Ṣé èmí tí ẹ rí yìí jọ ẹni burúkú tàbí Jàǹdùkú?- Auxilliary
Oko ọrọ bọ lẹnu alaga ẹgbẹ igbimọ to n se akoso awọn gareeji ọkọ nipinlẹ Oyo, PMS, eyiun Alhaji Mukaila Lamidi, ta tun mọ si Auxillary.
Auxillary, lasiko to n ba BBC Yoruba fọrọ jomitoro ọrọ salaye pe oun kii se janduku tabi adaluru gẹgẹ bi awọn eeyan kan se n pariwo oun kiri.
O kede pe awọn alatako oun ninu oselu ati ninu ẹgbẹ awakọ ero lo n sọ oun ni orukọ buruku to tako iwa oun.
Aabo ti wa lawọn ibudokọ wa ni Oyo, awa n pawo wọle fun ijọba ni – Auxillary
Nigba to n salaye ipo ti igbokegbodo ọkọ ero wa nipinlẹ Oyo bayi, Auxillary salaye pe tẹlẹ tẹlẹ, owo gọbọi ni awọn ọga ọlọkọ ero maa n ri nidi ipo ti wọn di mu.
₦2m ní Seyi Makinde ń fún Olopoeyan lọ́sẹ̀, wọ̀bìà ló mú kó kúrò nínú PDP - Auxillary
Auxillary: Seyi Makinde kò fi mí sílẹ̀ ní ẹ̀wọ̀n, òun ló ń sanwó iléẹ̀kọ́ àwọn ọmọ mi
O ni ọkọ kan soso to ba n lọ silu Eko, yoo ja tikẹẹti mẹtala ni ọjọ kan soso, lara tikẹẹti naa si ni tawọn ọga ọlọkọ ero ati ti olu ile ẹgbẹ ni Abuja wa.
Amọ o ni nibayii, awọn alakoso gareeji ọkọ n pa owo wọle fun ijọba ipinlẹ Oyo ni, ti awn ọga ẹgbẹ ko si maa da owo sapo ara wọn gẹgẹ bi wọn ti n se ninu ẹgbẹ NURTW ti wọn fi ofin de.
₦2m ní Seyi Makinde ń fún Olopoeyan lọ́sẹ̀, wọ̀bìà ló mú kó kúrò nínú PDP – Auxillary
Nigba to n sọrọ lori ohun to fa aawọ laarin rẹ ati agba oselu kan nilu Ibadan, Adebisi Olopoeyan, Auxilaary ni iwa wọbia, ainitlọrun ati oju kokoro lo n ba oloselu naa ja.
“Eeyan ti diẹ ko to, airirara ni yoo gbyin rẹ ni ọrọ Olopoeeyan
Gbogbo ọjọ Tuesday ni gomina Seyi Makinde maa n fun ni miliọnu meji naira lati se ounjẹ fawn ọmọ ẹgbẹ́.
Emi ati ẹ ko ja ri amọ igba to ni ki n la itan fun gomina ni mo yari pe oloore mi ni Makinde.
Makinde lo n tọju mi nigba ti mo wa ni ẹwọn, ti ko si fi emi ati idile mi silẹ rara.
Bo se n tọju mi, naa lo n tọju idile mi, to si n sanwo ile ẹkọ awọn ọmọ mi.
Amọ ka to di ibo gomina to gbe Seyi Makinde wọle, ni mo ti fi oju kan Adebisi Olopoeyan kẹyin, a kii ri ara wa rara.
BBC Yoruba wa kan si Alhaji Adebisi Olopoeyan lati mọ esi rẹ si awọn ẹsun ti Auxillary fi kan an, amọ o da wa lohun pe oun ko ni esi kankan ti oun fẹ sọ lori ọrọ Auxillary.
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìròyìn tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn jùlọ
Content is not available