Ìjọba àpapọ̀ wọ àwọn afurasí ọmogun tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé wọ́n fẹ́ dìtẹ̀ gbàjọba Tinubu lọ sílé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, Defence Headquarters/X
Ìjọba Nàìjíríà ti fi ẹ̀sùn mẹ́tàlá kan àwọn èèyàn tí wọ́n ní wọ́n ní wọ́n gbérò látio gba ìjọba lọ́wọ́ ààrẹ Bola Tinubu.
Ilé ẹjọ́ gíga ìlú Abuja ni wọ́n wọ́ àwọn afurasí náà lọ.
Lára àwọn afurasí náà ni ọ̀gágun Mohammed Gana, Erasmus victor, Ahmed Ibrahim, Zekeri Umoru, Bukar Goni àti Abubakar Sani.
Elòmíràn tí wọ́n tún fẹ̀sùn kàn àmọ́ tí wọ́n ní ó ti na pápá bora báyìí ni Mínísítà tẹ́lẹ̀ rí fún epo bẹntiróòlù, Timipre Sylva.
Ní ọjọ́ Ajé ni ọ́fíìsì agbẹjọ́rò àgbà Nàìjíríà wọ́ àwọn afurasí náà lọ sílé ẹjọ́ lórí àwọn ẹ̀sùn pé wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ìjọba, ìwà ìgbéṣùmọ̀mí àti ṣíṣe owó ìlú kúmọkúmọ tó nííṣe pẹ̀lú ṣíṣe àtìlẹyìn fáwọn agbéṣùmọ̀mí.
Nínú ẹ̀sùn tí olùpẹjọ́ fi kan àwọn afurasí náà ni pé wọ́n lẹ̀dí àpòpọ̀ láti gbógunti ìjọba lójúnà àti gba ìjọba lọ́wọ́ ààrẹ Nàìjíríà, ìwà tó ní ìjìyà lábẹ́ abala kẹtàdínlógójì òfin ìwà ọ̀daràn.
Ìjọba tún fẹ̀sùn kàn pé àwọn afurasí náà mọ̀ nípa èròńgbá ọ̀gágun Mohammed Alhassan Ma'aji àtàwọn míì láti fipá gbàjọba ṣùgbọ́n tí wọ́n kọ̀ láti fi tó àwọn aláṣẹ létí.
Bákan náà ni wọ́n tún fẹ̀sùn kàn pé àwọn afurasí náà kọ̀ láti gbé ìgbésẹ̀ kankan láti ṣe ìdádúró èròńgbà náà.
Yàtọ̀ sí ẹ̀sùn ìdìtẹ̀gbàjọba, àwọn olùjẹ́jọ́ tún ń kojú ẹ̀sùn ìwà ìgbéṣùmọ̀mí èyí tí ìjọba fẹ̀sùn kàn pé wọ́n lẹ̀dí àpòpọ̀ lé lórí.
Wọ́n ní Ahmed Ibrahim àti Zekeri Umoru kópa níbi àwọn ìpàdé tí wọ́n ti ń pète pèrò láti dojú ìjọba àwaarawa délẹ̀.
Wọ́n tún fẹ̀sùn kàn pé àwọn afurasí ń ṣe àtìlẹyìn fún ìgbéṣùmọ̀mí yálà lọ́nà tí wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ tàbí àìmọ̀ lójúnà àti jẹ́ kí wọ́n hùwà ibi náà.
Ìjọba fi kun pé àwọn afurasí ọ̀hún mọ̀ọ́mọ̀ pa àwọn ohun tí wọ́n mọ̀ mọ́ dípò kí wọ́n fi tó àwọn aláṣẹ létí.
Lára àwọn afurasí náà ni wọ́n fẹ̀sùn kàn pé wọ́n lọ́wọ́ nínú owó tí wọ́n tọpinpin sáwọn agbéṣùmọ̀mí.
Lẹ́yìn tí ìjọba kéde wíwọ́gilé ètò yíyan kiri ní àyájọ́ ọjọ́ òmìnira ní ọdún tó kọjá niàwọn èèyàn ǹ sọ pé ìgbésẹ̀ náà wáyé látàrí èròńgbà láti gba ìjọba mọ́ ààrẹ Tinubu lọ́wọ́.
Iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà jiyàn ẹ̀sùn náà àmọ́ tí wọ́n padà kéde ní oṣù Kìíní ọdún 2026 pé àwọn kan gbèrò láti gba ìjọba mọ́ ààrẹ Tinubu lọ́wọ́.
Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ológun, Samaila Uba sọ pé ìwádìí fi hàn pé àwọn ológun kan ló wà nídìí èròńgbà náà.
Uba ní ọwọ́ ti tẹ àwọn ológun náà àti pé wọ́n máa kojú ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ológun.
Ní où tó kọjá ni àwọn ẹbí àwọn ológun tó wà ní àhámọ́ pàrọwà sí ààrẹ láti jẹ́ kí àwọn èèyàn náà kojú ìgbẹ́jọ́ ní ilé ẹjọ́.
Omoyele Sowore wà lára àwọn tó ṣe ìwọ́de nígbà náà láti bèèrè fún pé kí ìjọba jẹ́ kí àwọn ẹbí àwọn ológun náà rí wọn bá sọ̀rọ̀.

























