Wo àwọn orílẹ́ède tó ń jèrè àtàwọn tó ń wọ gbèsè lórí ogun Iran àti Amẹrika pẹ̀lú Israel tó ń lọ
Oríṣun àwòrán, Tasnim News Agency/Getty Images
Ọwọngpogo epo rọbi ti gbode kaakiri awon orilẹede agbaye latari ogun to n lọ lọwọ laarin Iran ati Amẹrika pẹlu Israel.
O ti han gbangba pe bi Amẹrika ati Israel ṣe n ju ado oloro si Iran ti Iran naa si n da a pada si Israel ati sawọn ibudo ologun Amẹrika to wa ni ẹkun Middle East ti ṣakoba fun ọrọ aje ọpọ orilẹede.
Amọ, bi ogun naa ti n ṣakoba fun ọpọ orilẹede, awọn orilẹede kan si wa ti wọn n jere nibẹ.
Awọn orilẹede to n jere lori ogun Iran ati Amẹrika pẹlu Israel
Bo tilẹ jẹ pe oniruuru ajọ lagbaaye lo ti n gbiyanju lati mu adinku ba lilo epo rọbi tori ipa to n ni lori ayika, ogun to n lọ lọwọ ni Iran ti fi han pe epo rọbi naa si ni gbogbo agbaye n lo julọ.
Nitori naa, awọn orilẹede ti wọn ti ko epo pamọ ko mọ ọn lara rara.
Bi Iran ti di oju ọna Strait of Hormuz ninu okun ko jẹ ki ọpọ orilẹede le gbe epo rọbi kọja loju ọna ọhun mọ.
Eyi si ti ṣakoba fun ọpọlọpọ orilẹede ti wọn n ta epo silẹ okeere bii Qatar ati Saudi Arabia.
Bakan naa ni Iran ti n yin ado oloro sawọn orilẹede to ni ibaṣepọ pẹlu Amẹrika lẹkun Middle East.
Bi ọpọ orilẹede ti n wa epo rọbi ti wọn fẹ ra lawọn ẹkun mii lagbaye, awọn orilẹede bii Norway ati Canada n jẹ anfaani lọwọ yii.
Lati ọdun 2022 ti Russia ti ya wọ Ukraine ni ọpọ orilẹede ko ti ra epo Russia mọ.
Lati igba naa ni Norway ti n pese epo to pọ sii ti wọn si n ta a silẹ okeere.
Awọn orilẹede to n padanu latari ogun to n lọ ni Iran
Bawo ni nnkan ṣe ri ni orilẹede Amẹrika gan an? Donald Trump ni Amẹrika yoo rowo to pọ ti owo epo ba lọ soke.
Loootọ ni pe ọpọ ileeṣẹ epo rọbi Amẹrika yoo jere gọbọi ti ọwọngogo epo ba si tẹsiwaju bayii.
Amọ, eyi ko tumọ si pe Amẹrika lo n jere ogun to n lọ lọwọ ni Iran julọ.
Idi ni wi pe ọpọ ileeṣẹ epo rọbi ko maa tete ri epo ni ẹkun Middle East.
Fun apẹẹrẹ, ileeṣẹ epo rọbi ExxonMobil ni Qatar ti n da iṣẹ duro lati ibẹrẹ oṣu Kẹta yii.
Ni bayii, ado oloro ti Iran n ju si Qatar tun ti ṣakoba nla fun ilẹẹṣẹ naa.
Idi miran tun ni pe ileeṣẹ naa ti mu adinku ba iye epo ti wọn n wa latari bi owo epo ti n lọlẹ.
Ọpọ orilẹede to n wa epo ni ko le tete ṣe afikun epo rọbi ti wọn n wa.
Ẹwẹ, awọn onimọ nipa ọrọ aje ni fasiti Oxford ti woye pe o ṣee ṣe ki wọn maa ra agba epo kan ni $140, wọn ni eyi yoo si ṣakoba fun eto ọrọ aje lagbaaye.
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìròyìn tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn jùlọ
Content is not available