Ìlú kan rèé lábẹ́ ìjọba Ogun àmọ́ ilẹ̀ Benin ni wọn ti ń bímọ, pọn omi, ta ọjà pẹ̀lú ìnira ńlá
Yoruba ni ibi ti a ba gbe la n se amọ eyi ko ri bẹẹ fun awọn eeyan to n gbe nilu Ìgbọ́kọ́fì to wa lori aala ilẹ laarin orilẹede Naijiria nipinlẹ Ogun ati ilẹ olominira Benin.
Idi ni pe awọn eeyan ilu naa ko ri anfaani kankan jẹ lara ijọba orilẹede Naijiria, to si jẹ pe orilẹede olominira Benin ni wọn n lọ lati ni igbayegbadun to peye.
Koda, aye le fawọn eeyan ilu naa debi pe inira lo jẹ fun wọn tori aisi omi to se mu, oju ọna to ye kooro atawọn ohun eelo amayedẹrun miran to nu wọn.
Bi wọn ba si fẹ pọn omi to se mu, o di dandan ki wọn fẹsẹ tẹ ilẹ Benin, ki wọn to ri omi to dara.
Idi ree ti BBC News Yoruba se morile ilu naa lati mọ ọpọ ipenija to n koju wọn atawọn ohun ti wọn fẹ kijọba Naijiria ti wọn wa labẹ rẹ se lati mu ki aye tubọ dẹrun fun wọn.

"Ẹlomiran n rinrinajo ti ẹsẹ rẹ yoo ge, nibi to ti subu"
Nigba ti awọn eeyan ilu Ìgbọ́kọ́fì naa n ba BBC News Yoruba sọrọ, Adele Baalẹ Igbọkọfi, Oloye Bamgbose Alani sọrọ, ilẹ kun.
Bamgbose ni orilẹede Benin ni awọn maa n lọ tawọn ba fẹ mu omi tori ọhun ni omi wọn ti dara.
"Ajọ to n ri si ọrọ ibode nibẹ se awọn omi kan, sugbọn gbogbo rẹ ti bajẹ.
Koda, ọna ti ẹ gba debi, ti ojo ba fi rọ, ẹsẹ gan ko le gba a.
Bi Ọkada ba kuro nibi ni aago mẹsan aarọ, aago marun irọlẹ ni yoo de Ijoun.
Ẹlomiran n rinrinajo naa ti ẹsẹ rẹ yoo ge, nibi to ti subu, awa araalu si la se pako, ti a fi n gba ori odo kan, ti wọn n pe ni Iwoyi."
"Awọn ọlọpaa ilẹ Benin yoo wa silu yii lati wa mu eeyan lọ si agọ ọlọpaa lọdọ wọn, ti wọn yoo si tii mọle"
Oloye Bamgbose tun salaye pe aisi ina ọba nilu naa, isoro nla ni tori ọpọ awọn ọmọ wọn to kọ isẹ, ni ko ri isẹ se tori aisi ina ọba, ti wọn si di Ọlọkada.
"Nigba miran, awọn ọlọpaa ilẹ Benin yoo wa silu yii lati wa mu eeyan lọ si agọ ọlọpaa lọdọ wọn, ti wọn yoo si tii mọle.
Awọn Ọlọpaa to jẹ ti Naijiria to wa nibi ko ni ibọn amọ awọn ọlọpaa Benini ni ibọn.
Agọ ọlọpa to wa nibi, wọn kan fi di gẹrẹu ni, koda, isẹlẹ kan sẹlẹ, tawọn ọlọpaa ibẹ gba ori ogiri sa lọ"
Awọn olugbe ilu Igbokofin ni lootọ lawọn n dibo fawọn alasẹ tuntun ni ọdun mẹrin mẹrin, ti wọn si n rọ ijọba ipinlẹ Ogun lati dide iranwọ fun awọn.
