Ẹgbẹ́ ADC di àgùntàn tí kò ní Olùṣọ́, INEC yọ orúkọ Rauf Aregbesola, David Mark kúrò bíi adarí ẹgbẹ́, ariwo sọ

Oríṣun àwòrán, Collage

Oríṣun àwòrán, DavidM Mark/ Rauf Aregbesola /Facebook
Pẹlu bi wọn ṣe ni awọn tẹle aṣẹ ile ẹjọ Kotẹmilọrun, ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC, ti yọ orukọ awọn igbimọ amuṣẹṣe (National Working Committee) fun ẹgbẹ oṣelu ADC, labẹ idari alaga wọn; David Mark, kuro loju opo wọn.
Eyi tumọ si pe orukọ Rauf Aregbesola ti i ṣe Akọwe apapọ ẹgbẹ ati David Mark to jẹ alaga apapọ gan-an atawọn ọmọ ADC mi-in ko si loju opo INEC mọ, wọn ko da wọn mọ labẹ ofin.
Ajọ INEC tun tẹsiwaju pe oun ko ni I gba ohunkohun wọle latọdọ awọn eeyan yii mọ, bẹẹ ni oun ko ni I da si ipade yowu ti wọn ba n ṣe lorukọ ADC.
INEC sọ pe bẹẹ ni yoo wa titi digba ti ilẹ ẹjọ giga ilu Abuja ba da ẹjọ naa.
Gbogbo eyi jẹ jade ninu atẹjade kan ti Mohammed Haruna to n ri si ikede ati ilanilọye ni INEC fi sita l'Abuja l'Ọjọru ana.
O ni igbesẹ yii wa lati ma ṣe tako ohun ti ile ẹjọ n fẹ ko too di pe wọn yoo gbọ ẹjọ naa tan.
Wọn fi awọn lẹta ti wọn gba lati kootu gbe igbesẹ yii lẹsẹ, eyi to kilọ pe INEC gbọdọ yọ orukọ Aregbe, Mark, Nafiu Bala Gombe toun naa fẹ di Alaga apapọ ADC atawọn yoku wọn danu.
Wọn fi kun un pe awọn ti ọrọ kan ninu ẹgbẹ ni wọn kọwe ifisun.
Ki lo de ti INEC gbe igbesẹ yii?
"Niwọn igba ti orukọ awọn igbimọ amuṣẹṣe ti Seneto David Mark n dari ti wa loju opo wa lati ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹsan-an ọdun 2025 (Ọjọ keje lẹyin ipẹjọ) INEC yoo yọ orukọ wọn kuro loju opo wa bi aṣẹ ile ẹjọ Kotẹmilọrun, lati tẹle ohun ti kootu n fẹ titi igbẹjọ.
"Bẹẹ ni INEC ṣalaye ninu atẹjade naa.
Ajọ naa sọ pe oun yoo maa tẹsiwaju ninu otitọ.
O rọ ẹgbẹ ADC lati ma ṣe ohun ti yoo koba alakalẹ eto ti INEC gbe jade fun idibo ọdun 2027.
Alaye naa tẹsiwaju pe ile ẹjọ ko fi gbogbo ara gba David Mark bii Alaga apapọ ADC, eyi to si gbọdọ yanju ki ajọ eleto idibo to le gba a wọle.
Tẹ o ba gbagbe, ẹgbẹ ADC yii ni ibi isadi keji ti awọn oloṣelu ti ko fẹ darapọ mọ APC n sa si latigba ti rogbodiyan ti n ṣẹlẹ ninu PDP, ti ẹgbẹ Alaburada si ti pin si igun ọtọọtọ.
Ki ni ADC, PDP ati awọn eeyan Peter Obi wi?
Nigba ti won n fesi si igbesẹ INEC, Agbẹnusọ ADC; Bolaji Abdullahi ati Ini Ini Ememobong fun PDP, sọ pe INEC ṣe bẹẹ lati le sọ Naijiria di ilu ẹlẹgbẹ oṣelu kan ṣoṣo ni.
Wọn ni wọn ṣe bẹẹ lati koba ijọba awarawa ni, bakan naa ni wọn ni ijọba APC lo n da àrà yii.
O yẹ ki gbogbo awọn alatilẹyin ẹgbẹ alatako dide si ọrọ yii bi wọn ṣe sọ.
Bakan naa ni Alakooso apapọ fun Obidient Movement ti I ṣe awọn alatilẹyin Peter Obi, Yunusa Tanko, kilọ pe ipinnu to le da rogbodiyan silẹ ni INEC ṣe.
O ni ohun to le da wahala silẹ ni bi ajọ yii ba pinnu lati maa ṣe iru eyi.
Bolaji Abdullahi tẹsiwaju ni tiẹ pe ki i ṣe ile ejọ Kotẹmilọrun ni INEC tẹle, o ni awuruju ni awijare naa.
O ni David Mark to wa nipo alaga apapọ lo yẹ ki wọn fi silẹ si aaye rẹ.
Agbẹnusọ ADC naa sọ pe awọn ko ni I gbe etekete kankan wọle fun ajọ INEC.

























