Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé, orílẹ̀èdè 123, bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ tí yóò sọ òwò ẹrú di ìjìyà tó burú jù lọ fún ọmọnìyàn
Oríṣun àwòrán, Universal Images Group Via Getty Images
Akojọpọ ajọ Iṣọkan Agbaye (United Nations General Assembly) ti dibo lori ifẹnuko pe fifi eeyan ṣe owo ẹru ni ijiya to buru julọ to le ṣẹlẹ si ẹda eeyan laye.
Eyi ni ọpọ eeyan gba pe yoo mu ọgbẹ ọkan ti owo ẹru da silẹ san, ti yoo si tun mu idajọ ododo waye.
Orilẹede Ghana lo gbe aba yii kalẹ, orilẹede mẹtalelọgọrun-un (123) ni wọn si tun fara mọ ọn yatọ si ajọ UN.
Bakan naa ni wọn tun rọ awọn ọmọ ẹgbẹ UN lati tọrọ aforiji fun owo ẹru ti wọn fi awọn eeyan ṣe, ki wọn si tun fun wọn lowo pẹlu.
Wọn ko darukọ iye owo naa ṣaa.
America, Israel ati Argentina ko fara mọ ọn ni tiwọn
Igbesẹ ti awọn orilẹede 123 ti fọwọ si yii, awọn ilu bii America, Israel ati Argentina sọ pe awọn ko fara mọ ọn ni tawọn.
Awọn orilẹede mẹtalelaadọta (52) ni wọn ko da si ọrọ naa rara, titi to fi mọ United Kingdom ati awọn ọmọ ẹgbẹ European Union.
Lati ọdun pipẹ ni awọn orilẹede bii UK ti kọ lati san owo gba ma binu ni tiwọn, wọn ni awọn ko le maa bẹ ẹ̀ṣẹ̀ ijọba atijọ wo lara ti iwoyi.
Samuel Okudzeto Ablakwa, Minisita ọro ilẹ okeere lo ti ṣaaju sọ fun BBC, pe awọn n beere owo gba ma binu, ṣugbọn ki i ṣe pe awọn olori ilẹ Africa lo fẹẹ ko owo naa si apo ara wọn.
"Awọn to jiya imunilẹru la n beere idajọ ododo fun, a fẹ ohun ti yoo ran ẹkọ ati iṣẹ ọwọ awọn eeyan wọn lọwọ ni."
Ikede pe ki wọn ṣe ẹtọ to yẹ fun awọn ti wọn mu lẹru yii ko ṣẹṣẹ bẹrẹ, oun ni wọn fi ṣe akori ipade African Union lọdun 2025.
Laaarin ọdun 1500 si 1800, eeyan to to miliọnu mejila si mẹẹẹdogun ni wọn mu lẹru lọ si orilẹede America, nibi ti wọn ti fipa mu wọn lati ṣiṣẹ bii ẹru.
Akọsilẹ sọ pe eeyan to le ni miliọnu meji lo ku sọju ọna lasiko ti wọn n ko wọn rin irin ajo lọ oko ẹru naa.
Ipa aburu ti owo ẹru naa ko ba ilẹ yii ṣi n han lorilẹ bi Ablakwa ṣe ṣalaye fun BBC.
"A tun fẹ ki wọn da gbogbo awọn nnkan iṣẹdalẹ wa ti wọn ji ko lọ pada"
Yatọ si sisọ owo ẹru di ijiya to le julọ, awọn to n dabaa naa tun sọ pe awọn fẹ ki wọn da gbogbo nnkan iṣẹdalẹ to jẹ ogun ini ilẹ Africa pada.
Wọn ni awọn to ko eeyan bii tiwọn lẹru naa lo ji wọn ko lọ, asiko si ti to ki wọn da a pada silẹ Africa.
Orilẹede Ghana to jẹ ọkan lara awọn ọna ti wọn ko awọn ẹru naa gba lo n lewaju ninu ipe yii.
"A fẹ ki wọn da gbogbo awọn nnkan ini wa pada, awọn ni wọn duro fun aṣa ati iṣe wa.
"Wọn gbọdọ da gbogbo ohun ti wọn ji ko lasiko ijọba amunisin pada fun wa bayii.''
Bẹẹ ni Ablakwa to sọrọ lorukọ ilẹ Ghana sọ.
Bakan naa ni Aarẹ orilẹede Ghana, John Dramani Mahama, ṣalaye pe ipinnu onitan ni eyi, o si jẹ ohun ti ko ni I jẹ kawọn eeyan gbagbe itan wọn.
Aarẹ Mahama tako iṣakoso Aarẹ Donald Trump ilẹ America, to fi aaye gba gbigbagbe itan ilẹ eeyan dudu.
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìròyìn tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn jùlọ
Content is not available