Agbébọn tó kó òṣìṣẹ́ mẹ́ta lọ nílé ìwòsàn l'Ondo, ohun tí a mọ̀ rèé

Inu ibẹrubojo ni awọn olugbe Oke Ijebu, niluu Akure, ipinlẹ Ondo wa bayii pẹlu bi awọn agbebọn ṣe kọlu ile iwosan alabọọde to wa ni agbegbe naa ti wọn si ko awọn oṣiṣẹ ibẹ kan lọ.
Awọn agbebọn naa ya wọ ile iwosan ọhun ni deede aago meji oru ọjọ Abamẹta, ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Kẹta ọdun 2026 yii, wọn si ko awọn osisẹ ibẹ mẹta lọ.
Ẹni tó jẹ ọlọdẹ ile iwosan naa; Olawale Yaya Tella, sọ fun BBC YORUBA pe kete tawọn agbebọn naa de ile iwosan yii ni wọn bẹrẹ si i lu oun, ti wọn si ni koun lọ kan ilẹkun ibi ti awọn oṣiṣẹ wa, kawọn to wa ni inu ile le silẹkun naa.
O salaye pe bi wọn ṣe silẹkun naa fun wọn lati inu ile iwosan ni wọn tun bẹrẹ si i lu awọn eeyan naa, ti wọn si ko awọn oṣiṣẹ obinrin mẹta wọnu ọkọ ti wọn gbe wa, tí wọn gbe wọn lọ.
O salaye pe ọkọ Toyota Venza ni wọn gbe wa lati sọsẹ naa.
Ọlọdẹ naa sọ pe awọn mẹta ni agbebọn naa, ọkan ninu wọn gbe ibọn, awọn meji to ku si ko ada dani.
Bi wọn ṣe lu awọn eeyan ile iwosan naa lalubami ni wọn tun fọ gilaasi ọkọ ọkan lara wọn.
Kí ni ikọ Àmọtẹ́kùn Ondo sọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà?
Ikọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo ninu atejade rẹ lori iṣẹlẹ yii, salaye pe awọn doola ẹmi awọn marun-un lọwọ awọn ajinigbe naa, nijọba ibilẹ Guusu ilu Akure.
Oga agba ikọ Amọtẹkun Ondo, Akogun Adetunji Adeleye to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, salaye pe awọn osisẹ eleto ilera mẹta náà wa lara awọn marun-un ti wọn gba silẹ lọwọ awọn ajinigbe.
Adeleye sọ pe awọn meji to ku jẹ Baba ati ọmọ ti ki I ṣe oṣiṣẹ ile iwosan.
Ọga Amotekun naa sọ pe deede aago mẹrin aabọ idaji ni wọn tu awọn osisẹ ile iwọsan naa silẹ, ti awọn si gbe wọn lọ sile iwọsan Amotekun fun itọju.
Adeleye sọ pe awọn ti n tọpinpin awọn ajinigbe naa lati le fi panpẹ ọba mu wọn.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tako Àmọtẹ́kùn lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ninu atẹjade tiẹ sọ pe iṣẹlẹ to waye ni ile iwọsan naa ki i ṣe ijinigbe.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ondo; DSP Abayomi Jimoh, sọ pe awọn adigunjale lo sọsẹ ni ile iwosan naa, tako ohun ti Amọtẹkun sọ.
DSP Jimoh sọ pe deede aago meji oru ni awọn adigunjale naa ko ibọn 'Pump Action' ati ada wọ ile iwosan naa, ati pe wọn fo iganna wọle ni.
O salaye pe wọn ko awọn mẹta tí wọn wa lẹnu isẹ lọ, wọn si tun gba gbogbo ohun ini wọn, to fi mọ ẹrọ ilewọ ati ẹrọ POS.
Bakan naa ni DSP Jimoh sọ pe ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Venza dudu ni awọn to ṣiṣẹ naa gbe wa sile iwosan yii.
Ọkọ naa lo ni wọn fi gbe awọn mẹta naa lati Oke Ijebu lọ si agbegbe Olokuta, ni Ondo Road, Akure.
O salaye pe iwadi fi han pe awọn to sọsẹ naa pasẹ fun awọn ti wọn ko naa lati bọ aṣọ wọn, tí wọn si fi wọn silẹ si inu igbo naa.
O ni ọkan lara awọn oṣiṣẹ ibudo atunṣe Olokuta lo ri awọn obinrin naa ninu igbo ti wọn wa.
Ọkan lara awọn ti wọn jigbe salaye ohun ti oju rẹ ri
Ọkan lara awọn ti iṣẹlẹ naa kan; Kayode Omolabake, sọ pe ohun wa ni isẹ ale lasiko ti iṣẹlẹ naa waye.
Omolabake salaye pe to ba ti di asalẹ ni awọn maa n tilẹkun ọgba ile iwọsan naa, ti ọlọdẹ yoo si wa kan ilẹkun nígbàkigbà tí wọn ba ni alaisan to wa fun iwosan ni aṣalẹ tabi oru.
O salaye pe kete ti oun gbọ iro ilẹkun loru naa, ohun beere lati mọ boya alaisan ni wọn gbe wa.
O ni ọlọdẹ naa dake fun isẹju diẹ ko too sọ pe alaisan ni. Sugbọn iyalẹnu lo jẹ pe awọn eeyan to ko ibọn ati ada dani lo yọju ti wọn si lu oun ni alubami.
Omolabake ni ariwo toun n pa lo mu kawọn to ku mọ ohun to n sẹlẹ.
Awọn ẹlẹgiri naa gba ẹrọ ilewọ gbogbo awọn bo ṣe wi, wọn si gbe awọn lọ sinu ọkọ wọn.
Inu igbo kan lagbegbe Ondo Road ni Omolabake sọ pe wọn ko awọn lọ.
O fi kun un pe ninu igbo naa ni wọn ti paṣẹ pe kawọn bọ gbogbo aṣọ ara awọn kawọn si wa ni ihoho ọmọluabi. Lẹyin eyi lo ni wọn gba gbogbo owo to wa ninu asunwọn ikowosi nile ifowopamọ awọn.
Omolabake sọ pe lẹyin eyi ni wọn fi awọn silẹ tí wọn si gbe ọkọ wọn lati sa lọ.
Arabinrin naa sọ pe lẹyin ti awọn to sọsẹ naa fi awọn silẹ tan lawọn bẹrẹ si i rin titi tawọn fi de Olokuta, nibi ti wọn ti ba awọn pe Amotekun, tí Amotekun si ko awọn lọ sile iwosan.
O ni ede Yoruba ni awọn eeyan naa fi ba awọn sọrọ lasiko iṣẹlẹ naa, sugbọn wọn n sọ ede Igbo ti wọn ba ti n sọrọ asiri laarin ara wọn.
Ṣaa, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti sọ pe kawọn araalu fi ọkan balẹ, ki wọn si tete maa fi iṣẹlẹ ifura ti wọn ba ri lagbegbe wọn sun ileeṣẹ ọlọpaa kia.
























