Agbèbọ́n tún ṣọṣẹ́ ní Plateau, pa ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́jọ́ Ìsinmi Ọ̀pẹ

Aworan awon agbebon to gbe ibon kọrun ninu igbo, wọn n rin lọ.

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ikọlu tuntun mi-in tun waye lanaa ọjọ Aiku, ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kẹta ọdun 2026 yii ti i ṣe ọjọ isinmi Ọpẹ, nipinlẹ Plateau, nibi ti ọpọ eeyan ti di oloogbe ti ọpọ si farapa yanna-yanna.

Ilu kan ti wọn n pe ni Gari Ya Waye, lagbegbe Angwan Rukuba, ipinlẹ Plateau ni iṣẹlẹ naa ti waye.

Alẹ ọjọ Aiku ana ti ikọlu naa waye ni ijọba kede ofin konilegbele ọlọjọ meji, lati so okun aabo le si i.

Konilegbele ọhun ti yoo bẹrẹ ni aago mejila oru ni yoo wa bẹẹ titi di lọjọ akọkọ ninu oṣu Kẹrin ọdun 2026 yii.

Ki lo ṣẹlẹ gan-an?

Nnkan bii aago meje aabọ si mẹjọ alẹ ọjọ Aiku ni awọn agbebọn ṣina ibon bolẹ fun awọn olugbe Gari Ya waye, eyi to wa ni Angwan Rukuba.

Ibi kan ti awọn eeyan pe jọ pọ si ni a gbọ pe wọn ti deede ṣina ibọn bolẹ, to si ba ọpọ eeyan lojiji.

O kere tan, eeyan mejila lo di oku lẹsẹkẹsẹ gẹgẹ bi awọn iroyin agbegbe naa ṣe ṣalaye.

Ọpọ eeyan ni wọn lo tun farakaasa ibọn pẹlu, ti wọn si balẹ si ile iwosan to wa nitosi, nibi ti wọn ti n gba itọju.

Lasiko ti a n kọ iroyin yii, awọn alaṣẹ ko ti i sọ pato iye eeyan to di oloogbe ninu ikọlu ọhun.

"Ẹ fidi mọle yin bi awọn ẹṣọ alaabo ṣe n wọde kiri"

Atẹjade lati ọdọ ijọba ipinlẹ Plateau ti rọ awọn olugbe ilu naa lati fidi mọle bi awọn ẹṣọ alaabo ṣe n wọde kiri.

Kete ti ibọn yinyin ọhun wa sopin ni wọn ti da awọn eleto aabo naa sita pẹlu awọn agbofinro ti yoo ri si ki alaafia jọba, ti wọn yoo si mu awọn to ṣiṣẹ ibi naa.

Ikọlu agbebọn yii ti mu ọpọ nnkan duro ni Plateau, pẹlu bi awọn ile ẹkọ titi kan Yunifasiti ilu Jos ṣe ti tun ilana iṣẹ wọn to nitori ai si aabo to peye.

Bakan naa lo jẹ pe ipinlẹ Plateau wa lara awọn apa ibi ti ikólu ti maa n ṣẹlẹ l'Ariwa.

Ilu Jos to jẹ olu ilu naa ti foju wina ọpọ ikọlu ṣaaju lati bii ọdun mẹwaa sẹyin, gbogbo igbiyanju ijọba lati ṣẹgun rẹ ko si ti i fi bẹẹ so eso rere.

Bo si tilẹ jẹ pe ijọba ipinlẹ Pleateau n sọ pe ohun gbogbo wa labẹ akoso alaafia, sibẹ, ofin konilegbele ti wọn gbe jade yii ti mu ọpọ eeyan maa sọ pe ina ti jo de ori koko bayii nipa ọrọ aabo.

"Ko si idi kankan fun ikọlu yii rara, o buru jai''

Nigba to n ṣalaye nipa ikọlu yii, Gomina ipinlẹ Plateau,

Caleb Manasseh Mutfwang, sọ pe ohun ti ko si idi kankan fun ni.

Ninu atẹjade to fi sita ni Gomina Mutfwang ti koro oju si iṣẹlẹ yii, to si ni oun ti paṣẹ fun awọn ẹṣọ eleto aabo lati wa awọn agbebọn naa ki wọn si mu wọn ṣinkun.

O ni wọn gbọdọ fi wọn jofin gẹgẹ bo ṣe yẹ.