jẹ igbesẹ akọkọ lati gba idajọ ododo.
"Gbigba owo kan jẹ ara rẹ ni, titọrọ aforiji ati sisọ jẹ ara ọna lati wa ojutuu sii."























