Nàíjíríà ti ń dojú dé, ìyapa Yoruba Nation àti Biafra lọ̀nà àbáyọ, àlàyé rèé lórí ọ̀nà tá fi gba òmìnira láàrin àádọ́rún-ún ọjọ́ - Banji Akintoye

Awọn ọmọ ẹgbẹ Yoruba Nation di mọ asia ẹgbẹ naa
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn ọmọ ẹgbẹ to n pe fun ijigbara orilẹede Yoruba ati Biafra tun ti bẹrẹ ipe naa pada pẹlu ikede aadọrun ọjọ lati mu afojusun naa wa si imuṣẹ.

Ọkan lara awọn to n lewaju idasilẹ orilẹede Yoruba, Ọjọgbọn Banji Akintoye lo kede bẹẹ pẹlu afikun pe idasilẹ awọn orilẹede naa nikan lo le yọri si alaafia ati idagbasoke ni Naijiria.

Nibi ipade kan to waye niye niluu Atlanta, nilẹ Amẹrika ti Akintoye darapọ lori ayelujara, o ni fun ọpọ ọdun ni Naijiria ti n dojude gẹgẹ bii orilẹede, iyapa ẹya Igbo ati Yoruba nikan lo si le mu ki nnkan rọgbọ faraalu.

Ọjọgbọn Banji Akintoye nibi eto ilu kan

Oríṣun àwòrán, Banji Akintoye

Ki ni idi ti Akintoye fi n pe fun iyapa?

Akintoye sọ nibi ipade naa pe "ki ni idi ti a fi n pe fu ominira wa?

"Ko ṣẹyin pe awọn eeyan wa ko tii mọ ohun to n jẹ alaafia lati igba ti wọn ti so gbogbo wa pọ lọdun 1914.

"Ohun to n ṣẹlẹ ni Naijiria ti kọja pe ẹya kan n gbiyanju lati pa ẹya mii run, o ti di rogbodiyan ti gbogbo agbaye gbọdọ da si."

Ilana bi Yoruba ati Igbo yoo ṣe pinya

Nibi ipade ọhun ni wọn ti fẹnuko lori ọna ti awọn ẹya mejeji yoo gba kuro lara Naijiria ati bi wọn yoo ṣe kọ ofin ti orilẹede Oduduwa ati Biafra yoo maa lo lẹyin ti wọn ba pinya tan laarin aadọrun ọjọ pere.

Akintoye sọ pe ti wọn ba kọ awọn ofin naa tan, wọn yoo fi le ajọ United Nations lọwọ, to fi mọ ajo African Union, ECOWAS, atawọn ile igbimọ aṣọfin awọn orilẹede to ti goke agba lagbaye.

O ni "Afojusun wa ni lati fun awọn eeyan wa ni irọrun ati itẹsiwaju lori ilẹ ti Eledua fun awọn babanla wọn nibi ti wọn ti le ṣe rere pẹlu awọn ọmọ wọn.

"A rọ gbogbo awọn ajo agbaye ki wọ ti wa lẹyin lati ti pin Naijiria.... eyii jẹ ọrọ idajọ ododo, eto abo to peye ati ọjọ ọla ẹgbẹlẹgbẹ eeyan ti wọn ti wa ninu igbekun awọn jẹgudujẹra fun ọdun pipẹ."

Awọn mii ti wọn n fẹ iyapa Naijiria

Lara awọn mii to n fẹ iyapa Yoruba ati Igbo kuro lara Naijiria ni oloye Sunday 'Igboho' Adeyemo to pariwo ọrọ naa fun ọpọ ọdun, paapaa lasiko ijọba Aarẹ ana, Muhammadu Buhari.

Igboho ti n ṣatilẹyin fun ijọba Bola Ahmed Tinubu bayii lẹyin ti Tinubu yọ okun ọdaran ti wọn n wa lọrun rẹ.

Ẹlomii to n fun pe fun idasilẹ orilẹede Yoruba ni Ọmọwe Kayode Emola to sọ pe ẹya Igbo ati Yoruba le kuro lara Naijiria lai jagun gẹgẹ bo ṣe waye ni Yugoslavia lọpọ ọdun sẹyin.

Ẹni to ṣoju ẹya Igbo nibi ipade ọhun, Mazi Tony Nwisi, to jẹ alaga ajọ Igbo Global Network sọ pe fun ọpọ ọdun ni wọn ti n yọ ọwọ awọn Igbo kuro lawo Naijiria, asiko si ti to fun awọn lati lọ.

Awọn mii to tun wa nibẹ lorukọ awọn Igbo ni Mazi Emmanuel Kanu ati Mazi Ositadimma Igenu ti wọn ni awọn ko ni fi ọrọ naa ṣe ija tabi jagidijagan rara, amọ lilọ awọn kuro lara Naijiria gbọdọ di ṣiṣe laipẹ.