Àlàyé lórí bí Amẹrika ṣe dóòlà ọmogun rẹ̀ tó wà nínú bàálù ìjagun tí Iran fi àdó olóró já lulẹ̀

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọmogun Amerika ti doola ọmogun to wa ninu baalu ijagun Amẹrika eyi ti Iran fi ado oloro ja lulẹ.

Ko tii si ẹni to le sọ ẹkunrẹrẹ bi wọn ṣe ri ọmogun to wa ninu baalu naa doola, amọ, a gbọ pe nnkan ti ko rọrun ni.

Oniruuru baalu ijagun ati ẹlikopita Amẹrika lo ṣiṣẹ pọ pẹlu ajọ oluwadii CIA lati doola awakọ ofurufu naa.

Lanaa ọjọ Aiku ọjọ karun-un oṣu Kẹrin yii ni Aarẹ Donald Trump kede wi pe Amẹrika ti doola ọmogun rẹ to wa ninu ọkọ ofurufu F-15 ti Iran ja lulẹ, bo tilẹ jẹ pe o farapa gan.

Trump ni lori awọn oke nla kan ni Iran ni wọn ti ri awakọ baalu ijagun ọhun.

Lọjọ Ẹti ọsẹ to kọja ni iroyin jade wi pe baalu ijagun F-15 ti ọmogun to n ṣakoso nnkan ijagun ati awakọ baalu kan wa ninu rẹ ja lulẹ lẹyin ti Iran yin ado oloro si i.

Igba akọkọ ree ti awọn ọta yoo fi ado oloro ja baalu ijagun Amẹrika lulẹ ni nnkan bii ogun ọdun.

Awọn ọmogun Amẹrika mejeeji ti wọn wa ninu baalu naa lo raye jade lẹyin ti Iran yin ado oloro si baalu ijagun naa.

Lọjọ kan naa ni Amẹrika ti doola awako baalu naa, ṣugbọn ọmogun keji to wa ninu ọkọ ofurufu ọhun di awati.

Bayii ni Amẹrika bẹrẹ akitiyan lati ṣe awari ọmogun keji to wa ninu baalu naa.

Lẹyin naa ni Iran kede wi pe awọn fẹ mu ọmogun naa nibi kibi to ba wa, koda wọn ṣeleri lati fun ẹnikẹni to ba ri ọmogun Amẹrika naa ni $66,100.

Awọn fidio kan ti BBC ko le fi idi rẹ mulẹ ṣafihan bawọn araalu ti wọn di ihamọra ogun ṣe n wa ọmogun Amẹrika naa.

Ileeṣẹ ologun Amẹrika sọ pe ibọn ilewọ nikan yoo wa lọwọ ọmogun naa to ba ti wa lori ilẹ.

Awọn ileeṣẹ iroyin Amẹrika sọ pe ọmogun naa fi ara rẹ pamọ si oke ti o wa ki awọn ọta ma ba ri i.

Nibẹ si ni o duro si titi tawọn ọmogun Amẹrika ti wọn doola rẹ fi de.