Ìdí tí mi ò ṣe kí ń lo ọkọ mi ṣùgbọ́n tí mo máa ń lo ọmọ mi nínú fídíò àwàdà tí mò ń ṣe rèé - Kiekie

Oríṣun àwòrán, Kiekie/Instagram
Gbajugbaja adẹrinpoṣonu, Bukunmi Adeaga-Ilori, ti ọpọ mọ si Kiekie ti ṣalaye idi ti ki i fi lo ọkọ rẹ amọ to maa n lo ọmọdebinrin rẹ ninu fidio awada to maa n ṣe.
Kiekie fidi ọrọ yii mulẹ nigba to n sọrọ nibi eto kan ti wọn pe ni The Creative Blueprint 2.0.
Adẹrinpoṣonu naa sọ pe oun mọọmọ fi aala saarin iṣẹ toun n ṣe ati igbe aye toun n gbe ni.
''Mo ti fi aala saarin awọn nnkan ti mo maa n ṣe nile tawọn eeyan ko mọ nipa mi gẹgẹ bi Oluwabukunmi Adeaga-Ilori ati iṣẹ ti mo n ṣe.
Mo maa n ṣiṣẹ sọrọsọrọ lori tẹlifisan, mo tun maa n ṣakoso eto, oṣere ni mi, mo si tun maa n ṣe fidio lati pawọn eeyan lẹrin in.
Ọpọ igba ni mo maa n gbọ tawọn eeyan maa n sọ pe ki lo de ti mi kii fi lo ọkọ mi ninu fidio ti mo n ṣe.
Ọkọ mi kii ṣe ẹni to le pani lẹrin in, bawo ni mo ṣe fẹ lo o ninu fidio awada ti mo n ṣe?'' Kiekie lo sọ bẹẹ.
O ṣalaye pe oun maa n lo ọmọ oun Nola ninu fidio toun n ṣe tori o le ṣere daadaa niwaju ẹrọ kamẹra.
Kiekie fikun ọrọ rẹ pe Nola ọmọ oun gan an lo maa sọ pe kawọn ṣe fidio nigba mii.
Gbajugbaja adẹrinpoṣonu naa ni gbogbo agbara oun loun yoo lo lati ṣatilẹyin fun Nola lori bi o ti fẹran lati maa ya fidio awada.
Alawada obinrin naa ni eleyii ṣe pataki tori awọn obi oun naa gbaruku ti oun lori nnkan toun fẹran lati maa ṣe nigba toun n dagba.
Kiekie ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe lasiko isinmi lati ile ẹkọ nikan ni Nola maa n ṣe awọn fidio o maa n ṣe pẹlu oun.
O ni oun ko le jẹ ki fidio awada toun n ṣe ṣakoba fun ẹto ẹkọ ọmọ oun.
Kiekie wa lara awọn adẹrinpoṣonu ti ọpọ eeyan fẹran tori bi o ṣe maa n pani lẹrin-in ninu awọn fidio awada to maa n ṣe.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post


























