Ipa wo ni ìdarapọ̀ Kwankwaso mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú ADC máa ní lórí ìbò 2027?

Rabiu Kwankwaso wọ agbádá funfun, ó dé fìlà pupa, ó mú gbohùngbohùn dání

Oríṣun àwòrán, Rabiu Kwankwaso/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Kano, Rabiu Musa Kwankwaso ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú African Democratic Congress, ADC.

Ní ilé rẹ̀ tó wà ní ìlú Kano ni ayẹyẹ bó ṣe darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú náà ti wáyé pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwọn alátìlẹyìn tí wọ́n tò síwájú ilé náà.

Kwankwaso sọ fún àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ náà láti ri dájú pé wọ́n forúkọ sílẹ̀ pẹ̀lú ADC, kí wọ́n sì ri dájú láti gba káàdì ìdìbò ṣáájú ètò ìdìbò ọdún 2027.

Ní ọjọ́ Àìkú ni Kwankwaso kéde fífi ẹgbẹ́ òṣèlú NNPP sílẹ̀, tó sì ní ìgbésẹ̀ náà ń wáyé láti lọ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ mìíràn lójúnà àti mú àyípadà ọ̀tun bá Nàìjíríà.

Ó ní àsìkò tit ó láti ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ òṣèlú míì lójúnà àti koj;u àwọn ìpèníjà tó ń bá Nàìjíríà fínraàti láti pèsè ìṣèjọba fáwọn èèyàn.

Ipa wo ní Kwankwaso máa ní lórí dídarapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú ADC?

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ADC ṣe ń rẹ́sẹ̀ walẹ̀ sí lágbo òṣèlú Nàìjíríà, Kwankwaso tó darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú náà ni ìgbàgbọ́ wà pé ó máa ní ipa ńlá lórí ẹgbẹ́ náà.

Onímọ̀ nípa òṣèlú, Dókítà Kabiru Sufi sọ fún BBC Hausa pé ipa rẹ̀ ni pé ó máa jẹ́ kí ẹgbẹ́ òṣèlú ADC rí ìbò tó pọ̀ láti ìpínlẹ̀ Kano bó ṣe jẹ́ pé Kano ní ìbò táwọn aráàlú ń dì jùlọ ní Nàìjíríà ti máa ń wá.

Sufi wòye pé Kwankwaso ní ipa tó pọ̀ nínú iye ìò tí wọ́n dì ní ìpínlẹ̀ Kano níbi ètò ìdìbò ọdún 2023, tí òun nìkan sì ní tó ìbò tó lé ní mílíọ̀nù ní ìpínlẹ̀ Kano nìkan.

Onímọ̀ náà ní òun gbàgbọ́ pé Kwankwaso àti gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Kaduna, Mallam Nasir El-Rufai má ní ipa lórí ìdìbò tó máa jáde láti ẹkùn ìwọ̀ oòrùn àríwá Nàìjíríà lọ́dún 2027.

Kí ló dé tí kò darapọ̀ mọ́ APC?

Ṣáájú kí Tinubu tó gba ipò ààrẹ Nàìjíríà ni àhesọ ti ń lọ pé ó ṣeéṣe kí Kwankwaso darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC.

Níbi ìpàdé kan tí Tinubu àti Kwankwaso ṣe ní orílẹ̀ èdè France kí wọ́n tó búra wọlé fún Tinubu lọ́dún 2023 ni Tinubu ti sọ pé òun máa bá àwọn ẹgbẹ́ alátakò ṣiṣẹ́ tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì ti rò pé Kwankwaso máa darapọ̀ mọ́ APC ni.

Àmọ́ títí di àsìkò yìí, Kwankwaso kò darapọ̀ mọ́ APC tí onímọ̀ òṣèlú, Sufi sọ pé ìfaǹfà tó ń wáyé láàárín gómìnà ìpínlẹ̀ Kano, Abba Yusuf le wà lára ohun tí Kwankwaso kò ṣe darapọ̀ mọ́ APC.

Ó wòye pé tó bá jẹ́ pé Kwankwaso àti Abba jọ lọ sí APC papọ̀, kò bá tún dára àmọ́ ó máa nira fún Kwankwaso láti lọ APC lẹ́yìn tí Abba ti kọ́kọ́ darapọ̀ mọ́ APC.

Ṣé Kwankwaso àti Peter Obi le díje papọ̀ bí gẹ́gẹ́ bí ààrẹ àti igbákejì?

Peter Obi fọwọ́ kọ́ Kwankwaso lọ́rùn

Oríṣun àwòrán, Rabiu Musa Kwankwaso/Facebook

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Láti ìgbà tí Kwankwaso ti kéde láti fi ẹgbẹ́ òṣèlú NNPP sílẹ̀ ni àwọn olólùfẹ́ gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Anambra, Peter Obi ti ń wòye pé ó ṣeéṣe kó jẹ́ pé àwọn méjéèjì ló máa díje papọ̀ lọ́dún 2026 lábẹ́ àsíá ADC.

Awuyewuye náà ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ nígbà Peter Obi ṣe àbẹ̀wò sí Kwankwaso lásìkò ọdún ìtúnu ààwẹ̀ lọ́sẹ̀ tó kọjá níbi tí Peter Obi ti bá àwọn olólùfẹ́ Kwankwaso tó lọ b ṣọdún sọ̀rọ̀.

Láti ìgbà náà ni àwọn èèyàn ti ń rò ó pé ó ṣeéṣe káwọn àgbà olóṣèlú méjéèjì máa po nǹkan papọ̀.

Obi àti Kwankwaso ni wọ́n díje dupò ààrẹ Nàìjíríà lọ́dún 2023 lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Peter Obi dupò ààrẹ lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party nígbà tí Kwankwaso dupò ààrẹ lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú NNPP tí àpapọ̀ ìb]o tí àwọn méjéèjì sì ní jẹ́ mílíọ̀nù méje àbọ̀.

Àwọn onímọ̀ wòye pé tí àwọn méjéèjì bá jọ díje gẹ́gẹ́ olùdíje sípò ààrẹ àti igbákejì, ó ṣeéṣe kí wọ́n bá ààrẹ Tinubu àti ẹgbẹ́ òṣèlú APC wàákò níbi ètò ìdìbò gbogbogbò ọdún tó ń bọ̀.

Yunusa Tanko tó jẹ́ agbẹnusọ Obidient Movement ní Nàìjíríà sọ pé òun gbàgbọ́ pé àjọṣepọ̀ Kwankwaso àti Peter Obi ti ń rí àtìlẹyìn àwọn ọmọ Nàìjíríà.