"Mo ra ‘Sim Card’ táwọn ajínigbé ti fi gbá owó ìtúsílẹ̀ N50m, pa ẹni tí wọn jí gbé, mo bá dèrò àtìmọ́lé"
Adura ti ọpọ eeyan maa n gba ni pe ka ma ri ogun akoba, adaba, ọrọ ti a ko mọwọ, mẹsa, ko ma di ọran si wa lọrun.
Bẹẹ ni ọrọ ri fun ọmọbinrin kan, Tititlayo Ibrahim, ẹni to jiya aimọdi lori ọrọ ti ko mọ ohunkohun nipa rẹ.
Titilayo Ibrahim, lasiko to n ba BBC News Yoruba sọrọ salaye nipa ohun ti oju rẹ ri lọwọ ọlọpaa lori ọrọ ti ohun ko mọ nkankan nipa rẹ.
Ilu Akure tii se olu ilu ipinlẹ Ondo si ni isẹlẹ naa ti waye.
"Kaadi ipe, 'SIM card' ti mo ra lo gbe mi de ọgba ẹwọn"
Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Titilayo Ibrahim salaye pe adura ti ọpọ eeyan maa n gba pe ki isẹlẹ buruku to n waye ni Naijiria ko gba lori oun.
O ni isẹlẹ buruku ni isẹlẹ to de ba oun naa, eyi to sọ oun di ero ọgba ẹwọn.
Iwadii nipa ọrọ ijinigbe ati ipaniyan tileesẹ ọlọpaa n se lo gbe wọn de ọdọ omidan Titilayo.
Omidan naa lo sẹsẹ ra kaadi ipe, ta mọ si SIM card amọ to jẹ pe awọn ajinigbe lo ti lo kaadi ipe naa tẹlẹ, ti ọlọpaa si n tọpasẹ rẹ.
Onisowo asọ awọsun ati awọtẹlẹ fawọn obinrin si ni omidan Titiulayo Ibrahim.
"Obinrin kan pe mi lori aago pe oun fẹ ba mi ra ọja, a se ọlọpaa to fẹ mu mi ni"
"Ọjọ Kẹrindinlogun osu Kẹwa ọdun 2025 ni isẹlẹ naa waye nigba ti nọmba ipe kan ti n ko mọ, fi atẹjisẹ ransẹ sori nọmba ipe ti mo fi n ta ọja.
O ni ki n fi awọn aworan ọja ti mo n ta ransẹ, mo si se bẹẹ, to si mu asọ meji ninu wọn.
O ni foonu toun ti bajẹ, foonu ọkọ oun si ni oun n lo nitori naa, ki n gbe ọja naa wa sile itura ti awọn wa lati gba owo.
Mo ni emi kii gbe ọja lọ fun onibara amọ mo ni ọlọkada to le gbe wa fun wọn.
Lo ba ni awọn yoo kuku wa gba ọja naa funra awọn, ki n fi adirẹsi ile mi sọwọ, mo si fun.
Mo duro si ẹnu abawọle Estate wa, mo si ri obinrin kan, obinrin naa lomi lara, mo si ri pe asọ awọsun to fẹ ra, ko le gba a rara.
Mo wa lọ ba, mo si n fi ohun to fẹ ra han-an, nibi ti a ti n sọrọ lọwọ, ni ọkunrin kan ti rin wa ba wa."

"Ọlọpaa ni kaadi ipe tawọn ajinigbe fi gba owo itusilẹ aadọta miliọnu naira ni mo n lo"
Ọkunrin naa fi kaadi idanimọ rẹ han mi pe ọlọpaa ni oun, mo si lero pe ọkọ obinrin naa ni amọ emi si n fi awọn asọ awọsun to tobi, to le gba obinrin naa han lori foonu mi.
Sadede lo gba foonu mi, ti obinrin naa si fi kaadi idanimọ rẹ han mi pe ọlọpa ni oun naa, ti wọn si ni awọn ti mu mi"
Bi Titilayo Ibrahim se dero atimọle ọlọpa ree, o si ku ki wọn gbe lọ sile ẹjọ ni ori ko yọ.
Nigba ti wọn n ka ẹsun si lọrun, awọn ọlọpaa sọ fun omidan naa pe kaadi ipe to n lo, eyiun Sim Card, ni awọn ajinigbe ti fi huwa ọdaran tẹlẹ.

"Akọsilẹ Airtel fi han pe mo ra kaadi ipe lori atẹ ni ọjọ kẹẹdogun osu kẹrin ọdun 2024 lẹyin ọdun kan ati osu mẹta ti isẹlẹ ijinigbe ati ipaniyan ti waye"
Nigba to n salaye siwaju fun BBC News Yoruba, Titilayo ni awọn ọlọpaa sọ pe ẹni to n lo Sim Card naa tẹlẹ ji eeyan gbe, o si tun pa ẹni naa lẹyin to gba owo itusilẹ aadọta miliọnu naira lọjọ kinni, osu kinni ọdun 2024.
"Mo sọ fun wọn pe inu Mifi ni kaadi naa wa, ko silori foonu mi, mo kan maa n lo lori foonu mi ni, ọdun 2025 si ni emi ra kaadi ipe naa.
Amọ wọn ko gba gbogbo ohun ti mo sọ gbọ, ẹru ba mi mo n sunkun, ti mo si n gbadura pe ki Ọlọrun gba mi.
Agbẹjọro mi wa sọ fawọn ọlọpaa pe kawọn lọ wo akọsilẹ ileesẹ ibaraẹnisọrọ Airtel to ni kaadi ipe naa lati mọ boya lootọ ni oun ra kaadi naa lori atẹ.
A lọ sibẹ lootọ, ti akọsilẹ si fi han pe mo ra kaadi ipe naa lori atẹ ni ọjọ kẹẹdogun osu kẹrin ọdun 2024 lẹyin ọdun kan ati osu mẹta ti isẹlẹ ijinigbe ati ipaniyan naa ti waye.
Amọ sibẹ awọn ọlọpaa yii ko fẹ gba mi gbọ, wọn yaju si mi, wọn si fi iya jẹ pupọ.
Mo mọ pe ọpọ ọmọ Naijiria lo wa ni ahamọ wọn lai ni ẹnikan ti yoo ja fun wọn."
BBC News Yoruba wa kan sileesẹ lọpaa nilu Aklure ati ileesẹ Airtel to ni kaadi ipe naa sugbọn wọn ko fesi lori isẹlẹ naa.






