Àwọn ìgbésẹ̀ wo ló yẹ fún iléeṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ láti gbé kí wọ́n tó ta síìmù ìpè ti ẹnìkan ti lò rí fún ẹlòmíì?
Oríṣun àwòrán, Getty Images/BBC
Lẹ́yìn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tí BBC News Yorùbá ṣe fún arábìnrin Titilayo Ibrahim, níbi tí ó ti ṣàlàyé nípa bí òun ṣe di èrò àtìmọ́lé látàrí síìmù ìpè tó rà.
Titilayo sọ fún BBC pé ní ọdún tó kọjá ni òun ra síìmù ní iléeṣẹ́ ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ kan tó sì jẹ́ pé síìmù táwọn ajínigbé ti lò rí ni wọ́n fún òun ní nọ́mbà rẹ̀.
Ó ṣàlàyé bí àwọn ọlọ́pàá ṣe wá gbé òun nílé, tí òun sì di èrò àtìmọ́lé kó tó di pé orí padà kó òun yọ.
Ó ní ìwádìí àwọn ọlọ́pàá fi hàn pé lẹ́yìn ọdún kan tí àwọn ajínigbé ti fi síìmù náà ṣọṣẹ́ ni wọ́n ta síìmù náà fún òun.
Kí làwọn òfin tó de ríra síìmù ní Nàìjíríà?
Láti ìgbà tí fídíò náà sì ti jáde ni àwọn èèyàn ti ń bèèrè pé ṣé ó tọ̀nà fún àwọn iléeṣẹ́ ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ láti máa ta síìmù tí èèyàn kan bá ti lò rí fún ẹlòmíràn.
Èyí ló mú wa tọ onímọ̀ òfin lọ láti bèèrè bóyá ó tọ̀nà fún iléeṣẹ́ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ láti ta síìmù tí èèyàn kan ti lò rí àti pé kí ni ó yẹ kí èèyàn ṣe tó bá bá ara rẹ̀ nínú irú ipò tí Titilayo Ibrahim ti bá ara rẹ̀ yìí.
Agbẹjọ́rò kan tó fi ìlú Ibadan, olú ìpínlẹ̀ Oyo ṣe ibùjókòó, Abimbola Orogade sọ fún BBC News Yorùbá pé, lóòótọ́ ni àwọn òfin wà tó de ríra síìmù kí èèyàn tó bẹ̀rẹ̀ sí ní lò ó.
Ó ṣàlàyé pé tí èèyàn bá fẹ́ ra síìmù, onítọ̀hún máa nílò láti fi orúkọ sílẹ̀ pẹ̀lú iléeṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ tó ti fẹ́ ra síìmù náà, tí wọ́n sì máa gba orúkọ rẹ̀ sílẹ̀.
Ó ní yàtọ̀ sí orúkọ, ẹni náà máa nílò láti tẹ̀ka, ya àwòrán rẹ̀, tí wọ́n sì máa so nọ́mbà ìdánimọ̀ rẹ̀, NIN mọ́ nọ́mbà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ rà náà kí iléeṣẹ́ bẹ́ẹ̀ tó ta síìmù fun gẹ́gẹ́ bí òfin tí àjọ tó ń rí sí ìbánisọ̀rọ̀ ní Nàìjíríà ìyẹn Nigerian Communications Commission (NCC) ṣe là á kalẹ̀.
Orogade ní ó pọn dandan fún ẹni tó bá fẹ́ ra síìmù láti gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ìforúkọsílẹ̀ yìí lójùnà àti dènà lílo síìmù náà láti hùwà ọ̀daràn lọ́jọ́ iwájú.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Titilayo, agbẹjọ́rò náà ní ohun tó tọ̀nà ni Titilayo ṣe pẹ̀lú bó ṣe gbẹnu agbẹjọ́rò rẹ̀ láti lọ sọ fún àwọn ọlọ́pàá láti lọ ṣe ìwádìí nípa ìgbà tí òun ra síìmù àti ìgbà tí wọ́n ti fi hùwà ọ̀daràn tẹ́lẹ̀.
Agbẹjọ́rò náà ní ó yẹ kí àwọn ọlọ́pàá ti ṣe ìwádìí bẹ́ẹ̀ ṣáájú kí wọ́n tó fi òfin gbé arábìnrin náà.
Ó wá gba àwọn èèyàn lámọ̀ràn láti máa kàn sí àwọn amòfin tàbí agbẹjọ́rò nígbà tí wọ́n bá ń kojú irúfẹ́ ìṣòrò báyìí.
