Wo àwọn olórí Nàíjíríà mẹ́rin tó ti rìnrìnàjò ẹnu iṣẹ́ lọ sílẹ̀ UK ṣaájú Tinubu

Oloogbe Tafawa Balewa lo wa loke lapa osi, Oloogbe Shehu Usman Shagari lo wa nisalẹ lapa osi, nigba ti Ajagunfẹyinti Yakubu Gowon wa lapa ọtun ninu aṣọ ologun ilẹ wa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Oloogbe Tafawa Balewa lo wa loke lapa osi, Oloogbe Shehu Usman Shagari lo wa nisalẹ lapa osi, nigba ti Ajagunfẹyinti Yakubu Gowon wa lapa ọtun ninu aṣọ ologun.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 10

Ajọṣepọ ko ṣẹṣẹ bẹrẹ laaarin orilẹede Naijiria ati ilẹ Gẹẹsi ti a mọ si United Kingdom (UK).

Yatọ si pe awọn oyinbo Gẹẹsi yii lo fun Naijiria lominira ni 1960, ọjọ ajọṣepọ awon ilu mejeeji naa ti pẹ gidi lẹka ọtọọtọ.

Ọjọ kẹtadinlogun oṣu Kẹta ọdun 2026 yii ni Aarẹ Bola Tinubu ati iyawo rẹ; Sẹnetọ Oluremi, yoo balẹ gudẹ si UK, gẹgẹ bi awọn alaṣẹ ilẹ naa ṣe pe wọn lati ba wọn lalejo.

Amọ ṣaaju abẹwo Tinubu yii ni awọn olori Naijiria mẹrin ti ṣe abẹwo oriṣi kan naa, bo tilẹ jẹ pe aafin Buckingham ni wọn gba alejo awọn aarẹ mẹrin akọkọ naa si.

Ti Tinubu nikan si jẹ aarẹ akọkọ ti wọn yoo bu ọla fun ni Windsor Castle.

Wọnyi ni awọn olori Naijiria ti UK ti gba lalejo ri.

Tafawa Balewa

Tafawa Balewa, Olootu ijọba Naijiria tẹlẹ. O we lawani le ori agbada funfun to wọ, o n rẹrin-in bo ṣe duro lẹgbẹẹ ọkọ rẹ, o si nawọ siwaju. Awọn obinrin oyinbo kan han lẹyin rẹ ninu fọto yii.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Tafawa Balewa, Olootu ijọba Naijiria tẹlẹ

Olootu ijọba ti a mọ si Prime Minister ni Tafawa Balewa nigba ti ilẹ Gẹẹsi gba a lalejo lọjọ kẹrinla, oṣu Kejila ọdun 1965.

Tafawa Balewa ni olori Naijiria akọkọ ti Ọbabinrin Elizabeth II gba lalejo to si fi han pe ipo aṣiwaju ni Naijiria wa ninu awọn ilẹ Africa yoku.

Lasiko ti UK gba Balewa lalejo yii, ko ti i ju ọdun marun-un lọ ti Naijiria gba ominira lọwọ ijọba Gẹẹsi, ṣugbọn ilọsiwaju ati iyi to wa fun orilẹede yii kun awọn oyinbo naa loju jọjọ.

Ajagunfẹyinti Yakubu Gowon:

Yakubu Gowon

Oríṣun àwòrán, Gowon

Ọdun mẹjọ lẹyin ti UK gba Tafawa Balewa lalejo pataki ni Ọbabinrin Elizabeth II tun gba Ọgagun agba Yakubu Gowon, to jẹ olori orilẹede Naijiria nigba naa lalejo.

Ọjọ kejila, oṣu Kẹfa ọdun 1973 ni eyi jẹ. O si ṣafihan ajọṣepọ onitẹsiwaju laarin Naijiria ati UK.

Oloogbe Shehu Usman Shagari:

Oloogbe Shehu Usman Shagari, Aarẹ Naijiria lati 1979 de 1983.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Oloogbe Shehu Usman Shagari

Aarẹ adiboyan nilana ijọba awaarawa, Oloogbe Shehu Usman Shagari ni aarẹ kẹta ti wọn ki kaabọ silẹ United Kingdom lọjọ kẹtadinlogun oṣu Kẹta si ogunjọ oṣu Kẹta ọdun 1981.

