Ọkọ̀ ojú irin méjì forí sọ̀ ara wọn, wọn yà kúrò lójú òpó rélùwéè, ọ̀pọ̀ èrò farapa

Oríṣun àwòrán, @aonanuga1956
Pupọ ninu awọn ero to wa ninu ọkọ oju irin kan to gbera lati Abuja to n lọ si Kaduna lowurọ ọjọ Aje, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹta ọdun 2026 yii ni wọn farapa, nigba ti ọkọ to gbe wọn naa ya kuro loju opo rẹ.
Ohun ti a gbọ ni pe ọkọ naa fori sọ ikeji to n bọ lati ẹnu ọna iloro kan ni.
Adari ileeṣẹ ọkọ reluwee lorilẹede yii, Kayode Opeifa, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun ẹka iroyin Daily Post lọjọ Aje naa.
Opeifa ṣalaye pe ọkọ oju irin naa koju ijamba nibi kan ti a mọ si Asham, ni Kaduna, ni wahala fi ṣẹlẹ ti ọpọ ero si fara ṣeṣe.
Lasiko ti a n kọ iroyin yii, ẹnikan kan ko kú ninu awọn to farapa naa, gẹgẹ bii Opeifa ṣe ṣalaye.
Amọ ṣa, awọn to farapa ni won ti gbe pada si teṣan ọkọ oju irin Idu, lati le gba itọju .
"Mo le fidi ẹ mulẹ pe ọkọ oju irin Abuja si Kaduna koju ijamba ni Asham. Awọn ero farapa, nigba ti iwadii n lọ lọwọ lati mọ ohun pato to fa ijamba naa."
Bẹẹ ni Adari ileeṣẹ ọlọkọ oju irin Naijiria naa ṣalaye.
"A gbọ ariwo nla ki ijamba naa too ṣẹlẹ"
Gẹgẹ bi awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣe wi, wọn ni ariwo nla kan lo kọkọ sọ, lẹyin eyi ni ọkọ sọ awọn ero soke lojiji, nigba naa si ni idaamu ba awọn ero ọkọ yii.
Wọn ni ọkọ naa forisọ omiran to n bọ lati ibi iloro kan ni ijamba ọhun fi ṣẹlẹ.
Eyi lo mu ki awọn awakọ daṣẹ duro lati yanju wahala naa .
Ẹ o ranti pe eyi kọ ni igba akọkọ ti ọkọ oju irin yoo fi ọna rẹ silẹ bi eyi ni Naijiria.
Atẹjade ti yoo ṣalaye ohun to ṣẹlẹ ni kikun yoo jade lati ileeṣẹ NRC gẹgẹ bi Agbẹnusọ wọn, Callistus Unyimadu, ṣe fidi ẹ mulẹ.

























