N kò ní parí aáwọ̀ láàrin Funke Akindele àti Toyin Abraham mọ́, ó tó gẹ́ ẹ́ - Iyabo Ojo

Oríṣun àwòrán, Funke Akindele/ Iyabo Ojo/Toyin Abraham/Instagram
Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà, Iyabo Ojo ti dá sí aáwọ̀ tó wáyé láàárín àwọn àgbà òṣèré méjì Funke Akindele àti Toyin Abraham.
Eyi lo n waye lẹyin ọjọ meji ti Funke Akindele kọ lati da Toyin Abraham lohun nigba to n ki ni ode Iyabo Ojo to waye lopin ọsẹ, lọjọ Aiku, ọjọ Kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹta.
Ẹ o ranti pe ni ọjọ Aiku ni fidio gba ori ayelujara nibi ti Toyin Abraham ti n ki Funke Akindele ti wọn jọ jẹ agba oṣere, ṣugbọn ti Funke leju pa ti ko si dahun ikini naa.
Ninu fidio ọhun, Toyin tawọn eeyan mọ si Iya Ire, n ki awọn to wa nikale lode afihan fiimu ti Iyabo Ojo onitiata n ṣe lọjọ Aiku, nipinlẹ Eko.
Bo ṣe de ibi ti Funke wa lo sunmọ ọn to si n pe e; Ánti Funke, Anti Funke.''
Ṣugbọn kaka ki Funke tawọn eeyan tun mọ si Jenifa dahun, niṣe lo kọ oju rẹ si ọọkan, to n woke lai rẹrin-in rara, ko si dahun ikini naa, bo tilẹ jẹ pe ẹni to jokoo ti I dahun ni tiẹ.
Nigba ti Toyin ri I pe Funke ko dahun, o fi I silẹ, o si gba ibomiran lọ jokoo.
'Mo sunkun, mo kunlẹ, mo bẹ awọn mejeeji pe ki wọn gba alaafia laaye laaarin wọn'

Oríṣun àwòrán, Toyin Abraham/IG/ Funke Akindele/IG
Lẹyin naa ni Toyin kọ soju opo Instagram rẹ, ko to pa ariwisi naa rẹ pe oun ko telẹ Funke Akindele lori ayelujara mọ ati pe oun ko ni ki Funke Akindele, pe ọmọ ale ni oun ti oun ba pada ki i.
Ọpọ eeyan lo ti wa n kan si Iyabo Oo pe ko da si ifanfa to n waye laaarin Funke Akindele ati Toyin Abraham paapaa bi awọn mejeeji ṣe jẹ ọrẹ rẹ ati pe ibi ayẹyẹ ni iṣẹlẹ naa ti waye.
Iyabo Ojo ti wa sọrọ bayii ninu atẹjade kan to kọ soju opo Instagram rẹ lọjọ Iṣẹgun, ọjọ Kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹta nibi ti to ti sọ awọn igbesẹ to ti gbe lori awọn mejeeji.
O ni ọpọ eeyan ni wọn ti n bu oun, ti wọn si n sọrọ odi si oun pe oun ko da si aawọ awọn agba oṣere mejeeji.
O sọ pe oun ti gbiyanju agbara oun lati pari aawọ to maa n fi gbogbo igba waye laaarin Funke Akindele ati Toyin Abraham.
"Mo sunkun, mo kunlẹ, mo bẹ awọn mejeeji pe ki wọn gba alaafia laaye laaarin wọn ti wọn si gba si mi lẹnu. Idi niyẹn ti ẹ fi ri ti awọn mejeeji fi n sọrọ papọ ni ode ariya ni oṣu diẹ sẹyin."
