Wo bí Naijiria, Egypt ṣe ń pàdánù lẹ́ka epo nítorí ogun Iran, tí nǹkan sì ń ṣe ẹnu ire fún South Africa

Ọkunrin oṣiṣẹ ile epo kan n ta epo sinu ọkada nile epo kan niluu Abuja, o wọ aṣo alawọ aro ati awọ eweko.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ilẹ Africa n koju inira to n waye latari owo epo to n gunke si i, gbigbe epo naa kọja sílẹ̀ yìí kò dẹrun, ilẹ Africa n daamu lọwọ iyọnu to ju agbara rẹ lọ.
    • Author, Marco Oriunto
    • Reporting from, London
    • Author, Makuochi Okafor
    • Reporting from, Lagos
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Bi ogun Iran ṣe n tẹsiwaju, gbogbo orilẹede ilẹ Africa pata lo n mọ ọn lara.

O ṣee ṣe kawọn kan ninu wọn maa padanu bi owo epo naa ṣe n wọ́n si i ki wọn si ti ọna ti wọn n gbe e gba pa, amọ awọn kan ninu wọn le di ẹni to n jèrè lawọn oju ọna okoowo tuntun.

Naijiria : Ilẹ̀ to n ṣàn fun epo ṣugbọn ti nnkan ko ṣe ẹnu ire fun

Orilẹede Naijiria lo wa nipo keji ninu awọn ilu to n pese epo, ti a ba ti yọwọ Libya to wa nipo kin-in-ni. Bi owo epo rọbi ṣe n lọ soke yii, awọn alaṣẹ Naijiria n sọ pe awọn le pese epo si i ti yoo si to ohun ti gbogbo agbaye n fẹ.

Ṣugbọn bi ijọba Naijiria tilẹ ṣe eyi, awọn eeyan ti ko ni nnkan kan le maa ri anfaani rẹ jẹ latari ai si ibudo ifọpo to n ṣiṣẹ lorilẹede naa.

Naijiria maa n gbe pupọ ninu epo rẹ lọ si ilẹ okeere ni, nibi ti wọn yoo ti sọ ọ di dísù, bẹntiroolu ati awọn epo miran.

Awọn epo naa ni wọn yoo wa da pada si Naijiria niye to jẹ lọja agbaye. Nitori ọpọ ọkọ epo to ha si Iran bayii latari oju ọna Strait of Hormuz ti wọn ti pa, iye ti wọn n ta epo ni Naijiria naa ti lewo si i, o si n din èrè tawọn to n ta epo n jẹ ku.

"Bi owo epo lagbaaye ba gunke si i, owo ọkọ̀ maa n wọn si i kaakiri ni."

Onimọ agba nipa ọrọ aje, Dumebi Oluwole to jẹ oniṣowo epo lati ilu Eko lo ṣalaye bẹẹ.

"Owo epo ti fẹre le ni ida meji, bi ko ba jẹ ida mẹta gan-an bayii. Igba ti mo ba ri i pe o ṣe pataki fun mi lati ṣiṣẹ ni mo n dawọle e bayii, ki n le ṣọ iye ti mo maa na."

Morounmubo Akodu, oniṣowo kereje kan niluu Eko lo sọ bẹẹ.

Oniṣowo Morounmubo Akodu lati ilu Eko, o wọ aṣọ alawọ dudu ati pupa rẹsurẹsu, o ṣe irun rẹ ni wininkin, bẹẹ lo n woju kamẹra bo ṣe jokoo to kọyin si awọn eweko.
Àkọlé àwòrán, Niluu Eko, awọn olokoowo bii Morounmubo Akodu, ṣalaye pe niṣe lawọn n faramọ ẹkunwo to n ba owo epo naa, tawọn n din èrè awọn ku kawọn ma baa fowo le ọja fun awọn onibaara .

Yatọ si epo to gbe owo leri, ounjẹ naa ṣee ṣe ko wọ́n si i, bẹẹ si ni ọwọngogo ọja karikari naa le ṣẹlẹ, ti yoo si mu igbesi aye nira.

Bi ijọba ba si ṣe n pawo wọle si i nibi epo ti wọn fi n ranṣẹ soke okun, ọpọ ọmọ Naijiria ni yoo maa koju inira ti eeyan le fi oju inu wo ṣaaju ọjọ iwaju yii.

Egypt: Idaamu ba oju ọna Suez

Pẹlu bi awọn ọna ti wọn n gbe epo gba ṣe n koju iṣoro, orilẹede Egypt naa ti n padanu owo to n wọle fun un latari ogun to n lọ lọwọ yii.

