Ecuador: Nàìjíríà yóò má a wọ Ecuador láì gba ìwé ìrìnà
Oríṣun àwòrán, Getty Images
Orilẹ-ede Naijiria ati Ecuador ti se adehun ti yoo fun awọn ọmọ orilẹ-ede Naijria ni anfani lati wọ orilẹede Ecuador lai gba iwe irinna.
Orilẹ-ede Ecuador wa ni ariwa-iwọ oorun South America, pẹlu Colombia ni apa ariwa nigba ti orilẹ-ede Peru si wa ni apa ila ati guusu orilẹ-ede naa.
Asoju ilẹ Ecuador si Naijiria, Arakunrin Deopoldo Rovayo, lo sọ eyi ni Abuja nigba ti o se abẹwọ si akọwe agba fun ile-isẹ okeere lorilẹ-ede Naijria, arakunrin Olukunle Bamgbose ni Ọfiisi rẹ.
Rovayo wi pe adehun naa yoo waye lati mu ibasepọ to gbooro wa laarin orilẹ-ede mejeeji, nitori yoo faye silẹ fun awọn ọmọ orilẹ-ede mejeeji lati wọle- jade lai si iwe irinna ti yoo da wọn duro.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Asoju orilẹ-ede Ecuador naa fikun pe, o le ni ẹgbẹrun kan ọmọ Naijiria to n gbe ni orilẹ-ede Ecuador, atipe iye wọn yoo ma a pọsi.
Ninu ọrọ tirẹ, Bamgbose fi da asoju ilẹ Ecuador loju wi pe Naijiria yoo sisẹ pọ pẹlu wọn lati mu adehun naa wa is imusẹ.
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìròyìn tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn jùlọ
Content is not available