O ṣalaye pe awọn fi lelẹ nibẹ pe ẹnikẹni ko gbọdọ sọ ohunkohun to lodi tabi tabuku ẹnikeji lori ayelujara ti iṣẹlẹ kankan ba
'O yẹ ki Toyin Abraham wa ninu Arinzo, oun lo ni oun ko ṣe mọ'
Iyabo Ojo ni amọ nigba to di oṣu Kejila ọdun to kọja ti awọn mejeeji gbe fiimu lọ sinima, Toyin Abraham ni awọn kan n tẹ fiimu oun ri, wọn ko jẹ kawọn eeyan wo fiimu naa daadaa.
O ni bawọn eeyan ṣe n naka aleebu si Funke Akindele pe oun lo ṣokunfa bi wọn ṣe n tẹ fiimu Toyin ri, o ni eyi lo fa ikunsinu laaarin awọn mejeeji ko to di ọjọ ti wọn maa pade nibi ayẹyẹ oun.
Lori bawọn eeyan ṣe n sọrọ pe Iyabo Ojo ko fi Toyin Abraham sinu fiimu Arinzo to ṣẹṣẹ jade naa, o ni o yẹ ki Toyin wa nibẹ ṣugbọn o pada pe oun ko le kopa ninu fiimu naa nitori o rẹ oun.
O ni oun fẹ lọ sinmi, a ti pe oun fẹ rinrin ajo ti oun ko si le kopa ninu fiimu naa mọ.
Iyabo Ojo ni bi Toyin ṣe sọ fun oun pe oun ko le kopa ninu fiimu naa mọ dun oun nitori oun ṣẹṣẹ nilo lati tun fiimu naa kọ.
O ṣalaye pe Toyin ti bẹ oun ti awọn si ti pari ọrọ naa amọ o dun oun pe gbogbo nnkan yii n ṣẹlẹ nitori oju ọrun to ẹyẹ fo lai fara kanra.
O sọ pe oun ti gbiyanju agbara oun ti oun ko si le bẹ ẹnikẹni mọ ati pe ti awọn mejeeji ba ṣetan lati pari aawọ to wa laaarin wọn, wọn maa ṣe bẹẹ.
Kí ló fà á tí Funke Akindele kò fi dáhùn kíkí tí Toyin Abraham kí i lóde?
Ikini ṣe pataki pupọ nilẹẹ Yoruba, nitori o maa n fi ibọwọ fun agba ati iwa ọmọluabi han ni.
Ṣugbọn ti wọn ba ki eeyan ti tọhun ko dahun, to si gbọ ikini ọhun, yoo ni idi kan ṣaa ni.
Ohun to ṣẹlẹ ninu fidio kan to kari ayelujara bayii niyẹn, nibi ti Toyin Abraham ti n ki Funke Akindele ti wọn jọ jẹ agba oṣere, ṣugbọn ti Funke leju pa ti ko si dahun ikini naa.
Ninu fidio ọhun, Toyin tawọn eeyan mọ si Iya Ire, n ki awọn to wa nikale lode afihan fiimu ti Iyabo Ojo onitiata n ṣe lọjọ Aiku ana, nipinlẹ Eko.
Bo ti de ibi ti Funke wa lo sunmọ ọn to si n pe e; Ánti Funke, Anti Funke.''
Ṣugbọn kaka ki Funke tawọn eeyan tun mọ si Jenifa dahun, niṣe lo kọ oju rẹ si ọọkan, to n woke lai rẹrin-in rara, ko si dahun ikini naa, bo tilẹ jẹ pe ẹni to jokoo ti I dahun ni tiẹ.
Nigba ti Toyin ri I pe Funke ko dahun, o fi I silẹ, o si gba ibomiran lọ jokoo.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Kí ló dé tí Funke fi Toyin gún lágídi?
Bi fidio ọhun ṣe han to, ti ohun to ṣẹlẹ nibẹ ko ruju rara, aṣiri ohun to fa a ti Funke Akindele fi leju pa ko ti I han sita.
Ohun kan ti ọpọ eeyan tiẹ n sọ lori ayelujara ni pe Funke Akindele tawọn mọ ki i ṣe onigberaga.