Abẹwo Shagari naa kun fun iyi ati ẹyẹ fun orilẹede Naijiria, o si fi han pe ifẹ wa laarin ilẹ yii ati ilẹ Gẹẹsi.

Ajagunfẹyinti Ibrahim Babangida:

Ajagunfẹyinti Ibrahim Babangida, olori Naijiria kẹrin ti UK gba lalejo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ajagunfẹyinti Ibrahim Babangida
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nigba ti aarẹ Naijiria ẹlẹẹkẹrin to ṣabẹwo si UK yoo fi ṣe tiẹ, saa ijọba ologun lo ba de, eyi naa si ni iṣakoso Ajagunfẹyinti Ibrahim Babangida.

Ọbabinrin Elizabeth II lo gba Ọgagun Ibrahim Babangida ati iyawo rẹ to ti di oloogbe bayii, Mariam Babangida, lalejo.

Ọdun 1989 ni nigba naa, wọn pari abẹwo naa lọjọ kejila, oṣu Karun-un ọdun 1989.

Ni bayii to kan Aarẹ Bola Tinubu, oun ni yoo jẹ aarẹ karun-un ti UK gba lalejo ni ti idalọla to ga julọ.

Aafin ilẹ Gẹẹsi funra wọn lo kede pe awọn fẹ gbalejo aarẹ, ọjọ kẹwaa, oṣu Keji ọdun 2026 yii ni wọn si kọkọ kede naa.

Ọdun kẹtadinlogoji sẹyin ni UK gbalejo aarẹ Naijiria gbẹyin, o si tọ lati mọ pe ilẹ Naijiria yii nikan ni ilẹ Africa ti UK ti gba alejo aarẹ wọn fun igba marun-un bayii.

Ko si iru rẹ ninu itan ilẹ Africa mi-in nibikibi.

Wọn gba alejo aarẹ South Africa nigba mẹta ri, awọn orilẹeede bii Egypt, Ghana, Zimbabwe, Senegal, Morocco, Malawi, Liberia, Zambia ati Tanzania ni tiwọn ko ti i ju ẹẹkan ṣoṣo lọ.

Wo bí ètò àbẹ̀wò Tinubu sí UK yóò ṣe lọ àti kókó àǹfàní márùn-ún tí Náìjíríà yóò jẹ́ nínú àbẹ̀wò náà

Aarẹ Tinubu ati Ọba Charles ni Buckingham Palace

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ijọba ilẹ Gẹẹsi ti kede pe oun yoo gbe awọn opopona kan ati oju ofurufu tipa lagbegbe Windson ṣaaju abẹwo Aarẹ Naijiria, Bola Tinubu, sibẹ ninu ọsẹ yii.

Tinubu ati iyawo rẹ, Oluremi ni wọn yoo jọ balẹ silẹ Gẹẹsi lọjọru, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 2026 ti a wa yii, nibi ti Ọba ilẹ naa, Charles Kẹta yoo ti gbalejo wọn ni Windsor Castle.

Ni ipalẹmọ abẹwo naa, ileeṣẹ ọlọpaa Thames Balley sọ ninu atẹjade kan pe awọn n ṣiṣẹ ni ifọwọsowọpọ pẹlu Royal Borough ti Windsor ati Maidenhead, to fi mọ idilẹ ori ade ọhun.

Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, wọn yoo ti oju ofurufu pa ni Windsor Castle laarin aago meje aarọ si aago mejila oru naa, lọna ati daabo bo awọn alejo pataki naa.

Ọga ọlọpaa, Adrian Hall ni akojọpọ awọn agbofinro ilẹ Gẹẹsi ni yoo jọ ṣiṣẹ papọ lati daabo bo gbogbo awọn ti yoo wa nibẹ.

Abẹwo naa ni akọkọ iru rẹ lati ọdun mẹtadinlọgọta sẹyin.