Oju ọna ti epo n gba ti a mọ si Suez Canal lorilẹede Egypt jẹ ọkan gboogi fun awọn ọkọ oju omi to n gbe epo atawọn ọja miran laaarin awọn agbegbe Gulf ati Europe.

Latigba ti inunibini yii ti bẹrẹ, awọn ileeṣẹ nla nla to n gbe epo kọja ti wa ọna miran ti wọn yoo maa gba, yatọ si Hormuz Strait ati Okun Pupa, nitori ki wọn ma baa lugbadi ado oloro.

Eyi ti din bi wọn ṣe n gbe epo gba ọna Suez ku jọjọ, o si tun din owo to n wọle ku, ohun to si n fa a ti gbigbe epo wọle lati ilẹ okeere ṣe n wọ́n si i niyẹn, ti owo epo si n gunke si i lọdọ wa.

"Owo Pọ́n-un ti Egypt n lo ti padanu ni ida meje, eyi ri bẹẹ nitori oju opo Suez to jẹ ọna ti wọn n gbe epo pupọ ati awọn ọja miran gba ti wa ni titi pa."

Dumebi Oluwole, onimọ nipa ọrọ aje lo ṣalaye bẹẹ.

South Africa: Ọna okoowo tuntun ṣi silẹ fawọn

Ohun to n pa ẹnikan lẹkun le jẹ orisunn ayọ fun ẹlomi-in.

Bi ọrọ epo yii ṣe n lọ ni Iwọ-Oorun Africa ti ko tura yii, bẹẹ kọ lo ri ni Guusu Africa ti i ṣe South Africa. Koda, ọna ọla ati okoowo tuntun lo ṣi silẹ fun wọn.

Maersk ati Hapag-Lloyd ti wọn wa lara awọn ileeṣẹ agbepo nla lagbaaye, kede ninu oṣu Kẹta pe awọn yoo gbe awọn to ṣe gboogi ninu iṣẹ awọn lati Middle East gba ọna South Africa, loju ọna wọn ti i ṣe Cape of Good Hope.

Bi awọn tanka agbépo ṣe n yago fun oju ọna Strait of Hormuz ati Okun pupa bayii, ọpọ ọkọ epo lo n gba awọn ọna ẹkùn South Africa, eyi to n pese iṣẹ fun awọn oṣiṣẹ ọlọkọ lebute ibẹ, paapaa julọ ni South Africa gangan.

Ibudo agbépo kan pẹlu awọn kontẹna meji ti wọn kọ Maersk si lara, oju opo reluwee kan wa lẹgbẹẹ, igi ọpẹ kan naa wa nibẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Lara awọn ileeṣẹ agbepo nla lagbaaye ti kede pe awọn yoo gbe awọn to ṣe gboogi ninu iṣẹ awọn lati Middle East gba ọna South Africa, loju ọna wọn ti i ṣe Cape of Good Hope.
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Ọna tuntun to gùn ti awọn ọlọkọ n gba yii yoo mu iṣẹ pọ fun ọpọ awọn ebute ọkọ ni Guusu Africa– Walvis Bay, Cape Town, Durban, Maputo, Dar es Salaam."

Timothy Walker, Oluwadii agba nile ẹkọ Institute for Security Studies lo ṣalaye bẹẹ.

Ni ibẹrẹ oṣu Kẹta, ẹka Cape Chamber of Commerce and Industry ni South Africa, ri afikun ọkọ epo ni ida 112%, ti wọn duro ni ebute Cape Town.

"Bo tilẹ jẹ pe ọrọ aje le ṣe daadaa lẹka ipese epo, atunṣe awọn ọkọ oju omi ati ipese awọn ohun ti ọkọ̀ oju omi nilo, sibẹ, adojukọ wa labala nnkan amayedẹrun."

Jacques Moolman, Aarẹ Cape Chamber of Commerce and Industry lo sọ bẹẹ.

Bakan naa, Transnet National Ports Authority (TNPA), ileeṣẹ ijọba to ni ibudokọ ọkọ oju omi mẹjọ to wa ni South Africa to si n boju to o, fidi ẹ mulẹ pe awọn yoo pese ọna tuntun mi-in ni Cape Town, awọn yoo si mojuto ẹka to n tun ọkọ̀ oju omi labẹle ṣe.

Ṣugbọn ṣaa, nnkan ko ti i fi gbogbo ara ṣe daadaa fun South Africa naa. Nitori bi orilẹede naa ṣe n gbe epo rẹpẹtẹ wọle, owo gọbọi ti wọn n ta epo lagbaaye ati ai tete ri i ja sibi to yẹ yoo ṣakoba fun awọn to nilo epo naa ati okoowo wọn, koda bi ẹka okoowo ori omi gbooro ju bẹẹ lọ.