Wọn ni ẹni to maa n ko ọpọ eeyan mọra ni Funke to bi Ibeji, ohun to jẹ ko fi Iya Ire gun lagidi ko ye awọn.
Ṣugbọn alaye awọn miran ni pe awọn iwa ti Toyin ti hu si Funke tẹlẹ lo jẹ ko 'jẹ oju rẹ' laarin ero.
Wọn ni bi Iya Ire ṣe maa n fi fiimu rẹ si asiko kan naa ti Funke ba gbe sinima jade le ma dun mọ Jenifa ninu.
Bakan naa ni awọn kan sọ pe Toyin maa n figagbaga pẹlu Funke Akindele ju, bẹẹ, Funke ki I ṣe ẹgbẹ rẹ nibi kankan.
Awọn ere bii meji ti Funke ti gbe lọ si sinima, to si jẹ pe asiko yẹn naa ni Toyin naa gbe tiẹ si, pẹlu awọn ọrọ to farajọ ifigagbaga ti wọn ni Iya Ire ti sọ ri nipa Funke ni awọn miran sọ pe o fa a ti Funke fi kọyin si I lode ariya.
Awọn iṣẹlẹ yii tipẹ, ọpọ eeyan lo si ro pe awọn oṣere meji yii ti gbagbe nipa rẹ, ṣugbọn ohun ti Funke ṣe yii lo jẹ ki wọn maa sọ pe aarin wọn ko tii gun rege.
Mo gbàdúrà títí kí n tó lè padà sọ́dọ̀ Funke Akindele lẹ́yìn tí a pínyà- Toyo Baby

Oríṣun àwòrán, BBC/Funke Akindele/Instagram
Ọdọbinrin onitiata to di gbajumọ nipasẹ ere agbelewo ti Funke Akindele gbe jade nigba kan, Juliana Olayode tawọn eeyan mọ si Toyo Baby, ti ṣalaye idi to fi pada sọdọ gbajumọ oṣere naa lẹyin ti ipinya de laarin wọn.
Ninu ere ti a mọ si Jenifa's Dairy naa ni Toyo Baby ti jẹ Toyosi, ti Funke si maa n pe e ni Toyo Baby.
Ṣugbọn lojiji ni ọdọmọbinrin naa ṣa deede di ẹni ti kopa ninu ere ọhun mọ, ti ọpọ eeyan si n beere pe Toyo Baby da.Ni ọdun 2023 ni Toyo Baby kọkọ ṣalaye ohun to fa ipinya naa nigba to kọ ọ si oju opo Instagram rẹ pe ai ni oye to lagbo ere tiata lo ṣe oun .
O fi kun un nigba naa pe oun ko ri olutọsọna tootọ, nitori ẹni kan to da bii alagbatọ oun nigba naa lo fi atẹjiṣe kan ranṣẹ si awọn awon alakoso iṣẹ naa lai jẹ ki oun mọ.
Eyi lo ni o fa rogbodiyan ti oun si pada kabaamọ bi aarin oun ati Funke to mu oun di gbajumọ ṣe daru.
Toyo Baby sọ pe oun ṣẹṣẹ jade ile ẹkọ girama nigba ti Jenifa fun oun ni anfaani nla lati kopa ninu iṣẹ rẹ to sọ oun di gbajumọ oṣere.
Ninu atẹjade naa lo si ti tọrọ aforiji ita gbangba lọwọ oloore rẹ yii, ti Funke naa si da a lohun pe oun mọ ọn lara lasiko ti Toyo ko ba oun ṣiṣẹ.
Funke Akindele sọ pe oun naa fẹran rẹ, ọmọ oun ni.
