Hisbah Kano fi òfin de lílo èdè 'Black Friday', àwọn ọmọ Naijiria kan yarí lórí ayélujára

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Àjọ Hisbah tó jẹ́ ọlọ́pàá Sharia ní Kano kọ lẹ́tà ìkìlọ̀ lórí lílo èdè 'Black Friday'.

Ajọ to n ṣamojuto Ofin Sharia nipinlẹ Kano, Hisbah, ti kọ lẹta si ileeṣẹ agbohunsafẹfẹ kan to wa nipinlẹ naa, lori lilo àṣà 'Black Friday'.

Ninu lẹta naa ti ajọ Hisbah kọ, o ni ọjọ Mimọ ni ọjọ Jimọ jẹ ninu ẹsin Islam, nitori naa pipe e ni ọjọ dudu jẹ nkan iwọsi.

Wọn sọ ninu lẹta naa pe "Musulumi ni ọpọ awọn to n gbe nipinlẹ Kano, ti wọn si ka ọjọ Jimọ si ọjọ Mimọ.

Hisba ni: "Nitori eyi, a rọ yin lati fi opin si pipe ọjọ naa ni 'Black Friday', ni kiakia.

"A si fẹ ki o ye e yin pe awọn ọlọpaa Hisbah yoo ma a tọ pinpin lati le dena lilo ede naa, ati lati le jẹ ki alaafia ati irẹpọ wa nipinlẹ Kano."

Alayee re e lori nkan ti Ọjọ́ Black Friday jẹ ni agbaye

  • Black Friday ni orukọ ti wọn n pe ọjọ Ẹti to ba tẹle ọjọ idupẹ 'Thanksgiving Day' nilẹ Amerika.
  • Ọjọbọ kẹrin ninu oṣu Kọkanla lọdọọdun ni wọn maa n ṣe e.
  • Ọjọ Black Friday yii ni awọn ile itaja maa n ta awọn ọja wọn ni ẹsinwo.
  • Gbogbo agbaye si ni awọn onile itaja ti maa n lo ede yii.
  • 'Black Friday' àyájọ́ ẹ̀dínwó ọjà tó gbá ayé kan.
  • Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla, si ni Black Friday ti ọdun 2020.
Àkọlé fídíò, Adebola Ademilua: Àìrísẹ́ ṣè lẹ́yìn ìwé kíkà ló sọ mi dí ìyá onírú, mo dúpẹ́ tèmi

Awọn wo ni Hisbah?

Oríṣun àwòrán, AFP

Ọjọ ti pẹ ti orukọ ajọ Hisbah ti n jẹyọ ninu iroyin, paapaa ni awọn ipinlẹ to wa ni Ariwa Naijiria.

Ọrọ lẹta ti wọn kọ yii si ti n fa ariyanjiyan lori ayelujara Twitter.

Ninu ọrọ rẹ, @DrOlufunmilayo lori Twitter sọ pe "Black Friday ma n ran awọn ontaja lọwọ. O si n ran awọn eeyan to ku diẹ kaato fun lọwọ.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

"Ti ẹ ba fi opin si black Friday, yoo pa okoowo lara, ati awọn talika to yẹ ko ra nkan ni ẹdinwo."

@Sunnyyon ni ti s pe boti lẹ jẹ pe oun kii ṣe ololufẹ ajọ Hisbah, oun naa ko fẹran àṣà 'Black Friday'. O ni o y ki Naijiria naa ni awọn ọjọ isinmi ti ẹ.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Oriṣiriṣi iwa 'to ba tako ẹsin Islam' ni wọn ma n mu awọn eeyan si, ti wọn si ma n fi ofin Sharia ṣe idajọ wọn.

Laipẹ yii ni iroyin sọ pe wọn dana sun awọn ọti lile.