Bi alakalẹ abẹwo naa yoo ṣe lọ

Ijọba ilẹ Gẹẹsi ti kede alakalẹ bi ayẹwo Aarẹ Tinubu silẹ naa yoo ṣe lọ laarin ọjọ kẹtadinlogun si ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 2026 yii.

Oniruru ayẹyẹ ati ipade pẹlu awọn ọmọ Naijiria to wa nilẹ Gẹẹsi ni yoo waye lasiko abẹwo naa.

Ọmọba Prince William ati Catherine, to jẹ ọmọbabinrin Wales ni yoo ki Tinubu kaabọ si UK.

Lẹyin naa ni wọn yoo ṣe ẹyẹ ẹkaabọ silẹ wa fun Tinubu loju ọna Datchet, nibi ti wọn yoo ti kọ orin orilẹede mejeji, ti awọn ologun yoo si yan fanda nibẹ.

Wọn yoo yinbọn soke nigba mọkanlelogun ki wọn to lọ jẹun ni gbagede St George to wa ni Windsor Castle.

Lẹyin naa ni Tinubu yoo ṣe ipade pẹlu awọn agbagba ilẹ Gẹẹsi.

Ohun ti ipade naa yoo da le lori ni ibaṣepọ laarin orilẹede mejeji nipa eto ọrọ aje, eto aabo, irinajo ati idagboske.

Ọjọ naa yoo pari pẹlu eto aṣa nibi ti wọn yoo ti ṣafihan awọn ohun iṣẹnbaye Naijria ki wọn to tun lọ jẹun ni Windsor Castle.

Lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹta ni Aarẹ yoo bẹrẹ ọjọ rẹ pẹlu ounjẹ aarọ pẹlu Ọba Charles Kẹta ati Ayaba Camilla ko to rinrinajo lọ siluu London.

Ni London ni yoo ti lọ ṣayẹsi awọn ologun to ti ṣubu loju ija nibi isinku awọn ologun to wa ni Westminster.

Tinubu yoo tun ṣe ipade pẹlu olootu ijọba UK, Keir Starmer ni ojule kẹwaa, adugbọ Downing.

Ipade naa yoo da le bi ibaṣepọ aarin orilẹede mejeji yoo ṣe gbooro siwaju si.

Tinubu yoo ṣe ipade miran pẹlu awọn ọmọ Naijiria ni UK, yoo tun tọwọ bọwe adehun pẹlu ilẹ Gẹẹsi ni aafin Buckingham.

Lẹyin abẹwo naa ni Tinubu yoo pada si Naijiria lati papakọ ofurufu RAF Northolt.

Awọn to fẹ gbogun ti Tinubu ni UK

Ẹwẹ, ijọba apapọ ti ke gbajare pe awọn kan wa ti wọn fẹ gbogun ti Aarẹ Tinubu ninu irinajo rẹ ọhun.

Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ to n ri si idagbasoke ohun alumọlẹ fi lede, wọn ni ileeṣẹ Jupiter Ltd lo fẹ ba orukọ Aarẹ jẹ.

Ijọba ni ileeṣẹ naa fẹ gbe igbesẹ lati maa kọ iroyin ibanilorukọjẹ nipa ẹka iwakusa Naijiria lọna ati tabuku Naijiria nilẹ okeere.

Olubadamọran pataki si Aarẹ Tinubu lori ohun alumọni, Segun Tomori, sọ pe irọ ni iroyin to ni ijọba Naijiria gbẹsẹ le awọn eroja litiọmu kan to jẹ ti ijọba ilẹ Gẹẹsi.

Tomori ni Naijiria ko ni ajọṣepọ kankan pẹlu ileeṣẹ Jupiter Lithium, ati pe ofin Naijiria ko faye gba ki ileeṣẹ ilẹ okere laṣẹ lori ohun alumọni inu ilẹ ni Naijiria.

Anfani ti abẹwo Tinubu si UK yoo ṣe fun ọmọ Naijiria

Ni igba kẹyin ti adari Naijiria ṣabẹwo silẹ Gẹẹsi, wọn ko ti bi ida 70% awọn ọmọ Naijiria lonii nigba naa.

