Àwọn tó ń f'owó ran Boko Haram lọ́wọ́ jẹ́ ẹni táwọn aláṣẹ mọ́, wọn ò kàn dárúkọ wọn ni- Buratai

Oríṣun àwòrán, COAS
Olori ikọ ologun Naijiria tẹlẹ, Tukur Buratai, tí ni ẹnikẹni ko le di oun mu fun ẹsun pe wọn ko kede orukọ awọn eeyan to n ṣe agbatẹru tabi fi owo ran igbesunami lọwọ lorilẹede Naijiria.
O tẹnu mọ pe awọn eeyan jẹ mimọ, ti wọn si n gbe pẹlu wa lorilẹede Naijiria.
Buratai sọ eyi nigba ti wọn n gba a alejo ni ikanni Channels TV, Ọgagun naa ni awọn alaṣẹ mọ nipa awọn to n ṣe onigbọwọ awọn agbebọn sugbọn oun ko mọ idi ti wọn fi kuna lati kede orukọ wọn fun gbogbo ilu.
"O ko le sọ pe ki wọn bí mi nípa idi ti wọn ko fi kede orukọ awọn to n se onigbọwọ, fi owo ran ìkọlu lọwọ lorilẹede Naijiri.
"Ko kí n ṣe nipa dida orúkọ wọn nìkan; awọn ẹka yii mọ idi ti wọn ko fi kede orukọ awọn eeyan yii. ijọba ni lati gbe igbesẹ; awọn eeyan n gbe pẹlu wa lonii, ti awọn araalu si mọ wọn. Mo le gba awọn ebu lori awọn nnkan ti o jẹ ojuṣe ikọ ologun Naijiria.
Buratai tun fikun pe igbesẹ eto irapada fun ọmọ ogun Boko Haram lo jẹ ti ijọba apapọ, kí í ṣe ti ileeṣẹ ologun.
"Eto ti a ni fun wọn ní pe a fun wọn ní gbedeke ọdun 2016 lati ju wọ silẹ, ti wọn se eyi, a o fa wọn awọn agbofinro lọwọ," o fikun.
Bakan naa ni Buratai kọminu lori bii eto aabo ṣe mẹhẹ lọwọ yìí, to si rọ ijọba lati lo imọ igbalode koju isoro awọn agbebọn.
O tun kesi ìjọba lati gba ọpọlọpọ eeyan sidi iṣẹ ologun lati le ki eroja koju awọn agbebọn ati lati le daabo bo araalu.


























