UK ní òhun kò ní bá Amẹ́ríkà kógun ja Iran, bí China ṣe bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti fòpin sí ogun

Àwòrán ohun ìjà ogun lẹ́gbẹ̀ẹ́ etí odò

Oríṣun àwòrán, MOD CRWON COPYRIGHT/PA

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Olóòtú ìjọba United Kingdom, UK, Sir Keir Starmer ti ní orílẹ̀ èdè náà yóò wá ọ̀nà láti mú kí àjọṣepọ̀ tí wọ́n ní pẹ̀lú àjọ ìṣọ̀kan ilẹ̀ Yúróòpù, EU gbokùn síi.

Starmer sọ èyí níbi ìtàkurọ̀sọ tó ṣe pẹ̀lú àwọn akọ̀ròyìn lọ́jọ́rú látàrí ogun tó ń lọ ní Iran.

Ó sọ pé àwọn máa lo ìpàdé àpérò tó máa wáyé láàárín UK àti EU ní ọdún yìí láti fi wa àjọṣepọ̀ EU lórí ètò ọrọ̀ ajé àti ààbò.

Ìgbésẹ̀ yìí ló ń wáyé látàrí ìyapa ẹnu tó ń wáyé láàárín Amẹ́ríkà àti UK lẹ́yìn tí olóòtú ìjọba náà ní òun kò ní jẹ́ kí Amẹ́ríkà wọ òun wọnú ogun tí Amẹ́ríkà àti Israel ń gbé ti Iran.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Starmer ṣèkìlọ̀ pé ogun náà ṣeéṣe kó ní ipa lórí ọrọ̀ ajé UK ṣùgbọ́n tó sọ àrídájú rẹ̀ pé ìjọba ń gbé ìgbésẹ̀ láti mú àdínkù bá ìpèníjà táwọn èèyàn ń kojú.

Ṣáájú ni àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò ti ní kí ìjọba sọ àwọn ìgbésẹ̀ tí wọ́n ń gbé láti mú àdínkù bá owó epo tó ń lọ sókè, tí wọ́n sì ń bèèrè pé kí ìjọba yọ owó orí táwọn èèyàn ń san lórí àwọn ohun àmúṣagbára.

Olóòtú ìjọba náà ní òun dúró lórí ìpinnu òun pé àwọn kò ní bá Amẹ́ríkà àti Iran dá sí ohun tí wọ́n ń gbe ti Iran, tí ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump sì ti bu ẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ yìí, tó sì ní kí wọ́n lọ máa gbé epo wọn fúnra wọn ní Strait of Hormuz.

Ẹ̀wẹ̀, akọ̀wé iléeṣẹ́ ilẹ̀ òkèèrè ni àwọn máa ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn orílẹ̀ èdè márùndínlógójì ní ọjọ́bọ̀ tó fi mọ́ àwọn orílẹ̀ èdè nílẹ̀ Yúróòpù àti àwọn orílẹ̀ èdè ilẹ̀ Arab.

Wọ́n ní ìpàdé náà máa dá lórí bí wọ́n ṣe máa rí ààyè wọ Strait of Hormuz lẹ́yìn tí ogun bá parí.

Pakistan, China bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti jẹ́ kógun ó sinmi

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nínú ìròyìn míì, bí ogun tí Amẹ́ríkà àti Israel ń gbé ti Iran ṣe ti ń wọ oṣù méjì lọ, tó sì ń ṣe àkóbá fún epo rọ̀bì káàkiri àgbáyé, orílẹ̀ èdè China ti ń gbìyǹjú láti wá ọ̀nà láti pẹ̀ẹ̀tù sí aáwọ̀ náà.

Ìgbésẹ̀ China yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí Trump sọ pé ó ṣeéṣe kí ogun tí wọ́n ń gbé ti Iran parí láàárín ọ̀sẹ̀ méjì sí mẹ́ta àma kò sọ bí èyí ṣe máa wáyé.

China ló ń darapọ̀ mọ́ Pakistan láti pèsè ìlànà márùn-ún tí wan máa gbà láti fi òpin sí ogun náà.

Pakistan, tó jẹ́ ọ̀rẹ́ pẹ̀lú Amẹ́ríkà ti ríbi kó sí ààrẹ Amẹ́ríkà nínú láti báwọn dá sí ogún náà lójúnà àti fòpin síi.

Àmọ́ China, tí òhun àti Amẹ́ríkà ti ń ṣe ọ̀tá fún ọjọ́ pípẹ́ ni yóò máa kópa níbi ìgbésẹ̀ yìí ṣáájú ìpàdé tí ààrẹ China, Xi Jinping yóò ṣe pẹ̀lú Trump lóṣù tó ń bọ̀.

Onímọ̀ nípa Middle East, Zhu Yongbiao, tó tún jẹ́ adarí ẹ̀ka Centre for Afghanistan Studies ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Lanzhou wòye pé China yóò pèsè àtìlẹyìn pẹ̀lú èròńgbà pé Pakistan máa kó ipa tó lòòrìn lórí ìpẹ̀tùsááwọ̀ náà.

Ó ní ìbéèrè ńlá ni pé kí ló dé tí China ń dìde láti dá sí ogun náà báyìí pẹ̀lú bí wọ́n ṣe dákẹ́ láti ìgbà tí ogun náà ti bẹ̀rẹ̀.

Ìgbésẹ̀ yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí mínísítà fún ilẹ̀ òkèèrè orílẹ̀ èdè Pakistan gbéra lọ sí China láti bèèrè àtìlẹyìn China láti wá ojútùú sí bí wọ́n ṣe máa paná ogun náà.

Mínísítà fún ilẹ̀ òkèèrè orílẹ̀ èdè China ní ọ̀nà kan gbòógì tó ṣe kókó láti fi paná ogun ni ìjíròrò, tó sì wòye pé ó ṣe pàtàkì láti dá ààbò bo gbogbo àwọn ìrìnnà ojú omit ó fi Strait of Hormuz tí Iran tì pa.