"Niṣe ni mo maa n gbadura pe ki Ọlọrun fun mi ni anfaani lati pada sọdọ Funke Akindele''
Nigba to n ṣalaye ohun to ṣẹlẹ lasiko ti ipinya naa fi waye, Juliana sọ lori eto ori ayelujara ti atọkun rẹ jẹ Chude Jideonwo laipẹ yii, pe:
"Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun gan-an ni, ni gbogbo ọdun yẹn, mo kan n fi sinu adura ni.
" Mi o tiẹ kọ ki n ma le ba wọn ṣiṣẹ mọ, ohun ti mo fẹ ni pe ki n le lọ sile wọn, ki n le ba wọn rẹrin-in, ki n ri wọn, ki n ki wọn, ki ajọṣepọ wa ṣaa ma ti bajẹ."
Bẹẹ ni Toyo Baby ṣalaye.
O ni nigba ti adura naa gba ni oun pada sọdọ Funke, to si gba oun tọwọ tẹsẹ.
Latigba ti ija naa si ti pari ni ajọṣepọ awọn mejeeji tun ti gun rege pada, ti ohun gbogbo n lọ bo ṣe yẹ bi Toyo Baby ṣe sọ.
Ta ni Juliana Olayode?

Oríṣun àwòrán, Juliana Olayode/ Instgram
Ṣaaju asiko to bẹrẹ si I kopa ninu ere Jenifa, ọpọ eeyan ni ko mọ Juliana Oluwatobilola Olayode, ṣugbọn akọsilẹ fi han pe wọn bi si idile ọlọmọ mẹjọ, niluu Eko.
Ko too di gbajumọ, Toyo Baby ti kopa ninu awọn ere bii mẹrin, ṣugbọn ti Jenifa lo gbe orukọ rẹ yọ.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu BBC, Olayode sọ pe ẹkọ nipa iṣẹ akọroyin lo wu oun lati ṣe.
O ni eyi ri bẹẹ nitori baba rẹ fẹran lati ma a tẹti si iroyin lori redio ati amohunmaworan.
Olayode sọ pe amọ ala oun ko ṣẹ, nitori pe awọn obi oun ko ri owo san fun ile ẹkọ oun.
"Igba mẹta ni mo ṣe idanwo JAMB, amọ aisi owo jẹ ki n padanu lati fi awọn esi mi wọ fasiti."
O ni eyi lo mu ki oun bẹrẹ si i ṣiṣẹ ni ile itaja kan lati tu owo jọ fun ile ẹkọ giga.
Ko too di pe okiki de nipasẹ iṣẹ Funke Akindele ti oun ti kopa.
Lasiko kan ni ẹnu kun oṣerebinrin yii nitori ọrọ kan to sọ pe ara oun n wa ibalopọ, ti oun si le ṣe igbeyawo kiakia nitori ki oun le ni ibalopọ.
Ọpọlọpọ eeyan lo bu ẹnu atẹ lu osẹrebinrin naa fun ọrọ to sọ yii nigba naa.
Amọ ninu alaye to ṣe fun BBC, Olayode sọ pe awada lasan ni oun fi ọrọ naa ṣe.
O ni oun sọ ọ lati le ṣe iwuri fun awọn eeyan bi t'oun, to n pa ara wọn mọ lai fẹ ẹ ni ibalopọ ṣaaju igbeyawo.
"Mo fẹ ki awọn eeyan naa mọ pe kii sẹ awọn nikan ni ara wọn ma n fẹ ẹ ni ibalopọ, amọ o jẹ iyalẹnu pe awọn eeyan kan ṣi ọrọ mi tumọ.
"Eyi ri bẹẹ nitori pe bi eeyan ba ṣe n dagba si i, ni ara rẹ yoo ma a wa ibalopọ botilẹ jẹ pe o ti pinnu lati mu ara duro titi di inu igbeyawo."
Ṣaaju asiko naa ni Toyo Baby ti maa n gba awọn eeyan ni imọran lori ayelujara lati pa ara wọn mọ.

























