Àwọn èèyàn Burkina Faso gbọdọ̀ gbàgbé nípa ìjọba awarawa – Ibrahim Traoré

Oríṣun àwòrán, TASS via Reuters

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba awarawa maa n paayan ni awọn eeyan wa si gbọdọ gbagbe rẹ lai fọta pe.

Aarẹ ologun orilẹede Burkina Faso, ọgagun Ibrahim Traoré, lo sọ bẹẹ ninu ifọrọwerọ kan.

Ibrahim Traoré to gba ọpa aṣẹ orilẹede naa lọdun mẹta sẹyin ninu iditẹgbajọba sọ pe ọpọ awọn ọmọ ilẹ Afrika ni ko fẹran ijọba awarawa, a ti pe orilẹede awọn ni ọna ti wọn yoo fi maa ṣejọba ara wọn lai lo eto oṣelu.

Ṣaaju ni Traoré ti kọkọ ṣeleri lati da ijọba pada fun awọn oloṣelu ninu oṣu Keje ọdun 2024 amọ nigba to ku oṣu meji ki gbedeke to da pe, o kede pe awọn ologun ni yoo ṣi maa tukọ ilẹ naa lọ fun ọdun marun un mii.

Ninu oṣu Kinni ọdun 2026, ijọba ologun naa gbẹsẹle gbogbo ohun to jọ mọ oṣelu nibẹ.

Wọn ni igbesẹ naa jẹ ọkan lara awọn ọna lati tun orilẹede naa ṣe.

Ninu ifọrọwerọ ọhun ni Traoré ti sọ pe "Awọn eeyan wa lati gbagbe nipa ijoba awarawa. Ijọba awarawa kii ṣe fun wa. Ẹ wo Libya, eyii jẹ apẹrẹ to sun mọ wa."

Fun odidi ogoji ọdun gbako ni ọgagun Muammar Gaddafi fi tukọ Libya bo tilẹ jẹ pe o n pese ile fun araalu ni ẹdinwo, ẹkọ ọfẹ ati eto ilera ọfẹ.

Gadafi ku lasiko rogbodiyan to lọwọ ijọba ilẹ okeere ninu.

Lati igba ti Gadafi ti jade laye ni eto idibo kankan ko tii waye lorilẹede naa, onirurun ẹgbẹ agbebọn lo si n ṣejọba bo ṣe wu wọn lorilẹede ọhun.

Traoré ṣalaye pe "Gbogbo igba ti awọn alagabra lati ilẹ okeere ba n sọ pe awọn fẹ fi ẹsẹ ijọba awarawa mulẹ niAfrika ni ọpọ ẹmimaa n ṣofo.

Lootọ ni awọn ologun ti ditẹgbajọba lawọn orilẹede kan ni Afrika, amọ pupọ orilẹede ni Afrika lo n fi ibo gbe awọn adari wọn wọle.

Ẹwẹ, ọpọ awọn ariyanjiuyan lo maa waye lẹyi eto idibo ni Afrika, ti pupọ rẹ si maa da lori bi ijọba to wa lode ṣe maa n ṣe makaruru ninu eto idibo naa, eyii to maa n pada de ile ẹjọ.