Iyẹn ni igba ti Aarẹ ologun Ibrahim Babangida ṣabẹwo si UK ti Ọbabinrin Elizabeth keji ati ọmọba Philip gbalejo rẹ lọdun 1989.

Ọdun mẹtadinlogun lẹyin rẹ bayii ni Aarẹ Bola Tinubu bẹ UK wo ti Ọba Charles ati iyawo rẹ, Camilla yoo gbalejo rẹ nile nla Windsor Castle.

Iwọyin ni awọn anfani ti abẹswo Tinubu si UK yoo ṣe fun Naijiria atawọn ọmọ Naiiria lapapọ.

1. Ibaṣepọ to dan mọran laarin orilẹede mejeji

Ibaṣẹpọ Naijiia ati ilẹ Gẹẹsi ti wa tipẹtipẹ lẹyin ti opin de ba ijọba amunisin lọdun 1960.

Bo tilẹ jẹ pe abẹwo Tinubu yii ko ni nnkankan lati ṣe pẹlu ohun to ti waye sẹyin laarin orilẹede mejeji, o ni ohun pupọ lati ṣe pẹlu ohun ti yoo ṣẹlẹ ọjọ iwaju wọn.

2. Ọrọ aje

O ti pẹ ti Tinubu ti maa n sọ pe Naijiria ti ṣetan lati gbalejo awọn to ba nifẹ si ati ṣowo ni Naijiria, igbagbọ si wa pe eyii wa lara ohun ti wọn yoo jiroro ninu abẹwo yii.

Naijiria ni orilẹede keji to n ba UK dowopọ julọ nilẹ Afrika ti owo to si n gba aarin wọn kọja le ni biliọnu mẹjọ pọun lọdun.

Igbagbọ wa pe ibaṣepọ yii yoo pese ọpọ iṣẹ fun awọn ọmọ Naijiria.

3. Ibaṣepọ pẹlu awọn ọmọ Naijiria nilẹ okeere

iroyin ni idaji miliọnu kan ọmọ Naijiria lo n gbe nilẹ Gẹẹsi, eyii to n ṣe anfani nla fun ọrọ aje Naijiria bi awọn eeyan naa ṣe n fi owo ranṣẹ sile.

Yatọ si eyii, ọpọ awọn ọmọ Naijiria lo n lọ si UK lati lọ kẹkọọ eyii to tun n ṣanfani nla fun ọrọ aje ilẹ naa.

Ibaṣepọ to dan mọran laarin ijọba Naijiria atawọn ọmọ Naijiria ni UK yoo jẹ anfan nla fun orilẹede mejeji.

4. Oniruru ipade mii ti yoo waye

A gbọ pe oniruru ipade ni yoo waye lasiko abẹ Aarẹ Tinubu naa, paapaa, pẹlu olootu ijọba Keir Starmer, ni ojule kẹwaa, adugbo Downing.

Tinubu yoo tun kopa ninu ipade kan to ni ṣe pẹlu ọrọ aje nibẹ.

Asiko abẹwo ọhun ni Tinubu yoo lanfani lati kede awọn eto to ni fun ilọsiwaju ọrọ aje Naijiria faraye.

5. Ọrọ eto aabo

Lara iṣoro gboogi to n koju Naijiria lonii ni eto aabo to mẹhẹ.

Lara nnkan to si jẹ ijọba ilẹ Gẹẹsi logun nipa Naijiria ni bi eto abo rẹ yoo ṣe gberu si.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ninu oṣu Keje ọdun to kọja ni ijọba Naijiria ati ilẹ Gẹẹsi ṣe ipade ti wọn pe ni Security and Defence Partnership Dialogue nilu London.

Ireti wa pe ọrọ aabo Naijiria yoo lewaju lara awọn ọrọ ti ijọba Naijiria yoo ba ijọba ilẹ Gẹẹsi sọ ati bi wọn ṣe le ran Naijiria lọwọ lori eto aabo lasiko abẹwo Tinubu si UK.