"Ile iwosan ijọba wa nilu yii tẹlẹ amọ o ti wo, ti a ba si fẹ bimọ, ilẹ Benin la ti n lọ bimọ, ọmọ tabi iya le ku"
Deborah Bamgbose tii se ọmọbibi ilu naa salaye pe ko si ile iwosan to yanranti nilu naa bi o tilẹ jẹ pe abẹ ijọba ipinlẹ Ogun ni orilẹede Naijiria ni wọn wa.
"Ile iwosan ijọba wa nilu wa tẹlẹ amọ o ti wo, ti a ba si fẹ bimọ, ilẹ Benin la ti n lọ bimọ.
Alaboyun miran ti le yọwọ ki wọn to de ilẹ Benin, ti wọn ba si de ọhun, o le jẹ pe ọmọ nikan ni wọn yoo gbe wa sile, ti iya yoo ti ku tabi ko jẹ nidakeji."
O wa fidi rẹ mulẹ pe inira tawọn eeyan ilu Igbọkọfi n koju ti pọ ju pẹlu afikun pe o le ni ọgbọn ọdun tawọn ti n lọ si ilẹ Benin lọ bimọ.
"Owo to yẹ ki wọn gba ni aabọ, wọn yoo sọ di ilọpo meji fun wa. Iya ọmọ le gbe Benin fun ọsẹ kan tabi meji ko to wale tori ko ri owo ti wọn ni ko san.
Wọn mọ lọhun pe ọmọ Naijiria ni wa, a kii se ọmọ orilẹede Benin, to ba si ko owo Naijiria lọn wọn yoo ni ko to owo tawọn.
"Ẹsẹ ni awa obinrin maa n rin lọ silu Ijoun, bo se jinna si wa to, lọpọ igba, pẹlu ọmọ lẹyin, a subu, ọja wa yoo si danu"
Yatọ si aisi oju ọna to dara ati ile iwosan, inira nla lo tun jẹ fawọn eeyan ilu Igbọkọfi lati ire oko ti wọn n pese.
Lootọ lo jẹ pe agbẹ ni ọpọ eeyan ilu naa, amọ ọja ti wọn n na, jinna silu naa, ti oju ọna ko si dara.
Deborah Bamgbose ni "Ti a ba ni ka lọ na ọja nilu Ijoun, o jinna si wa, bi ojo ba si pọ, inira lo maa n jẹ tori oju popo ti yoo kun fun omi.
Ẹsẹ ni awa obinrin maa n rin lọ silu Ijoun, bo se jinna si wa to, lọpọ igba pẹlu ọmọ lẹyin, a subu, ọja wa yoo si danu.
Nigba miran, ọja wa ko ni se ta mọ, ta ba gbe de ọja ni Ijoun, awọn ti yoo ra ọja naa si ti le lọ lọpọ igba.
Alaga ijọba ibilẹ Ariwa Yewa salaye awọn igbinyanju ijọba lati wa ojutu sawọn isoro to n bawọn eeyan ilu Igbọkọfi finra
BBC News Yoruba kan si alaga ijọba ibilẹ Ariwa Yewa, ti ilu Igbọkọfi wa labẹ rẹ, lati mọ ohun to fẹ se mu ki idẹrun bawọn eeyan ilu naa.
Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, alaga ijọba ibilẹ naa, Olusola Akinbode ni awọn ti bẹrẹ si kọ ibudo ilera alabọde fun wọn lọwọ lọwọ bayii nilu Igbọkọfin.
O ni kii se pe ko si omi mimu ni Igbọkọfi, amọ omi ti ajọ to ba fun akoso aala ilẹ laarin orilẹede miran se omi fun wọn.
Amọ o fikun pe aise itọju omi naa lo mu ko tete bajẹ.
"Ile eto ilera ta n kọ, omi wa nibẹ. A si tun ti n la ọna lati igberiko kan si omi pẹlu ẹrọ katakata ti a sẹsẹ tun se."






