Ìdí rèé tí mo fi so àpò ilé ọmọ mi - Shaffy Bello

Oríṣun àwòrán, Shaffy Bello/Instagram
Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà, Shaffy Bello ti sọ̀rọ̀ ìpinu kan tó ṣe fún ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn lórí ọ̀rọ̀ bíbí àti iye ọmọ tó fẹ́ bí.
Shaffy Bello sọ pé òun ṣe iṣẹ́ abẹ láti dènà bíbí ọmọ tó pọ̀ nítorí òun kò fẹ́ ní ẹbí púpọ̀ nítorí òun ti ní iye ọmọ tó wù òun láti bí.
Bello sọ èyí níbi ètò rẹ̀ kan tó máa ń ṣe lórí Youtube, Shaffy Bello TV níbi tó ti ṣàlàyé ìrìnàjò rẹ̀ lásìkò tó ń bímọ lọ́wọ́ àti àwọn ìpinnu tó ṣe láti fètò sí ọmọ bíbí.
Ó sọ pé láti nǹkan bíi ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n sẹ́yìn ni òun ti so àpò tí ẹyin máa ń gbà wọlé ọmọ láti dènà níní oyún míì lẹ́yìn tí òun bí ọmọ méjì tán.
Ó ní òun gbé ìgbésẹ̀ náà nígbà tí òun ti pinnu pé òun kò fk bí ọmọ kankan mọ́.
Ó ṣàlàyé pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkọ òun nígbà náà ń fẹ́ ọmọ sí, òun dúrọ lórí ìpinnu òun láti má bi ọmọ kan mọ́ lẹ́yìn àwọn méjì tí òun ti bí.
"Ọkọ mi nígbà náà bẹ̀mí pé kí n bí ọmọ kan si. Mi ò fẹ́ ọmọ púpọ̀, kò wùmí láti bímọ si ni mo ṣe kọ̀ jálẹ̀."
Àgbà òṣèré náà ṣàlàyé pé ibi ìdodo òun ni wọ́n gbà láti fi ṣe iṣẹ́ abẹ síso àpò náà fún òun.
Ó sọ pé òun ti mọ iye ọmọ tí òun fẹ́ bí tí òun kò sì fi ìgbà kankan tàbí jẹ́ kí àwùjọ kó sí òun lórí láti bímọ ju iye tí òun fẹ́ lọ.
Shaffy Bello ní òun máa ń sọ fún ara òun pé tí òun bá padà lóyún lẹ́yìn tí òun ṣe iṣẹ́ abẹ náà ó túmọ̀ sí pé òun fẹ́ bí ọmọ ẹ̀mí mímọ́ nìyẹn.
"Mo máa rí ara mi gẹ́gẹ́ bí Mary tuntun tí mo bá tún lóyún lẹ́yìn tí mo ti so "fallopian tube" mi."
Kí ni síso àpò tí ẹyin ń gbà wọ ilé ọmọ "fallopian tube"?
Ìgbésẹ̀ síso àpò tí ẹyin máa ń gbà dé ilé ọmọ tí wọ́n ń pè ní "fallopian tube" máa ń dènà níní oyún fún obìnrin.
Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ètò ìfètò sí ọmọ bíbí tó fọkàn balẹ̀ jùlọ pàápàá fún àwọn obìnrin tí kò fẹ́ bímọ mọ́.
Inú ikùn obìnrin ni wọ́n máa ń là díẹ̀ láti fi ṣe iṣẹ́ abẹ́ síso àpò náà.
Ó máa ń gba kí wọ́n ge tàbí kí wọ́n fi píìnù mu tí ẹyin kò fí ní rí ibẹ̀ kọjá lọ sílé ọmọ.
Síso fallopian tube jẹ́ ohun tó ṣe é yípadà tí obìnrin tó bá ṣe é bá tún yí ìpinnu rẹ̀ padà láti tún bímọ si ṣùgbọ́n àwọn onímọ̀ sọ pé kò sí àrídájú pé obìnrin bẹ́ẹ̀ le lóyún mọ́.
Wọ́n ní lára ohun tó le mú kí àtúnṣe náà tún ṣiṣẹ́ padà máa ń dá lórí irú èyí tí èèyàn bá ṣe tẹ́lẹ̀, ọjọ́ orí àti bí àpò tí wọ́n gé kù bá ṣe ṣẹ́kù sí.
Wọ́n ní ìdá àádọ́ta (50%) sí ọgọ́rin (80%) nínú ọgọ́rùn-ún (100%) àwọn obìnrin tí wọ́n tú àpò wọn tí wọ́n so tẹ́lẹ̀ ló máa ń ní àṣeyọrí nínú oyún padà nígbà tí wọ́n tún iṣẹ́ abẹ náà ṣe.
Ta ni Shaffy Bello?

Oríṣun àwòrán, Shaffy Bello/Instagram
Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà tó máa ń kópa nínú eré sinimá Yorùbá àti Gẹ̀ẹ́sì ni Shaffy Bello.
Ọdún 1997 ló kọ́kọ́ di ìlúmọ̀ọ́ká nígbà tó kópa nínú orin "Love me jeje" tí òun àti Yemi Sodimu jọ kọ.
Fíìmù Eti Keta ni fíìmù kan gbòógì ló kọ́kọ́ kópa níbẹ̀ kó tó di pé ó kópa nínú fíìmù Tinsel lọ́dún 2012.
Orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ni Shaffy Bello gbé dàgbà, níbi tó ti lọ sílé ẹ̀kọ́, tó sì ti ṣe ìgbéyàwó, tó sì bí àwọn ọmọ rẹ̀, ọmọ méjì sí.
Ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn ni Shaffy Bello kúrò ní Amẹ́ríkà láti gbájúmọ́ iṣẹ́ rẹ̀.
Òun àti ọkọ rẹ̀ ti kọ ara wọn sílẹ̀ ní ọdún márùn-ún sẹ́yìn báyìí, tó sì ní òun àti ọkọ òun ń gbájúmọ́ títọ́ àwọn ọmọ wọn.
Ẹni àádọ́ta ọdún ni Shaffy Bello báyìí.


























