Àwọn agbébọn kọlu àwọn to ń gbé òkú lọ itẹ́ ní Kwara, yìnbọn pa fijilanté méjì, jí ọ̀kadà àti ìbọn wọn lọ
Oríṣun àwòrán, Others
Egbinrin ọtẹ, bi a ṣe n pana ọkan ni omiran n ru. Kaka ko san lara ọmọ iya ajẹ awọn agbebọn ni ipinlẹ Kwara, niṣe ni wọn n fi gbogbo ọmọ bi obinrin.
Awọn agbebọn tun ti ṣoro bi agbọn ni ilu Oro-Ago, ijọba ibilẹ Ifelodun, ipinlẹ Kwara bi wọn ṣe ṣekọlu sawọn eeyan ni ọjọ Kẹrinlelogun, oṣu Kẹta ọdun 2026.
Lasiko tawọn fijilanté kan lọ ṣe aabo fun awọn to n gbe oku lati ilu Ilorin lọ si ilu Oke-Oyan ni ijọba ibilẹ Ifelodun fun eto isin idagbere la gbọ wi pe awọn agbebọn kọlu wọn, ti wọn si gbẹmi eeyan meji ninu wọn.
Eyi waye lẹyin ọjọ meji ti awọn agbebọn kọlu ijọ ECWA ni ilu Omugo ni agbegbe Oro-Ago kan naa, nibi ti wọn ti gbe iyawo pasitọ ati awọn ọmọ ijọ mẹjọ mii lọ.
Àwọn fijilanté dúró tán àmọ́ ìbọn wọn kò lágbára tó
Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, ọrẹ ọmọ oloku ni ilu Oke-Oyan to ni ki a fi orukọ bo ohun lasiri sọ pe iya ọrẹ oun lo ku si ilu Ilorin ti wọn si n gbe lọ si ilu Oke-Oyan fun isinku ki awọn agbebọn to dawọn lọna.
O ni nitori ipenija eto aabo to n waye ni agbegbe naa ni awọn ṣe ro o lati gba awọn fijilante lati tẹle wọn de ibi ti wọn ti fẹ lọ sinku ọhun ṣugbọn ti ọrọ yiwọ.
"Bi eto aabo ṣe ri ni agbegbe wa lasiko yii paapaa julọ laaarin Oro-Ago si Oke-Oyan la ṣe woye pe o yẹ ki a pese eto aabo fun awọn ti wọn n gbe oku naa bọ.
"Fun idi eyii, awọn fijilante ti n duro sọ wọn ni Oro-Agọ, igba ti wọn de bẹẹ ni wọn n sọ wọn bọ wa si Oke-Oyan.
"A fi bii pe a ti mọ tẹlẹ, aarin ọna ni wọn ti ya bo wọn ti awọn igun mejeeji si wọ yaaja."
O ni awọn ko mọ pe awọn agbebọn naa ti faramọ sinu igbo, ti wọn n ṣọ ẹni yoo kọja ti wọn maa ṣe ikọlu si.
"Bi wọn ṣe kọja ni awọn agbebọn naa bẹrẹ si n yin ibọn, sugbọn awọn fijilante naa duro tan, awọn naa n daa pada.
"Ibọn awọn fijilante o lagbara bi eyi ti awọn agbebọn gbe lọwọ, eyi lo faa ti fijilante meji fi subu loju ija.
"Ibọn o wọle si awọn fijilante iyoku lara, awọn agbebọn gbiyanju lati gbe wọn, sugbọn wọn o gba fun wọn.
"Igba ti ija naa le, awọn agbebọn naa gbe awọn ọkada ati ibọn awọn fijilante meji ti wọn ku yii, wọn si wọ inu igbo lọ."
Tètè san N10m owó ìtúsílẹ̀ bàbà a rẹ tí o ò bá fẹ́ ká pa á bí àwọn fijilanté méjì yìí - agbébọn
Ẹwẹ, araalu mii ti baba rẹ wa lakata awọn ajinigbe lati bi ọjọ diẹ bayii ni wọn ti pe oun lori ago pe ki oun teete wa san owo itusilẹ ti awọn n beere ti ko ba fẹ ki awọn pa baba rẹ bi awọn ṣe pa awọn fijilante meji naa.
Araalu ti oun naa ni ka fi orukọ oun pamọ sọ pe wọn pe oun lori ẹrọ ibanisọrọ pe ti oun ko ba san millionu mẹwaa naira, wọn yoo pa baba oun.
"A ti n jọ fa a tẹlẹ, ti mo si n bẹbẹ si idaji millionu kan naira, a fi ti wọn tun pe ni ọsan yii pe, awọn lawọn pa awọn fijilante meji ni owurọ oni pe ti mi o ba san millionu mẹwaa naira, awọn yoo pa baba mi bi awọn ṣe pa awọn fijilante meji naa.
"Ohun to n bawa finra ni agbegbe wa leyii o, ki ijọba jọwọ ki wọn ran wa lọwọ, ki opin si de ba ipaniyan ati ijinigbe wọ yii."
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìròyìn tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn jùlọ
Content is not available