Ó wòye pé tí wọ́n bá gbèrò láti fẹ́ gba ọ̀nà ẹ̀bùrú tàbí parí rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá láì gba agbẹjọ́rò, ó ṣeéṣe kí ẹjọ́ bẹ́ẹ̀ ju bí ó ṣe yẹ lọ nítorí ìwà ọ̀daràn pọ́mbílé ni ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀.
Ṣé iléeṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ le ta síìmù tí ẹnìkan ti lò rí fún ẹlòmíràn?
Gẹ́gẹ́ bí òfin ètò ìbánisọ̀rọ̀ ní Nàìjíríà, ó ṣeéṣe kí iléeṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ gbé nọ́mbà tí ẹnìkan ti lò rí fún ẹlòmíràn.
Èyí le wáyé nígbà tí wọn kò bá lo nọ́mbà náà mọ́ fún ìgbà pípẹ́ – láàárín oṣù mẹta sí ọdún kan.
Àmọ́ agbẹjọ́rò Orogade sọ pé lórí ọ̀rọ̀ Titilayo Ibrahim, iléeṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ tó ta síìmù fún-un yẹ kí wọ́n ṣe àyẹ̀wò ẹni tó kọ́kọ́ lo síìmù náà - nípa orúkọ tí wọ́n gbà sílẹ̀ – kí wọ́n tó ta síìmù bẹ́ẹ̀ fún ẹlòmíràn.
Ó fi kun pé ó yẹ kí Titilayo pe iléeṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ àti iléeṣẹ́ ọlọ́pàá lẹ́jọ́ lórí àwọn ohun tí wọ́n jẹ́ kó là kọjá nítorí tí kò bá ṣe ohun tó yẹ bóyá kò bá wà nínú ẹ̀wọ̀n títí di àsìkò yìí.
Kí ni ó yẹ káwọn iléeṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ ṣe kí wọ́n tó ta nọ́mbà tí èèyàn ti lò tẹ́lẹ̀ fún ẹlòmíràn?
Lábẹ́ òfin ìbánisọ̀rọ̀ ní Nàìjíríà èyí tí iléeṣẹ́ NCC gbé kalẹ, iléeṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ lẹ́tọ̀ọ́ láti ta nọ́mbà tí èèyàn kan ti lò rí fún ẹlòmíràn àmọ́ tí ẹni tó kọ́kọ́ lò ó kò lò nọ́mbà náà láàárín oṣù mẹ́ta sí ọdún kan.
Èyí túmọ̀ sí pé ẹni náà kò fi nọ́mbà náà pè, kò ra owó ìpè sórí rẹ, kò fi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ tàbí gba àtẹ̀jíṣẹ́ sórí nọ́mbà náà.
Lẹ́yìn náà ni wọ́n máa yọ gbogbo nǹkan tó níṣe pẹ̀lú ẹni tó kọ́kọ́ lo nọ́mbà náà kúrò lára nọ́mbà náà bíi orúkọ, àwòrán àti ìka títẹ̀.
Bákan náà ni wọ́n máa yọ nọ́mbà ìdánimọ̀ NIN ẹni àkọ́kọ́ tí wọ́n fi si kí wọ́n tó le ta nọ́mbà náà fún ẹlòmíì.
Wọn kò nílò láti gbàṣẹ lọ́wọ́ ẹni tó kọ́kọ́ lo nọ́mbà náà kí wọ́n tó tà á fún ẹlòmíì.
Ṣé owo gba ma binu wa fun ẹni ti wọn fẹsun ọdaran kan lọna aitọ tori Siimu ipe to ra, bii Titilayo?
Ibeere to wa n tawọ tasẹ lọkan ọpọ eeyan ni pe se iru iya aimọdi bayii yẹ ko jẹ Titilayo Ibrahim gbe?
Wọn fẹ mọ boya ofin kan wa to fun ẹni ti wọn ba fẹsun aimọdi kan, ti wọn si jẹ niya tori o ra siimu ipe ti ẹnikan ti lo ri, ni anfaani lati beere fun owo gba ma binu?
Nigba to n dahun ibeere yii, Amofin Abimbola Orogade ni lootọ ni, ofin wa to gbe eeyan ti wọn ba jẹ niya lọna aitọ lẹyin lati pe ẹjọ beere fun owo gba ma binu.
Amọ o ni eeyan melo lo ni owo lati pe iru ẹjọ naa, sanwo fun agbẹjọro tabi ni suuru fun ọpọ ọdun ki ile ẹjọ to gbe idajọ bẹẹ kalẹ.
O wa gba omidan Titilayo Inbrahim, tii se agunbanirọ niyanju pe to ba lowo lati san fun agbẹjọro, ki wọn si gbe ẹjọ naa lọ sile ẹjọ, lati beere fun owo gba ma binu, yoo bori nile ẹjọ.
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìròyìn tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn jùlọ
Content is not available