Ooni Ile ife, Adeyeye Ogunwusi di onítíátà nílẹ̀ Amẹ́ríkà
Oríṣun àwòrán, Ooni Adeyeye Enitan Babatunde Ogunwusi - Ojaja II
Ọọni ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi ti di onitiata bayii o pẹlu bi o ṣe kopa ninu sinima kan ti wọn pe orukọ rẹ ni “Take Me Home”.
Ibudo sinima agbaye ni, Hollywood studios ni California lorilẹede Amẹrika ni wọn ti ya sinima naa.
Ọọni Adeyẹye Ogunwusi, gẹgẹ bi awọn olotu sinima naa ṣe sọ, ko ipa to tọ si oriade ninu sinima naa, gẹgẹ bi olori alade gbogbo ninu eyi to ti mu iyi, ọla ati ẹyẹ itẹ rẹ jẹyọ ninu ileeṣẹ sinima lagbaye.
Ọba Adeyeye kopa ninu ere tiata pẹlu Lateef Adedimeji
Koko sinima naa da lori ilepa ati pada si orirun ẹni pẹlu ibeere lori gbigbe igbesẹ lori awari kadara ẹni.
Lara awọn eekan to kopa ninu sinima naa ni awọn oṣere Amẹrika bii Dave Sheridan, Amber Rivette, Felissa Rose ati Meji Black.
Awọn oṣere sinima lati Naijiria bii Abdulateef Adedimeji ati Bayo Bankole ti ọpọ mọ si Boy Alinco, naa kopa ninu sinima naa.
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìròyìn tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn jùlọ
Content is not available